NDLEA fi kélé òfin gbé Pretty Mike, èèyàn 100 míì, lórí ẹ̀sùn lílo oògùn olóró

Pretty Mike kootu oyinbo alawọ miliki, o wọ shaat alawọ waini, o si lo tai alaranbara, o fi ọda goolu kun irun rẹ, o lo igo dudu soju, o si ki ọwọ ọtun bọ apo rẹ. Asọ alawọ waini lo wa lẹyin rẹ, gilaasi kan wa lara ogiri ni ọwọ alaafia rẹ, igi kan to gbe ododo duro si wa ni apa ọtun.

Oríṣun àwòrán, Pretty Mike Of Lagos

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ to n gbogun ti lilo ati tita oogun oloro ni Naijiria, NDLEA, ti fi ṣikun ofin gbe gbajumọ onifaaji ilu Eko, Mike Eze Nwalie Nwogu ti ọpọ mọ si Pretty Mike.

Ninu atẹjade kan ti NDLEA fi lede, wọn ni awọn fi ofin gbe Pretty Mike atawọn eeyan mii to le lọgọrun ninu ile ijo rẹ lasiko ti awọn eeyan n ṣee faaji pẹlu oogun oloro nibẹ.

Atẹjade ọhun sọ pe "NDLEA ti fi panpẹ ofin mu eeyan to le ni ọgọru ninu ile ijo Proxy Night to wa ni ojule keje, adugbo Akin Adesola, Victoria Island, niluu Eko, nibi ti wọn ti n gbafẹ pẹlu oogun oloro.

"Lara awọn ti a mu ni ẹni to ni ile ijo naa, Mike Eze Nwalie Nwogu ti inagijẹ rẹ n jẹ Pretty Mike, wọn si ti wa lakata fun ayẹwo."

NDLEA sọ siwaju si pe ọpọlọpọ paali oogun oloro ni wọn ri gba lọwọ awọn to wa nile ijo naa ati ninu yara ti wọn n ko ẹrọ pamọ si nibẹ.

Atẹjade naa ti agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi buwọlu sọ pe awọn ya bo ile ijo ọhun lẹyin ti awọn kan ṣi awọn ni gbẹre ipakọ pe ariya oogun oloro yoo waye nibẹ.

Pretty Mike gbajumọ fun bo ṣe maa n mura ati bo ṣe maa n ko awọn obinrin lọ si ode ariya.

Lasiko ti wọn yabo ile ijo naa, NDLEA sọ pe awọn ri koro oogun oloro 450,000 to fi mọ ẹgbẹgbẹrun oogun tramadol ati exol-5, cocaine, skunk, skuchi, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ta ni Pretty Mike?

Gbajumọ onifaaji ni Pretty Mike, o tun jẹ oniṣowo ati oludasilẹ ile ijo Proxy Night to wa niluu Eko.

Lara nnkan to mu ko gbaumọ ni bo ṣe maa n wọ ode atiya pẹlu aṣọ alaranbara atawọn obinrin to si maa n milẹ titi lori ayelujara.

Igba kan wa to wọ ode ariya pẹlu awọn obinrin to so okun aja mọ lọrun, nigba mii o tun wọ ode ariya pẹlu awọn obinrin alaboyun, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Nigba to ba BBC sọrọ lọdun 2021, o ni eremọde ati faaji lasan lawọn nnkan alaranbara toun maa n ṣe.

O fi kun pe o maa n gba oun ni ọpọ oṣu lati pilẹ awọn nnkan ti oun maa n ṣe to maa n milẹ titi lori ayelujara.

Nipa awọn to maa sọrọ abuku nipa rẹ, Pretty Mike ni gbogbo ọrọ alufanṣa ti awọn eeyan maa n sọ nipa oun ko tu iru kankan lara oun, oun ko si gbe igbeaye oun lati tẹ areye lọrun.