Ìjọba orílẹ́èdè Cameroon sọ̀rọ̀ lórí ìlera Ààrẹ Paul Biya tí kò tíì yọjú síta f’óṣù kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Cameroon ti sọ pe koko lara Aarẹ Paul Biya ilẹ naa le.
Eleyii jẹ esi si ahesọ ọrọ to ti gbalẹ kan lẹyin ti aarẹ Biya ko yọju sita fun bi oṣu kan bayii.
Wọn ko tii ri Aarẹ Biya nita lorilẹede Cameroon lati ọjọ kẹjọ oṣu Kẹsan an to ti kopa ninu eto apero laarin orilẹede China ati ilẹ Afirika niluu Beijing.
Koda, aarẹ naa ko lanfaani lati kopa ninu eto awọn olori orilẹede ti ajọ iṣọkan agbaye, UN ṣagbatẹru rẹ niluu New York.
Amọ, ọkan lara awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Cameroon ti kede ninu atẹjade kan to fi sita wi pe ṣaka lara Aarẹ Biya da.
O bu ẹnu atẹ lu awọn eeyan kan to ni wọn n gbe irọ kiri nipa ilera aarẹ Cameroon atawọn ti wọn n sọ pe o ṣee ṣe ki o ti ku.
Eekan ninu ijọba Aarẹ Biya fi atẹjade yii sita lẹyin ti ẹgbẹ alatako atawọn ẹgbẹ ajafẹtọọ n beere wi pe nibo ni aarẹ wa.
Ọgbẹni Samuel Mvondo Ayolo to jẹ ọkan lara awọn adari ijọba orilẹede Cameroon sọ pe Aarẹ Biya si wa niluu Geneva lorilẹede Switzerland.
Ọgbẹni Ayolo ṣalaye pe lati ilu Beijing ni China ni Aarẹ Biya ti rinrin ajo lọ si Switzerland, ko si tii pada wale lati igba naa.
Lọpọ igba ni awọn eeyan kan ni Cameroon ti fi aidunnu han lori bi Aarẹ Biya ṣe maa n pẹ nilẹ okeere papaa julọ lorilẹede Switzerland.
Ajọ OCCRP to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati iwa ọdaran ni Cameroon sọ lodun 2018 wi pe, Biya ti lo ọdun mẹrin ati aabọ nilẹ okeere lati igba to ti gori aleefa lọdun 1982.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ijọba, René Sadi, ti sọ pe Aarẹ Biya yoo pada de si Cameroon lati irinajo rẹ laipẹ.
Biya ni olori orilẹede to tii pẹ lori oye julọ nilẹ Afirika lẹyin to ti lo ọdun mejilelogoji bayii.















