Wo àwọn àgbà agbábọ́ọ̀lù mẹ́wàá ti wọ́n ti di olósèlú

George Weah, Romário de Souza Faria ati Lilian Thuram

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, George Weah, Romário de Souza Faria ati Lilian Thuram
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ohun to ba jọhun la fi n we'hun, oku ko papọ mọ iyawo, gẹgẹ bi bọọlu afẹsẹgba naa ṣe yatọ si oṣelu gedengbe.

Ṣugbọn ohun to ba n wu ni naa ni i pọ ju lọla ẹni, lo fa a ti awọn ogbontarigi agbabọọlu kan ṣe pa idi ọrẹ́ da, ti wọn si di oloṣelu.

Ninu iroyin yii, ẹ wa wo awọn agbabọọlu tẹlẹ ti wọn fi ọna ti wọn n tọ silẹ, ti wọn si di oloṣelu paraku .

Andriy Shevchenko:

Agbabọọlu to ṣee mu yangan ni Andriy Shevchenko tẹlẹ, awọn ikọ agbabọọlu bii Chelsea, AC Milan ati Dynamo Kyiv lo ti gba bọọlu fun ri.

Koda, o ti gba ami ẹyẹ to maa n wu gbogbo agbabọọlu, iyẹn Ballon d'Or.

Latigba ti Shevchenko ti n gba bọọlu naa lo ti nifẹ si oṣelu ṣiṣe, niba to si di akoko kan ni awọn ọdun 1990, o ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, ni Ukraine (United).

O si tun darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Ukraine Forward lẹyin to fẹyinti ni 2012, ko too di akọnimọọgba.

George Weah:

George Weah ni ọmọ ilẹ Africa kan ṣoṣo to gba ami ẹyẹ Ballon d'Or titi di asiko yii.

O gba bọọlu fun Chelsea, AC Milan ati AS Monaco.

Idarapọ mọ oṣelu akọkọ rẹ waye ni ọdun 2005, nigba to dije fun ipo aarẹ ilẹ Liberia, ṣugbọn o padanu sọwọ Ellen Johnson Sirleaf.

Nigba to di 2018, George Weah di aarẹ.

Romário de Souza Faria:

Romário lasan ni ọpọ eeyan mọ ọn si, agba agbabọọlu to gba bọọlu fun SV Eindhoven, FC Barcelona, Fluminense ati Flamengo ni.

Ẹẹmeji lo gba ami ẹyẹ Copa America, ni 1989 ati 1997 lo gba a.

Bakan naa ni Romário si jẹ ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu to gba ife ẹyẹ agbaye FIFA ni 1994.

Ni bayii, ipo sẹnetọ ni agbabọọlu tẹlẹ naa di mu lati Rio de Janeiro, ọdun 2014 lo ti n ba a bọ.

Lilian Thuram:

Atamatase agbabọọlu tẹlẹ ni Lilian Thuram, bo ṣe le gba ọwọ aarin naa lo mọ ẹyin naa gba.

Lẹyin to fẹyinti bii agbabọọlu lo di ẹni to n da si ọrọ oṣelu, ajafẹtọọ, onkọwe ati ẹlẹyinju aanu to n fi ohun to ni ran awujọ lọwọ.

Ọpọ igbiyanju ni Thuram ti ṣe fun iranlọwọ ọmọniyan, bo tilẹ jẹ pe ko di ipo oṣelu kankan mu.

Sol Campbell

Oríṣun àwòrán, Gettz images

Àkọlé àwòrán, Sol Campbell

Sol Campbell:

Awọn ikọ agbabọọlu bii Tottenham Hotspur ati Arsenal ni Sol Campbell ṣoju fun ri.

Ọdun 2014 lo koro oju si owo ori kan to si ni yoo wu oun lati darapọ mọ oṣelu ninu ẹgbẹ Conservatives.

O ṣe atilẹyin fun ipolongo Vote Leave ni 2016, lẹyin ti igbinyanju rẹ sipo Mayor foriṣanpọn ni 2015.

Hakan Sukur:

Ọkan lara awọn agbabọọlu to kaju ẹ ju ni Turkey ni wọn mọ ọkunrin yii si ninu itan.

Ami ayo 51 lo gba sawọn fun orilẹede rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ 112, o si ni ami ayo to pọju fun Galatasaray (288).

Ni 2011, wọn dibo yan an sile igbimọ aṣofin Turkey, bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu Justice and Development Party to n ṣejọba.

Cuauhtemoc Blanco:

Orilẹede Mexico mọ pe eekan ni Cuauhtémoc Blanco ninu agbabọọlu wọn.

O gba ami ayo mejidinlogoji sinu awọn, o si gba fila 119 fun El Tri lati 1995 titi de 2014. Agba ọjẹ ni ni Club América pẹlu.

O tun gba bọọlu fun Chicago Fire ati Real Valladolid.

Lẹyin ifẹyinti rẹ, Blanco dupo aarẹ Cuernavaca loṣu Kin-in-ni ọdun 2015, bii ọmọ ẹgbẹ Social Democratic Party. Ni 2018, wọn dibo yan an sipo gomina Morelos, lati ẹgbẹ Social Encounter Party.

Kakha Kaladze:

Eekan ni agbabọọlu tẹlẹ yii ni Georgia.

Kakha Kaladze gba ami ẹyẹ mẹtalelọgọrin fun ikọ agbabọọlu apapọ ilu rẹ, o si fẹrẹ lo to ọdun mẹwaa ni AC Milan.

2012 lo fẹyinti bii agbabọọlu, Kaladze darapọ mọ oṣelu, o di ọmọ ẹgbẹ Georgian Dream–Democratic Georgia Party, o si di ọmọ ile igbimọ aṣofin lọdun naa.

Wọn pada yan an sipo Igbakeji Olootu ijọba, ati minisita eto agbara.

2017 ni wọn yan Kaladze sipo Mayor ilu Tbilisi, o si ṣe bẹẹ di olori .

Pele:

Ọkan lara awọn onibọọlu ti a baa maa pe ni agba -baller ni Pele ti orilẹede Brazil. Lara awọn to fi iṣẹ bọọlu ṣe rere laye ni sentunri ogun ni.

Lẹyin ti Pele fẹyinti, o di minisita eto ere idaraya ni Brazil.

Lati bu ọla fun un, wọn da ofin "Pelé law" silẹ ti yoo maa gbogun ti ajẹbanu lẹka ere idaraya.

Zico:

Manigbagbe agbabọọlu ni Zico jẹ fun Brazil ninu itan, o mọ ere naa ṣe ni tootọ.

Ami ayo 48 lo gba sawọn fun Selecao, eyi to fi ba wọn ṣe lati ọdun 1976 de 1986.

Zico tun pada sidi ere bọọlu lẹyin saa akọkọ rẹ ninu oṣẹlu.

Akọkọ bii adari Kashima Antlers, ati Flamengo ko too kuro nibẹ latari aawọ awọn aarin igbimọ.

Zico gbiyanju lati di aarẹ FIFA ni 2015.

O pada darapọ mọ igbimọ Kashima Antlers ni 2018.