Ìwé ìrìnnà ilẹ̀ America já kúrò lára àwọn ìwé ìrìnnà tó lágbára jùlọ lágbàáyé

Aworan Aarẹ Donald Trump ati iwe irinna

Oríṣun àwòrán, Grace Cary via Getty Images/ AFP via Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iwe irinna orilẹede Amẹrika ti ja kuro ni ipo to wa oke tabili orilẹede mẹwaa lẹyin to ti lo ogun ọdun, iwadii Henley Passport ṣalaye.

Iwadii Henley Passport lo awọn iroyin ti wọn gba lati ọdọ International Air Transport Association to n gbe awọn iwe irinna sori isọri, eyi to da lori agbara awọn iwe irinna lia nilo fisa.

Wọn se iwadii lori awọn iwe irinna ti o le wọ orilẹede naa lai nilo fisa.

Iwe irinna US wa ni ipo kejila pẹlu iwe irinna orilẹede Malaysia.

Ni ọdun 2024, iwe irinna US wa ni ipo keje tẹle, ko to gbera walẹ si ipo kẹwaa ni oṣu keje ọdun yii. Ṣugbọn ni oṣu kẹwaa, Iwe irinna US ko si laaarin awọn orilẹede mẹwaa ti iwe irinna wọn lagbara ju lagbaye.

Alaga Henley&Partner ati oludasilẹ Henley Passport, Christian H Kaelin sọ pe ijakulẹ iwe irinna US waye nitori bi agbara se kuro ni ọwọ wọn.

"Ijakulẹ iwe irinna US fun o le ni ọdun mẹwaa lo da lori bi agbara se n kuro lati ibi kan sibi kan.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn to ni iwe irinaa US le lọ si orilẹede 180 pẹlu fisa ọfẹ, eyi le jẹ pe awọn orilẹede kan fi ofin de Amẹrika nitori US faye gba orilẹede 46 laye lati wọ orilẹede wọn.

Aarẹ Trump fofin irinna de awọn orilẹede mejila ni Afrika, Middle East ati Guusu Asia, to si tun dun koko mọ awọn orilẹede Afrika pẹlu iwe irinna, ti wọn yoo sisan owo toto 5,000 si 15, 0000 owo dọla.

Bakan naa ni iwe irinna UK ti jasi ipo kẹjọ lati ipo kẹfa ni oṣu keje.

Lọwọ bayii, awọn orilẹede Asia lo wa ni ipo to ga, pẹlu orilẹede Singapore n leke pẹlu anfani lati wọ orilẹede 193 lia nilo fisa pẹlu South Korea ati Japan si wa ni ipo keji si kẹta.

Iwe irinna Naijiria wa lara awọn orilẹede mẹwaa ti iwe irinna ko ja fafa lagbaye.

Naijiria wa ni ipo 96, ti wọn si n pin aye pẹlu orilẹede Ethiopia, Lebanon ati Myanmar, awọn orilẹede yii ni anfani si orilẹede 44 pere.

Seychelles ni orilẹede Afrika to lagbara ju pẹlu anfani lati wọ orilẹede 155 lagbaye.

Lẹyin naa ni Botswana, Namibia, Lesotho, eSwatini, Morocco, Malawi, Kenya, Tanzania, ti Gambia ati Ghana si tẹle.

Awọn iwe irinna orilẹede mẹwaa to lagbara ju

  • Singapore pẹlu fisa ọfẹ si orilẹede 193
  • South Korea pẹlu fisa ọfẹ si orilẹede 190
  • Japan pẹlu fisa ọfẹ si orilẹede 189
  • Germany, Italy, Luxembourg, Spain ati Switzerland pẹlu fisa ọfẹ si orilẹede 188
  • Austria, Belgium Denmark, Finland, France, Ireland ati Netherlands pẹlu fisa ọfẹ si orilẹede 187
  • Greece, Hungary New Zealand, Norway, Portugal ati Sweden pẹlu fisa ọfẹ si orilẹede 186.
  • Australia, Czechia, Malta ati Poland pẹlu fisa ọfẹ si orilẹede 185.
  • Croatia, Estonia, Slovakia, Slovenia, United Arab Emirates ati United Kingdom pẹlu fisa ọfẹ si orilẹede 184.
  • Canada pẹlu fisa ọfẹ si orilẹede 183.
  • Latvia ati Liechtenstein pẹlu fisa ọfẹ si orilẹede 182.