Ṣé òfin fààyè gba Donald Trump láti lọ fún sáà kẹta bíi ààrẹ Amẹ́ríkà?

Aarẹ America, Donald Trump n sọrọ lọwọ ninu aworan yii. O nawọ rẹ kan soke lati ṣakawe, o wọ kootu alawọ aro, ṣẹẹti funfun lo wa ninu aṣọ naa, ati tai alawọ elese aluko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ ilẹ America, Donald Trump, ti ni ohun to ṣee ṣe ni koun dije fun saa kẹta gẹgẹ bii aarẹ ilẹ America.

Trump sọ pe o wu oun lati ṣe bẹẹ.

Abi yoo nifẹẹ lati du ipo igbakeji aarẹ ni 2028 ni awọn akọroyin tun beere lọwọ rẹ lasiko to n rin irinajo lọ si Asia.

Pẹlu bi awọn kan ṣe n gbe e kiri pe Trump le lo ilana igbakeji aarẹ yii ko si fi yẹ ofin to de awọn aarẹ lati ma ṣe lọ fun saa kẹta.

Eyi ni Trump dahun si pe ko yẹ ko ri bẹẹ. O ni bo tilẹ jẹ pe ofin fi aaye gba koun dupo igbakeji aarẹ, iru rẹ ko wu oun.

Ṣugbọn ilana ti aarẹ naa yoo gba fi dije ko ti i fi oju han rara.

Nigba to n tẹsiwaju nipa saa kẹta, Trump sọ pe:

"Mi o ti i ronu nipa rẹ. Ṣugbọn emi naa ni mo ni ibo to pọ ju."

Bakan naa ni Aarẹ Trump sọ pe Igbakeji oun, JD Vance ati Akọwe ijọba; Marco Rubio naa le gbapo lẹyin oun bii aarẹ. O ni wọn ko ṣee da duro rara.

"Ohun ti mo le sọ fun yin ni pe awa ni awọn eeyan nla ti awọn ko ni. ( Iyẹn awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako ti i ṣe Democrats).

Ǹ jẹ òfin fi ààyè gba Trump láti ṣe sáà kẹ́ta?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Abala kejilelogun ofin ilẹ America ko fi aaye gba aarẹ lati lọ fun saa kẹta.

Bi wọn yoo ba yọ ofin yii kuro, wọn yoo nilo ki ida meji ninu mẹta awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju ati aṣofin fi ọwọ si i.

Tabi ki ipade kan ti ida meji ninu mẹta awọn aṣofin yoo gbe kalẹ waye. Eyi ko si jọ pe o ṣee ṣe.

Atunṣe ofin yii yoo tun nilo atilẹyin ipinlẹ mejidinlogoji ko too le wọle labẹ ofin.

Ọsẹ to kọja yii ni olugbani-nimọran fun Trump tẹlẹ, Steve Bannon – to ṣi n ti i lẹyin gidi, sọ pe eto ti wa nilẹ lati jẹ ki Trump lọ fun saa kẹta.

"Trump maa di aarẹ ni 2028, o si yẹ kawọn eeyan jẹ ko wa ni ibamu pẹlu wọn. Nigba ti asiko ba to, a maa ṣiṣọ loju eto naa."

Bannon lo sọ bẹẹ.

Loṣu Kẹta, Trump sọ fun ẹka CNBC pe ko daju pe oun yoo tun dupo aarẹ mọ, bo tilẹ jẹ pe o pada sọ pe ere loun fi ọrọ naa ṣe.

Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni Kamala Harris, igbakeji aarẹ America tẹlẹ, to ba Trump figa gbaga lọdun to kọja naa sọ pe o ṣee ṣe koun naa dupo aarẹ lẹẹkan si i.

Bakan naa ni Gomina California, Gavin Newsom, naa sọ fun ẹka CBS, alajọṣẹ BBC, pe oun naa nifẹ lati dupo aarẹ America.

Ibi ti ọwọ aago ipo aarẹ naa yoo fi si ko ti i ye ẹnikan.