Ìfẹ́ látinú àtìmọ́lé! Mùsùlùmí Ọmọ Afganistan fẹ́ ọmọ ẹ̀yà Jew lábẹ́ ìṣàkóso Taliban

Sammi and Safi wọ aṣọ igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Sammi Cannold

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Nigba ti Kabul ko sọwọ Taliban ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2021, gbogbo aye lo wo bi ọpọ araalu ṣe ya bo papakọ ofurufu lati fi ilu orilẹede naa silẹ.

Ni Washington to jẹ olu ilu orilẹede Amẹrika, ọkunrin kan ti to ti fi akoko igba kan ṣiṣẹ fun ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi, Safi Rauf bẹrẹ iṣẹ ni idankọnkọ lati doola awọn ọrẹ ati mọlẹbi rẹ to ha si Afganistan.

Amọ ko mọ pe ibi ti oun yoo ti maa doola awọn eeyan loun yoo ti pade ẹni bii ọkan oun.

Koda, ẹni ti yoo fẹ naa yoo jẹ ẹya Jew to tun jẹ ẹlẹsin miran.

O ni "mo kọkọ ran ẹni kinni lọwọ, mo bọ si ẹnikeji, ẹni kẹta, titi iti ṣẹ naa fi di nla pẹlu ọpọ eeyan ni Afganistan ati Amẹrika.

Sammi lọjọ igbeyawo wọn

Oríṣun àwòrán, Sammi Cannold

Safi, ti wọn bi si agọ awọn ogunlende to si lọ silẹ Amẹrika ko to pe ẹni ogun ọdun n ṣiṣẹ idoola ẹmi naa.

Asiko to n ṣiṣẹ idoola ẹmi naa lo pade Sammi Cannold, to n gbe niluu New York amọ to n gbiyanju lati doola ibatan rẹ kan kuro ni Kabul.

Sammi ati Safi joko labẹ aburada

Oríṣun àwòrán, Sammi Cannold

Sammy ni "mi o mọ ẹnikankan ri. Mo ṣadede ri iroyin nipa ẹgbẹ Safi lori ẹrọ amohunmaworan, lẹyin naa ni mo kọwe si wọn fun iranlọwọ, o si fesi pada pe mo ni lati lọ si Washington lati ṣiṣẹ pẹlu awọn eeyan rẹ nibẹ."

Obinrin naa di igba di agbọn rẹ, o wọ ọkọ oju irin, o gba ilu Washington lọ nibi to ti pade awọn ajagunfẹyinti.

Sammi ko mọ ohunkohun nipa Afganistan amọ o ni awọn imọ kan ti yoo wulo fun lọhun.

Sammy nileeṣẹ ọmọ ogun ilẹ Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Safi Rauf

Àkọlé àwòrán, Ọdun 2010 ni Sammi lọ iẹ Amẹrika ko to darapọ mọ ileeṣẹ ọmọ ogun

Ọrọ ifẹ ninu laasigbo

Bo tilẹ pe oniruru rogbodiyan lo n waye nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ, nnkan mii tun n lọ labẹle nibẹ.

Sami ni lootọ loun nifẹ Safi, koda oun ṣewadii rẹ loju opo Google gan lati mọ ọjọ ori rẹ boya o ti to ẹni to le ni ololufẹ.

O ni "O ṣe ọpọlọpọ wahala lasiko naa ti oju rẹ fi gbo ju ọjọ ori rẹ lọ nigba naa."

Nigba ti wọn kọkọ jọ rin papọ, aago mẹta oru ni lasiko ti wọn n reti lati pade awọn ogunlende ti awọn ọmọ ogun Taliban tu silẹ.

Wọn rin gba inu gbagede nla ti Washington titi ti wọn fi de Lincoln Memorial.

Gbagede Lincoln Memorial ni Washington DC ti ere ifẹ wọn ti bẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gbagede Lincoln Memorial ni Washington DC ti ere ifẹ wọn ti bẹrẹ

Sami ni "niṣe lo dabii fiimu ti mo si n bere lọwọ ara mi pe ṣe mo si maa fẹ bọbọ yi ṣa?"

Lẹyin naa ni wọn fi ẹnu ko ara wọn lẹnu ki wọn to bẹrẹ si n jiroro lori awọn nnkan mii bii ọkọ ayọkẹlẹ, aṣa ilẹ wọn atawọn nnkan mii

Safi ati Sammi duro lẹgbẹ ara wọn ninu aṣọ alarabara

Oríṣun àwòrán, Sammi Cannold

"Safi maa n bere lọwọ mi boya mo maa fi ou oun han awọn mọlẹbi mi amọ mo maa da lohun pe ko jọ."

Awọn mọlẹbi Safi ti wọn jẹ Musulumi n reti ko fẹ ọmọ orilẹede Afganistan ti baba rẹ wa ọkọ fun amọ Sammi jẹ ẹya Jew.

Sammi n ba awọn ọrẹ rẹ sọrọ

Oríṣun àwòrán, Andy Henderson

Àkọlé àwòrán, Sammi n ba awọn ọrẹ rẹ sọrọ

Akoko igbekun

Ninu oṣu Kejila ọdun 2021, Safi pada si Kabul fun iṣẹ idoola ẹmi pẹlu aburo rẹ ọkunrin bo tilẹ jẹ pe wọn kilọ fun pe ko ma lọ amọ o ni awọn ọmọ ogun Taliban ko ni fọwọ kan oun.

Ṣugbọn lọjọ to kẹyin to yẹ ki wọn lo ni Afganistan ni Taliban ji oun, aburo rẹ ati ọmọ ilẹ okere marun un mii gbe.

Sammi, pẹl iya rẹ niluu New York

Oríṣun àwòrán, Sammi Cannold

Àkọlé àwòrán, Sammi, pẹl iya rẹ niluu New York

Ibẹrubojo gba ọkan Sammi niluu New York to wa, nigba ti yoo wo ibi ti olulufẹ rẹ wa lori foonu, o ri pe ọgba Taliban lo wa.

O ni mi o mọ ọpọ ibi ni Kabul amọ mo mọ pe ipo to wa ko daa rara.

Safi atawọn ologun akẹgbẹ rẹ l'Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Safi Rauf

Ninu igbekun to wa, o fun ọkan lara awọn to n ṣọ lowo lati gba foonu ko le pe ololufẹ rẹ.

Ọjọ kẹtadinlogun to wa ni ahamọ lo to ri aye lati pe e.

Gẹgẹ bii ohun ti Safi sọ, ko foju kan oorun fun ọgọrin ọjọ akọkọ rẹ ni ahamọ Taliban.

Safi in military uniform smiling at the camera while holding a phone

Oríṣun àwòrán, Safi Rauf

Àkọlé àwòrán, Safi says he clung to memories of Les Mis during his captivity to stay strong

Ipade pẹlu awọn obi

Sammi ati Safi pẹlu awọn obi wọn lọjọ igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Sammi Cannold

Ko rọrun lati jiroro pẹlu Taliban amọ nigba ti yoo di aadọrin ọjọ ni ahamọ, wọn fẹnuko lati fi Sammi silẹ.

Sammi ni wọn dunkoko lati pa oun lasiko kan ti ijọba Amẹrika ko ba tete gbe igbesẹ.

Safi ati Sammi pẹlu awọn ti jọjọ kuro ni fghanistan

Oríṣun àwòrán, Safi Rauf

Àkọlé àwòrán, Safi ati Sammi pẹlu awọn ti jọjọ kuro ni fghanistan
Lẹyin ọjọ marunlelọgọrun ti Safi gba ominira lati lọ pade Sammi

Oríṣun àwòrán, Sammi Cannold

Àkọlé àwòrán, Lẹyin ọjọ marunlelọgọrun ni Safi gba ominira lati lọ pade Sammi

Igbeaye wọn papọ

Nigba ti wọn pada pade ara wọn nilẹ Amẹrika, wọn bẹrẹ si n gbe ninu ile kan naa.

Safi ati Sammi wọ aṣọ pupa gẹgẹ bii tọkọtaya

Oríṣun àwòrán, Sammi Cannold

Àkọlé àwòrán, Safi ati Sammi wọ aṣọ pupa gẹgẹ bii tọkọtaya

Lẹyin naa ni wọn ṣe igbeyawo ti wọn si da aṣa Jew ati Afganistan pọ mọra wọn ninu ile gẹgẹ bi tọkọtaya.

Ọjọ igbeyawo wọn ree pẹlu ẹbi ati ara

Oríṣun àwòrán, Sammi Cannold

Àkọlé àwòrán, Aworan ọjọ igbeyawo wọn ree