Mo ṣì lè du ipò ààrẹ Amẹ́ríkà lẹ́ẹ̀kan sí, gbogbo ohun tí mo kìlọ̀ nípa Trump ló ti ń ṣẹlẹ̀ - Kamala Harris

Kamala Harris, Igbakeji aarẹ America tẹlẹ lo n rẹrin ẹyẹ yii. O da irun rẹ walẹ, o si wọ aṣọ oyinbo ti awọ rẹ dudu, pẹlu funfun ninu rẹ.
Àkọlé àwòrán, Kamala Harris, Igbakeji aarẹ America tẹlẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bi ẹsin ba da ni, a maa n tun un gun ni.

Igbakeji aarẹ ilẹ America tẹlẹ, Kamala Harris, ti sọ pe oun ko ti i pari eto oṣelu oun, o ni oun ṣi le du ipo aarẹ ilẹ America lẹẹkan si .

Kamala to sọrọ yii fun BBC ninu ifọrọwerọ akọkọ rẹ ni UK, ṣalaye pe oun le di aarẹ America lọjọ kan.

Obinrin to ba Aarẹ Donald Trump figa gbaga lọdun to kọja naa sọ pe oun gbagbọ pe obinrin yoo di aarẹ America lọjọ iwaju.

O ni bo tilẹ jẹ pe oun ko ti i pinnu bi yoo ṣe jẹ, igbagbọ oun ni pe o ṣee ṣe koun dupo naa ni 2028 ti saa Trump yoo pari.

Harris sọ pe awọn ọmọ iyekan oun yoo foju ri i pe obinrin di aarẹ America, o si ṣee ṣe ko jẹ oun ni aarẹ naa.

" Mi o ti i pari, inu egungun mi ni ka ṣiṣẹ sin wa, ohun ti mo ti n fi akoko iṣẹ mi ṣe niyẹn."

Bẹẹ ni Kamala Harris wi.

"Gbogbo ohun tí mo kìlọ̀ nípa Trump ló ti ń ṣẹlẹ̀"

Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Kamala sọ pe awọn ohun ti oun kilọ pe Trump yoo danwo to ba di aarẹ America ti n ṣẹlẹ bayii.

O ni oun kilọ pe Aarẹ Trump yoo maa ṣe bii apaṣẹ-waa ni, o si ti n ṣe bẹẹ.

" Trump leri pe oun yoo lo ẹka idajọ lati le awọn eeyan ti ko ba fẹran kuro, ohun to dẹ n ṣe naa niyẹn."

Kamala fi bi ileeṣẹ igbohusafẹfẹ ilẹ America, American Broadcasting Company (ABC) ṣe da adẹrin-in-poṣonu Jimmy Kimmel, duro, nitori iyẹn fi bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican ṣe huwa nigba ti wọn pa Charlie Kirk toun naa jẹ sọrọsọrọ, ṣe ẹfẹ.

O ni Trump ṣajọyọ idaduro naa.

"Ti ẹ ba wo ohun to n ṣẹlẹ, o ti lo awọn ẹka ijọba apapọ lati le awọn to n fi ọgbọn sọ aleebu ijọba rẹ danu.

"Ara rẹ ko gba awada bintin tabi titọka aleebu rẹ, o si tori ẹ fẹ ti odidi ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ pa."

Kamala Harris lo sọ bẹẹ.

Ó yẹ kí Kamala Harris ti mọ pe awọn eeyan Amẹ́ríkà ko gba irọ to n pa wọle mọ - iléeṣẹ́ Ààrẹ Amẹ́ríkà fèsì

Bakan naa ni Igbakeji Joe Biden nigba kan yii bu ẹnu atẹ lu awọn olori okoowo ti wọn sọ ara wọn di ẹru Aarẹ Trump.

O ni gbogbo aṣẹ to ba pa fun wọn ni wọn n sare tẹle ki wọn le sunmọ aarẹ, ri oju rere rẹ tabi ko ma baa wadii wọn.

BBC kan si ileeṣẹ Aarẹ America lati gbọ ero wọn nipa ọrọ ti Kamala Harris sọ, ṣugbọn wọn ko ka ọrọ obinrin naa kun rara.

Agbẹnusọ ile ijọba America, Abigail Jackson, sọ pe: "Nigba ti Kamala Harris padanu ibo to foju han gedegbe bẹẹ, o yẹ ko ti mọ pe awọn eeyan America ko gba irọ rẹ to n pa wọle mọ.

"Boya o si ti ye e naa lo ṣe n lo awọn ẹka iroyin ilẹ okeere lati fi ẹhonu rẹ han."

Ṣugbọn pẹlu aridaju ti Kamala Harris fi ṣalaye ọrọ fun BBC, obinrin naa ko ṣetan lati yi ipinnu rẹ pada.