Ìjà parí, ọ̀tẹ̀ bùṣe láàrin Ọọ̀ni àti Aláàfin lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ bí Ọba Owoade ṣe fi aṣọ wé gbohùngbohùn tó gbà lọ́wọ́ Ọba Ogunwusi

Aláàfin Abimbola Owoade wọ agbada àti Sokoto aláwọ̀ Kọfi àti Goolu, ó dé fìlà abeti ajá, ó fi ìlẹ̀kẹ̀ ńlá méjì sọrun, tó sì mú gbohùngbohùn tí wọn fi aṣọ funfun we lọ́wọ́. Ọọ̀ni Adeyeye Ogunwusi dúró sí ẹgbẹ́ Aláàfin, ó dé adé sórí, ó wọ agbada àti Sokoto aláwọ̀ miliki sọrun, O si fi ìlẹ̀kẹ̀ sọrun pẹlu

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ló wáyé nílùú Eko, nile ìtura Eko hotel nígbà tí àwọn oríadé méjì nílẹ̀ Yorùbá ń ṣe gbọ́n-ń-kú gbọ́n-ń-kú síra wọn.

Àwọn Ọba méjèèjì náà ni Ọọ̀ni tilu Ilé-Ifẹ̀, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ọjaja kinni àti Aláàfin tilu Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade, Orumọgale àkọ́kọ́.

Níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí aadọrun ọdún gbajumọ olokoowo Kan, Kessington Adebutu, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Baba Ìjẹ̀bú ni àwọn oríadé méjèèjì tí gapa síra wọn.

Aláàfin Abimbola Owoade wọ agbada àti Sokoto aláwọ̀ Kọfi àti Goolu, ó dé fìlà abeti ajá, ó fi ìlẹ̀kẹ̀ ńlá méjì sọrun, Ọọ̀ni Adeyeye Ogunwusi dúró sí ẹgbẹ́ Aláàfin, ó na ọwọ́ sókè bíi ọgbà to ń juwọ

Oríṣun àwòrán, Collage

Bawo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe waye?

Ìṣẹ̀lẹ̀ aáwọ láàrin Ọọ̀ni àti Aláàfin tún fojú hàn níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà, níbi tí Ọọ̀ni tí kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, to si gbe gbohùngbohùn fún Alaafin, ẹni tó dúró sí ẹgbẹ rẹ pé kí òun náà sọ̀rọ̀.

Ọọ̀ni, ẹni tó kàn gbé gbohùngbohùn fún Aláàfin lai wo ojú rẹ, kan ń wò ọkàn kan èyí tó fi hàn pé àárín wọn kò gún.

Ní kété tí Alaafin sì tẹwogba gbohùngbohùn náà, lo kọ ojú sẹ́yìn, sì ọdọ ẹ̀ṣọ́ rẹ kan to dúró tíì.

Ẹṣọ náà sì lọ yàrá mú aṣọ inuju tí a mọ̀ sí Handkerchief tuntun méjì jáde, tó fi wé ẹnu àti ara gbohùngbohùn náà.

Lẹ́yìn tí wọn we ara gbohùngbohùn náà tán pẹlu aṣọ inuju yìí, ní Alaafin to lo o láti sọ̀rọ̀.

Fídíò bí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe waye lọ lu orí ayélujára pa, èyí tí kò dùn mọ ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá nínú.

Ṣé ni ọpọ eeyan ń kọminu pé báwo ni àwọn àgbà méjì yóò ṣe máa ṣorò bíi èwe.

Ìjà àgbà méjì nílẹ̀ Yorùbá bùṣe, Kessington Adebutu parí ìjà láàrin Ọọ̀ni àti Aláàfin

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wàyí o, leyin ti fídíò bí Ọọ̀ni àti Aláàfin ṣe ṣe gbọ́n-ń-kú gbọ́n-ń-kú síra wọn jáde sórí ayélujára, ìròyìn tí jáde pé ogún ti parí, ọ̀tẹ̀ tí bùṣe laarin awọn oríadé méjèèjì náà.

Atẹjade kan tó jáde sọ́wọ́ àwọn Akọroyin láti ààfin Ọọ̀ni tilu Ilé-Ifẹ̀ lọ fìdí ìgbésẹ̀ náà mulẹ.

Atẹjade náà ni Bàbá Ìjẹ̀bú tó ṣe ọjọ́ ìbí náà, tó tún jẹ́ Odole Oodua lo doola aáwọ láàrin àwọn oríadé méjèèjì náà ni ọjọ́ Ẹti.

Níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà sì ni ìgbésẹ̀ àlàáfíà náà tí wáyé nilu Eko, táwọn àgbà Oba méjèèjì náà sì fi ọwọ́ sọya pé àwọn yóò gba àlàáfíà, ibọwọ fún ara ẹni àti agbega ilẹ̀ Yorùbá láàyè.

Àwọn Ọba méjèèjì náà wà béèrè fún ìjíròrò àti ifọwọsowọpọ laarin itẹ isẹmbaye méjèèjì pẹlu àfikún pe lati ipasẹ̀ ìfẹ́ nìkan ni ìlọsíwájú fi le bá ilẹ Yoruba.

"Ọjọ́ Manigbagbe ni ọjọ́ òní jẹ nínú ìtàn ilẹ̀ Yorùbá, a sì ti mú ní ọkunkundun láti wá Irẹpọ laarin awọn ọmọ Yorùbá lọkunrin ati lóbìnrin, ká sì ṣe agbega ẹmi ibọwọ fun ara ẹni tí a jogún láti ọwọ́ awọn baba ńlá wa."

Ágbékalẹ̀ Ìgbìmọ̀ àpapọ̀ tó wà fun irẹpọ ilẹ̀ Yorùbá gbérasọ

Nibi ètò idoola aáwọ náà tún ní wọ́n ti kéde àgbékalẹ̀ Ìgbìmọ̀ àpapọ̀ tó wà fún irẹpọ ilẹ̀ Yorùbá.

Àfojúsùn Ìgbìmọ̀ náà ni láti gbájúmọ́ ìpèsè àlàáfíà, ààbò àwọn àṣà wa àti wíwà agbega ètò ọrọ̀ ajè pẹlu igbayegbadun àwùjọ yíká ilẹ̀ Kaarọ Oojire.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé náà, bàbá ọlọ́jọ́ ìbí, Kessington Adebutu fi ayọ̀ rẹ̀ hàn pé idoola aáwọ àwọn oríadé méjèèjì náà ṣe ojú òun.

O wa ṣe àpèjúwe ìgbésẹ̀ náà bíi èyí tí yóò mú irẹpọ àti ìlọsíwájú bá gbogbo ọmọ Yorùbá lapapọ.

Lára àwọn èèkànlú tó péjú síbi ètò náà ni àwọn ọba àlàyé, Gbajúmọ̀ ọmọ Yorùbá àti àwọn agbáṣàga nílẹ̀ Yorùbá.

Aláàfin Abimbola Owoade wọ agbada àti Sokoto aláwọ̀ Kọfi àti Goolu, ó dé fìlà abeti ajá, ó fi ìlẹ̀kẹ̀ ńlá méjì sọrun, Ọọ̀ni Adeyeye Ogunwusi dúró sí ẹgbẹ́ Aláàfin, ó na ọwọ́ sókè bíi ọgbà to ń juwọ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Báwo ni aáwọ Ọọ̀ni àti Aláàfin ṣe bẹ̀rẹ̀?

Iporogan bẹ̀rẹ̀ láàrin Ọọ̀ni Adeyeye Ogunwusi àti Aláàfin Abimbola Owoade nínú oṣù kẹjọ ọdún 2025 nígbà tí ariwo sọ lórí òye Ọ̀kanlọmọ ilẹ̀ Yorùbá tí Ọọ̀ni fi gbajumọ olokoowo kan, Jubril Dotun Sanusi jẹ.

Bi ìròyìn ṣe jáde síta nípa òye náà ni Aláàfin gbé ìkéde síta pé Ọọ̀ni kò ní àṣẹ láti fi òye tó kàn gbogbo ọmọ Yorùbá jẹ ní ilé Ife bikoṣe láti ìlú Oyo.

Alaafin wa fún Ọọ̀ni ni wakati mejidinlaadọta láti yí Igbesẹ náà padà àmọ́ Ọọ̀ni kéde pé kí i ṣe oyè Okanlomo ilẹ̀ Yorùbá ni òun fi Sanusi jẹ bikoṣe Okanlomo Oodua.

Ọ̀rọ̀ yìí ló fà awuyewuye pupọ, tí àwọn alatilẹyin Ọọ̀ni àti Aláàfin sì ń sọ òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn.

Láti ìgbà náà ni àárín àwọn oríadé méjèèjì yìí kò ti gún, kò tó di pé wọ́n pàdé níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà.