Iléẹjọ́ ti dá wa láre, mó ń padà sí gáréèjì bíi alága NURTW l‘Oyo lẹ́yìn ìdádúró ọ̀dún mẹ́fà àmọ́ a kò ní fa wàhálà - Ejiogbe

Abideen Olajide wọ aṣọ ẹgbẹ́ NURTW, àwọn òṣìṣẹ́ NURTW míì wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún

Oríṣun àwòrán, NURTWOMOORILE/FACEBOOK

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Alága ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́kọ̀ National Union of Road Transport Workers, NURTW, Alhaji Abideen Olajide tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ejiogbe ti sọ pé òun ti ṣetán láti padà sẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn.

Ejiogbe, nígbà tó ń bá BBC News Yoruba sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá, ọdún 2025 sọ pé, òun ti ń gbáradì láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àwọn padà nígbà tí ilé ẹjọ́ ti dá àwọn láre.

Ó ní gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ lábẹ́ òfin ni àwọn ti tẹ̀lé láti ìgbà tí gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti fòfin dé ẹgbẹ́ àwọn láti ọdún mẹ́fà sẹ́yìn.

Ó fi kun pé gbogbo sùúrù tí àwọn ti ṣe náà ti so èso rere fáwọn báyìí, tàwọn sì ti gbáradì láti padà sẹ́nu iṣẹ́ àwọn.

"Ìjọba ní àwọn gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ wa, a dẹ lọ sílé ẹjọ́, ilé ẹjọ́ ní àti gbígbẹ́sẹ̀ lé wọn, àti dídáwa dúró lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n ní àwọn da gbogbo ẹ nù, kí ló dẹ̀ tún kù? Ka padà sẹ́nu iṣẹ́ wa ni na."

Iṣẹ́ wa lá fẹ́ gbà padà, a ò ní fa wàhálà

Ejiogbe sọ pé láti ìgbà tí ilé ẹjọ́ ti dá àwọn láre ni àwọn ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti ri pé pípadà sẹ́nu iṣẹ́ kò mú wàhálà kankan dání.

Ó ní láti bíi ọdún mẹ́fà tí wọ́n ti dáwọn dúró ni àwọn ti ń gba àlááfíà láàyè, àwọn yóò sì ri dájú pé kò ní sí wàhálà kankan báyìí lẹ́yìn tí àwọn ti gba ìdájọ́.

"Àwa tí a ò ṣe jàgídíjàgan, ọdún kẹfà rèé tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo lábẹ́ gómìnà Seyi Makinde tó ti gbẹ́sẹ̀ lé ẹgbẹ́ wa, tó ní eégún ẹgbẹ́ wa kò gbọdọ̀ ṣẹ́ mọ́.

"A ò wá fa wàhálà láti ọdún mẹ́fà, ṣé nísìn-ín tí Ọlọ́run ṣe é tí a wá gba ìdájọ́ la ma wá fa wàhálà? A ò ní wàhálà kankan tí a fẹ́ fà.

Alága NUTRW náà ní òun ní ìgbàgbọ́ pé Gómìnà Seyi Makinde máa tẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́, tí wọ́n sì máa gba àwọn láàyè láti padà sẹ́nu iṣẹ́ àwọn láì sí wàhálà kankan.

Ó ní òun mọ̀ pé nígbà tí àwọn bá ti bẹ gómìnà fún ọjọ́ díẹ̀, òun mọ̀ pé gómìnà yóò ri pé ẹ̀tọ́ àwọn ni àwọn ń bèèrè fún, tí yóò sì dáwọn lóhùn.

Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹwàá, ọdún 2025 ni ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó fi ìlú Ibadan ṣe ibùjókòó gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé bí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ṣe fòfin de iṣẹ́ wọn, tí ìjọba sì dá ẹgbẹ́ náà dúró.

Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní bí ìjọba ṣe dá ẹgbẹ́ náà lọ́dún 2019 kò bá òfin mú rárá.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ọjọ́ Kọkànlélagbọ̀n, oṣù Karùn-ún ọdún 2019 ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde fòfin de gbogbo iṣẹ́ àti ìṣe àwọn ẹgbẹ́ NURTW, pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà ń da omi àlááfíà ìpínlẹ̀ Oyo láàmú.

Lẹ́yìn náà ló ní kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba gba gbogbo gáràjì, tó sì dá ẹgbẹ́ Parks Management System sílẹ̀.

Ìgbésẹ̀ náà kò tẹ́ ẹgbẹ́ NURTW nínú tí wọ́n sì gba ilé ẹjọ́ National Industrial Court lọ ní ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Keje, ọdún 2021, pé kí ilé fi òfin dá ẹgbẹ́ àwọn padà.

Àmọ́ ilé ẹjọ́ náà da ẹjọ́ náà nù lọ́jọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kẹta, ọdún 2022 pé ẹjọ́ náà kò ní gbòǹgbò.

Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ yìí kò tẹ́ NURTW lọ́rùn, tí wọ́n sì gba ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lọ lọ́jọ́ Kejìlélógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2022 níbi tí wọ́n ti fẹ̀sùn kàn pé ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo kò ní àṣẹ lábẹ́ òfin láti dá ẹgbẹ́ tó forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ Trade Union dúró.

Tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo, tí agbẹjọ́rò àgbà ìpínlẹ̀ náà, Abiodun Aikomo ṣojú fún nílé ẹjọ́ sọ pé ìdí tí ]ijọba fi dá ẹgbẹ́ náà dúró ni pé wọ́n ń da omi àlááfíà ìpínlẹ̀ náà rú.

Lẹ́yìn-ò-rẹyìn, ìgbìmọ̀ adájọ́ ẹlẹ́ni mẹ́ta ní ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lábẹ́ ìdárí Adájọ́ Kenneth Amadi dájọ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo kò ní ẹ̀rí láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹgbẹ́ náà ń fa wàhálà èyí tó mú wọn dáwọn dúró.

Adájọ́ Amadi wá gbé ìdája kalẹ̀ pé dídá ẹgbẹ́ náà dúró kò tọ̀nà àti pé òun gbé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Industrial Court dànù.

Ilé ẹjọ́ náà ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe ìjọba ni láti rip é àlááfíà jọba láàárín ìlú, ó ní wọ́n gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìṣàmúlò òfin ni.