Inú ẹ̀sìn Islam ni wọ́n bí mi sí àmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan ló dé sí mi, tí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ru igbá Ọbatala - Ọmọ Ayinla Omowura

Àkọlé fídíò, Arugba Obatala
Inú ẹ̀sìn Islam ni wọ́n bí mi sí àmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan ló dé sí mi, tí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ru igbá Ọbatala - Ọmọ Ayinla Omowura

Ọ̀kan lára àwọn òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá ni Ọbatala èyí tí àwọn èèyàn kan ṣì ń bọ títí di òní.

Lọ́pọ̀ ìgbà sì ni a máa ń ṣe alábàápàdé àwọn èèyàn pàápàá àwọn obìnrin tí wọ́n ń bọ òrìṣà yìí tí wọ́n máa gbé ẹrù sórí láti fi yíde káàkiri ìlú.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń wòye láti mọ ohun tó wà nínú ẹrù náà àti ìdí rẹ̀ gan tí àwọn obìnrin náà fi ń ru ẹrù ọ̀hún.

Kabirat Ayinla Omowura, tó jẹ́ ọmọ bíbí gbajúmọ̀ olórin àpàlà, Ayinla Omowura jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó máa ń ru ẹrù náà láti fi bọ òrìṣà Ọbatala.

Ó sọ fún BBC pé láti kékeré ni òun ti máa ń bá wọn kópa níbi ayẹyẹ ọdún náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀sìn Islam ni wọ́n bí òun sí.

Kabirat Ayinla Omowura wọ aṣọ léèsì níbi àwòrán apá ọ̀tún, tó sì wọ aṣọ funfun pẹ̀lú igba lórí

"Ọmọ ọdún mẹ́fà ni àìsàn kan kọlù mí, tí wón kò sì rí ìwòsàn fún àyàfi ìgbà tí wọ́n gbé mi dé ọ̀dọ̀ àwọn oní òrìṣà Ọbatala"

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí òun wà ní ọmọ ọdún mẹ́fà ni àìsàn kan kọlu òun tí wón kò sì rí ìwòsàn fún òun àyàfi ìgbà tí wọ́n gbé òun dé ọ̀dọ̀ àwọn oní òrìṣà Ọbatala.'

Ó ní ibẹ̀ ni wọ́n ti sọ fún àwọn òbí òun pé àfi kí òun máa báwọn ṣe òrìṣà Ọbatala kí òun tó le gbádùn.

"Láti ọdún yẹn ni ìyá ti ń gbémi lọ ṣe òrìṣà yẹn tí wọ́n bá ti ń ṣọdún

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹrù gbígbé náà ṣe máa ń rí lẹ́yìn tí wọ́n bá rù ú tán, ó ní àwọn kìí mọ ohunkóhun tí àwọn bá ń sọ àti pé kìí yé àwọn náà.

Kabirat Ayinla Omowura wọ aṣọ léèsì alawọ buluu ati goolu, o we gele asọ leesi naa, o si fi ilẹkẹ meji sọrun, aworan meji to jẹ ti baba rẹ, tii se gbajumọ akọrin Apala nigba aye rẹ, Ayinla Omowura, wa lara ogiri ti obinrin naa fẹyin ti.

"Kìí ṣe pé òrìṣà náà dédé wu mí láti máa bọ ni mo ṣe darapọ̀ mọ Ọbatala àmọ́ òrìṣà náà gan ló pe mí"

Arugba Ọbatala náà sọ pé àwọn máa sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí àwọn bá ti ru igbá náà tán ṣùgbọ́n nǹkan tí àwọn ń sọ kò lè yé èèyàn àyàfi tí wọ́n bá tu fún èèyàn.

"Ọ̀rọ̀ wa dàbí ẹlẹ́mìí ni, tí ẹlẹ́mìí bá jíṣẹ́ fún un yín nísìnín, tí ara rẹ̀ bá ti walẹ̀, tẹ bá ní kí lẹ sọ fún mi, a sọ pé òun kò mọ̀.

"A ò lè sọ pé nǹkan báyìí là ń sọ tí a bá ti gbé ẹrù rù ṣùgbọ́n tí a kò bá ì tíì gbé ẹrù, a ṣì mọ ohun tí a fẹ sọ.

"Àwọn aṣògùn tó jẹ́ ọkùnrin tí wọ́n máa ń dúró tì wá lẹ́gbẹ̀ẹ́ nìkan ló lè gbọ́ ohun tí à ń sọ, tí wọ́n sì lè tu fún èèyàn.

Kabirat fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kìí ṣe pé òrìṣà náà dédé wu òun láti ṣe ni òun fi darapọ̀ mọ bíkòṣe pé òrìṣà náà gan ló pe òun.