'À ń bẹ̀rù ẹ̀mí wa' - àwọn àgbẹ̀ tó ń kojú Boko Haram sọ̀rọ̀ síta

Aisha Isa dúró ní ẹ̀gbẹ́ oko kan ní ìlú Darwa, ó fi ọwọ́ sí àgbọ̀n

Oríṣun àwòrán, Ayo Bello / BBC

Àkọlé àwòrán, Aisha Isa wà lára àwọn àgbẹ̀ tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò máa ń ṣọ́
    • Author, Ijeoma Ndukwe
    • Reporting from, Borno state
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bí àwọn kan ṣe ń wọ́n omi sí ẹ̀fọ́, táwọn míì ń tu kóko nínú ọgbà nǹkan ọ̀gbìn wọn ní ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà, àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò dúró tì wọ́n pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà ni wọ́n ń pè ní Agro Rangers – ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ ààbò tí ìjọba gbé dìde láti máa dá ààbò bo àwọn àgbẹ̀ lọ́wọ́ àwọn agbéṣùmọ̀mí Boko Haram àti Islamic State West Africa Province (ISWAP), tó máa ń ṣe ìkọlù sáwọn àgbẹ̀ nínú okò ní ìpínlẹ̀ Borno nígbàkúgbà.

"Ìbẹ̀rù ni èyí – à ń bẹ̀rù ẹ̀mí wa," Aisha Isa, ẹni àádọ́ta ọdún sọ fún BBC bó ṣe ń mójútó oko rẹ̀.

Nítorí àìsí ààbò fún òun àtàwọn ẹbí rẹ̀ ni wọ́n ṣe sá kúró nílé ní ọdún mọ́kànlá sẹ́yìn, òun àtàwọn míì bíi tirẹ̀ ni wọ́n kó lọ sí ìlú Dalwa ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti ibìkan ní ìlú Maiduguri, olú ìlú ìpínlẹ̀ Borno.

Ibùgbé kan ni wọ́n ń gbé báyìí, tó sì jẹ́ pé ẹ̀wà àti àgbàdo tó ń gbìn ni ọ̀nà tí òun àti ẹbí rẹ̀ fi ń rí oúnjẹ jẹ báyìí.

"A máa ń fi orí la ewu láti wá sí oko bí àwọn Agro Rangers kò bá wá."

Níbí, iléeṣẹ́ ológun ti ṣàmì sí ilẹ̀ tí àwọn èèyàn le dákó lé lórí. Tí wọ́n bá kọjá ààlà náà, ó ṣeéṣe kí ìdúnkokò àwọn ológun wáyé.

"Ati ń gbọ́ pé wọ́n ń jí àwọn èèyàn gbé," Mustapha Musa, ẹni ọdún méjìlélógójì sọ. "Wọ́n ti pa àwọn èèyàn kan. Ìdí nìyí tí ẹ̀rù fi máa ń bàmí, tí mi ò kìí fẹ́ dáwá láìsí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò."

Bàbá ọlọ́mọ mẹ́wàá náà sọ pé òun fi ìlú òun, Konduga sílẹ̀ ní ọdún mẹ́tàlá sẹ́yìn àti pé òun kò ní padà síbẹ̀ àyàfi tí ìjọba bá mójútó ètò ààbò ní agbègbè náà pátápátá.

Láti bíi ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́yìn tí àwọn agbéṣùmọ̀mí ti ń ṣọṣẹ́ ní ẹkùn ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn ló ti jáde láyé, tí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn sì ti fi ilé wọn sílẹ̀.

Iye àwọn àgbẹ̀ tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú àwọn ìkọlù sáwọn oko ní ọdún yìí nìkan ti lékún lọ́nà ìdá méjì sí ti ọdún 2024 gẹ́gẹ́ bí ìwádìí Armed Conflict Location and Event Data (ACLED) ṣe sọ.

Síbẹ̀, gómìnà ìpínlẹ̀ Borno ń gbé ìgbésẹ̀ láti ri pé àwọn èèyàn tó ń ṣe àtìpó ní àwọn ibùdó tí ìjọba pèsè bẹ̀rẹ̀ oko dídá lójúnà àti pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu.

Ọkùnrin tó wọ aṣọ ẹ̀ṣọ́ ààbò tí wọ́n kọ NSCDC sí, ó gbé ìbọn dání

Oríṣun àwòrán, Ayo Bello / BBC

Àkọlé àwòrán, Ìjọba nàìjíríà ní àwọn fẹ́ mú ìgbòòrò bá Agro Rangers
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bí èèyàn tó tó mílíọ̀nù mẹ́rin ni ó ṣeéṣe kí wọ́n kojú ìṣòro àìsí oúnjẹ ní ẹkùn ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN. Ṣùgbọ́n àwọn àjọ kan ń sọ pé ìgbésẹ̀ gómìnà láti pọnkún ètò ọ̀gbìn náà yá jù.

Àjọ International Crisis Group sọ pé ìgbésẹ̀ náà dàbí fífi àwọn tó ń ṣe àtìpó náà sínú ewu àti pé níṣe ni àwọn ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí náà máa ń lọ àwọn àgbẹ̀ náà lọ́wọ́ gbà láti fi kówó jọ fún àwọn iṣẹ́ láabi wọn.

Abba Mustapha Muhammed mọ̀ nípa àwọn nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò bá tètè rí owó ìtúsílẹ̀ san ní àkàtà àwọn ajínigbé sọ ìrírí rẹ̀ nígbà tí wọ́n jí òun àtàwọn àgbẹ̀ mẹ́sàn-án míì gbé.

"Ẹnìkan wà tí wọ́n pa nítorí kò lè san owó ìtúsílẹ̀. Àwọn ẹbí rẹ̀ kò rí owó kójọ di ìgbà tí wọ́n dá fun, wọ́n sọ òkú rẹ̀ nù nígbà tí wọ́n pa á tán. Wọ́n ní kí àwọn ẹbí rẹ̀ lọ gbé òkú rẹ̀."

Ó sọ pé wíwà ní àhámọ́ nínú ogbó kìí ṣe ohun tó rọrùn rárá.

"Oúnjẹ kékeré tí wọ́n ń fún wa máa ń hú ebi sílẹ̀ ni, tó sì máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ yàgbẹ́ gbuuru. Kò sí omit ó mọ́ fún wa láti mu.

Bàbá ọlọ́mọ mẹ́ta náà sọ fún BBC pé ẹ̀rù ń ba òun láti padà sídìí oko dídá nítorí àwọn agbéṣùmọ̀mí ṣì ń ṣọṣẹ́.

"Ní àná òde yìí, èèyàn mẹ́wàá ni wọ́n jígbé."

Àwọn èèyàn tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ ńlá

Oríṣun àwòrán, Ayo Bello / BBC

Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Mohammed Hassan Agalama, adarí ikọ̀ Agro Rangers ní ìpínlẹ̀ Borno tẹmpẹlẹmọ pé ikọ̀ náà kò jẹ́ káwọn agbéṣùmọ̀mí ṣọṣẹ́.

"A ò tíì ri káwọn agbéṣùmọ̀mí máa padà wá ṣe ìkọlù sáwọn àgbẹ̀ mọ́ nítorí wọ́n mọ̀ pé a wà digbí lásìkò oko dídá," Agalama tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣọ́ ààbò Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC) sọ.

Agbẹnusọ NSCDC, James Bulus sọ fún BBC pé ìjọba ń gbógun tako àwọn agbéṣùmọ̀mí àti pé èrè oko tó wà lọ́dùn yìí ṣàfihàn rẹ̀, pé àwọn àgbẹ̀ ń bá iṣẹ́ wọn lọ.

Ẹ̀wẹ̀, ó gbà pé àwọn ohun èlò láti fi kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí náà kò tó.

Agro Rangers jẹ́ ìgbésẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, kìí ṣe ohun tó máa lọ fún ìgbà pípẹ́ láti kojú ètò ààbò ní ẹkùn náà.

"A ò lè sí ní ibi gbogbo. A ò kìí ṣe iwin. Ṣé gbogbo ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ikọ̀ Agro Rangers le ká gbogbo oko tó wà ní Maiduguri? Rárá."

Fún ìdí èyí, ìjọba àpapọ̀ ń gbèrò láti mú àlékún bá ètò Agro Rangers.

Òṣìṣẹ́ àgbà kan fún ACLED, Ladd Serwat sọ pé iye àwọn aráàlú tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn lọ́dún yìí ti pọ̀ púpọ̀ nítorí ìkọlù tí wọ́n ń ṣe sáwọn àgbẹ̀.

Bákan náà ni ìjábọ̀ sọ pé iye èèyàn tí Boko Haram àti Iswap ti pa ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ló pọ̀ jù láàárín ọdún márùn-ún.

Adam Goni, wọ aṣọ olómi aro, dé fìlà, ó sì ń wo ọ̀ọ́kán

Oríṣun àwòrán, Ayo Bello / BBC

Ní ìlú Maiduguri, àwọn àgbẹ̀ kan péjọ ní ilé Adam Goni, alága ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀ tó ń pèsè ọkàbàbà, National Association of Sorghum Producers, Processors and Markerters.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn agbéṣùmọ̀mí ti ní ipa lórí ayé wọn.

Lára wọn ni Baba Modu, ẹni tí àwọn Boko Haram pa ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún.

"Ó dùn mí gan," ó sọ. "Wọ́n máa ń pa èèyàn bí ẹni pé èèrà ni wọ́n ń pa… Àwọn ìpànìyàn tí a ti fojú rí kò da rárá ṣùgbọ́ ti ọdún yìí lo burú jù… Tí mo bá lọ sóko, ẹ̀rù pé wọ́n le pa mí ló máa ń wà lọ́kàn mi. Kò sí ìfọ̀kànbalẹ̀ fún mi nílé – a ò le di ojú méjéèjì sùn, ẹ̀rù pé wọ́n máa ṣe ìkọlù sí wan í gbogbo ìgbà."

Inú ìrònú ni Modu fi máa ń wà lórí ìjòkòó rẹ̀. Ó ní àìsí ààbò náà ń ní ipa lórí òun àti ìlú náà.

"Kòdá bí ebi bá ń pa èèyàn, tí kò sì sí oúnjẹ, a ò ní lè lọ sí oko. Nígbà tí a bá gbìyànjú, wọ́n máa lé wa tàbí kí wọ́n pa wá. Ní ìbẹ̀rẹ̀, wọ́n máa ń bèèrè owó ìtúsílẹ̀ tí wọ́n bá jí èèyàn gbé àmọ́ wọ́n máa pa èèyàn tí wọ́n jígbé báyìí lẹ́yìn tí wọ́n bá gba owó tán"

Ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ bíi Modu sọ pé agbára àwọn agbéṣùmọ̀mí náà le kọjá àwọn ológun tí wọ́n bá ṣe ìkọlù.

"Àwọn ológun gan máa ń sá tí wọ́n bá rí àwọn agbéṣùmọ̀mí nígbà míì."

Ní apá kan ọgbà náà, Goni ń mójútó oko ọ̀dùnkún.

Ó sọ fún BBC pé òun ní ilẹ̀ eékà mẹ́rìnlélógún tó yẹ kí òun lọ kó èrè oko ibẹ̀ ní ibi tí kò ju máìlì márùn-ún sí wọ́n lọ àmọ́ ẹ̀rù ń ba òun láti lọ síbẹ̀.

Ó ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni àwọn agbéṣùmọ̀mí pa àgbẹ̀ kan tó ní oko ní ẹ̀gbẹ́ oko òun.

"Kò sí ààbò, a kàn ń fi ẹ̀mí ara wa wé ewu láti lọ síbẹ̀ nítorí àwọn Boko Haram wà ní gbogbo oko wa."

Goni gbàgbọ́ pé àwọn ológun ṣì lè ṣiṣẹ́ láti fòpin sí ìwà ìgbéṣùmọ̀mí tó ń wáyé ní ẹkùn náà.

"Inú ń bí wa gidi gan. Inú wà kò dùn sí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀. Tí ìjọba bá mọ ohun tí wọ́n ń ṣe, wọ́n máa rẹ́yìn Boko Haram láàárín oṣù kan ní Nàìjíríà."

Ẹ̀wẹ̀, Bulus sọ pé iléeṣẹ́ ológun ń kojú ìgbéṣùmọ̀mí náà.

"Àlááfíà ń padà sípò díẹ̀díẹ̀. Kìí ṣe ohun tó ṣeéṣe lọ́jọ́ kan."

Àmọ́ ìgbésẹ̀ náà ti ń pẹ́ fún àwọn àgbẹ̀ yìí. Láti bíi ọdún mẹ́ẹ̀dógún báyìí, àìsí ààbò ń ní ipa lórí ìgbé ayé wọn gbogbo.

BBC kàn sí iléeṣẹ́ ológun lórí ohun táwọn àgbẹ̀ náà sọ pé wọ́n kò ṣiṣẹ́ tó láti dá ààbò bò wọ́n àmọ́ wọn kò tíì fèsì.