Kílódé tí a máa ń jí kalẹ̀ láàárín òru láì rí oorun sùn?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ̀pọ̀ àgbàlagbà ló máa ń jí ní òru, láàárín aago mẹ́ta sí aago mẹ́rin tí wọn kò sì ní rí oorun sùn mọ́ títí tí ilẹ̀ fi máa mọ́.
Ọ̀pọ̀ ni kìí mọ ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì máa ń kọminú lórí ohun tó ń fa èyí lójoojúmọ́.
Dókítà Greg Murray, Adarí ẹ̀ka ìlera ọpọlọ ní Australia, tó ń pèsè ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ìlera ọpọlọ sọ pé jíjí láàárín aago mẹ́ta òru jẹ́ ohun tí nǹkan tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń kojú láti dé ìgbà.
Ó ní èyí le fa àìlera tó bá ti di ohun tí ohun fí ojoojúmọ́ wáyé, tó sì nílò àmójútó.
Ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta èèyàn tó wà ní Amẹ́ríkà ló máa ń jí láàárín òru, tó sì jẹ́ pé iye rẹ̀ ti lékún lẹ́yìn tí ààrùn coronavirus gbòde.
Dókítà Murray sọ pé kìí ṣe wàhálà ni kìí jẹ́ kí ọ̀pọ̀ rí oorun sùn láàárín òru.
"Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èèyàn máa ń jí kalẹ̀ láàárín òru pàápàá nígbà tí ilẹ̀ bá dúdú biribiri. A sì máa ń sábà gbàgbé àwọn jíjí yìí," Dókítà Murray sọ.
"Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ nǹkan, bíi àárẹ̀ ara, ló máa ń fa kí èèyàn máa jí kalẹ̀ láàárín òru."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun tí èèyàn ń ṣe ní ojoojúmọ́, bíi láti máa gbèrò bí ọjọ́ wọn yóò ṣe rí, wíwo ìròyìn lórí ìkànnì ayélujára, nígbà míì, ó lè jẹ́ àìsí atẹ́gùn tó bẹ́ẹ̀ nínú yàrá le ṣokùnfà ohun tó le máa mú èèyàn jí kalẹ̀ láàárín òru.
Stephanie Romiszewski, onímọ̀ nípa oorun ní ilé ìwòsàn Sleepyhead ní London mú ìmọ̀ràn wá pé nígbà tí èèyàn bá jí kalẹ̀ lórù, ó sàn kí èèyàn dìde tí èèyàn bá ti jí kalẹ̀ lórù, kí èèyàn sì má padà sórí ìbùsùn títí di ìgbà tí oorun tún fi máa kun èèyàn padà.
Ó ní nígbà tó bá yá èèyàn máa padà rí àyípadà, èèyàn máa padà máa jí lásìkò kan, tó sì máa padà di ohun tí èèyàn ń ṣe.
Romiszewski tún ní ó dára láti máa ṣe eré ìdárayá, gba oòrùn sára ní àárọ̀.
"A nílò láti jẹ́ kí ọpọlọ wa mọ̀ pé ẹ̀ẹ̀kan ní a ní láti fi sùn àti pé alẹ́ ni àsìkò náà tàbí tí kò bá jẹ́ alẹ́ láwọn àsìkò míì."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ó ní ohun tó fà á tí ẹlòmíràn fi máa ń jí ní òru ni pé wọn kò ní sùn títí di aago mọ́kànlá sí aago méjìlá òru tó sì jẹ́ pé bíi aago méje sí mẹ́jọ àárọ̀ ni wọ́n máa ń jí. Èyí túmọ̀ sí pé aago mẹ́ta sí mẹ́rin òru ni àsìkò àárín oorun wọn jẹ́.
Dókítà Aneesa Das, Adarí ètò oorun ní ẹ̀ka Sleep Program ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Ohio State University sọ pé àsìkò oorun máa ń ṣe ségesège láti ìgbà dégbà pàápàá tí èèyàn bá ń lá àlá. Ó ní ẹnikẹ́ni ló lè jí láwọn àsìkò yìí.
"Ìdí tí tí a fi máa ń jí ní àsìkò kan náà ni pé a máa ń sùn lásìkò kan náà ní ojoojúmọ́, tí ilẹ̀ bá ṣe ń mọ́ ni oorun máa ń díkùn."
Dókítà Michael Scullin, Ọ̀jọ̀gbọ́n ní ilé Baylor University ní Amẹ́ríkà ní ìdí tí èèyàn fi máa ń jí ní ààrín òru nígbà míì le jẹ́ nítorí àlá tí kò dára.
"àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti bíi ọgọ́rùn-ún ọdún gbà pé tí èèyàn kò bá parí iṣẹ́ kan tàbí tí èèyàn bá ń ṣe iṣẹ́ kan lọ́wọ́ le mú kí ọpọlọ èèyàn jí kalẹ̀."
Ẹ̀wẹ̀, Romiszewskiwòye pé tí èèyàn bá máa ń jí kalẹ̀ láàárín aago mẹ́ta òru sí mẹ́rin tó ti ń lé ní oṣù mẹ́ta, ó yé kí ẹni náà lọ rí àwọn dókítà nítorí à ti tètè mójúto kó tó di ohun tí kò ní ṣe é mójútó mọ́ lásìkò.












