Mọ̀ nípa àwọn ìpínlẹ̀ Naijiria méje tó ń pawó wọlé jùlọ

Owo Naira ẹgbẹrun kan Naira alapapọ, owo beba eedegbeta naira àti owo beba igba naira alapapọ tí wọn di papọ

Oríṣun àwòrán, CBN

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Mọ̀ nípa àwọn ìpínlẹ̀ Naijiria méje tó ń pawó wọlé jùlọ

Latigba ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu ti yọ owo iranwọ ori epo kuro loṣu Karun-un ọdun 2023 ni afikun ti ba iye owo ti ijọba apapọ n fun awọn ipinlẹ Naijiria kọọkan.

Ẹka iṣuna kan, budget IT center, fidi eyi mulẹ.

Ọpọ ipinlẹ lo jẹ pe owo ti ijọba apapọ n fun wọn yii ni wọn gbojule, ti wọn fi n gbọ bukata ilu wọn.

Ṣugbọn awọn ipinlẹ kan wa ti wọn jẹ atootiletọ laaye ara wọn, ti wọn n pawo wọle ti wọn si tun ni ajẹṣẹku .

Meje ninu awọn ipinlẹ naa ni BBC gbe yẹwo ninu iroyin yii, pẹlu titẹle akọsilẹ BudgIT Institute, ati onka ti ajọ Nigerian Bureau of Statistics, NBS, fi sita nipa owo to n wọle labẹnu fun awọn ipinlẹ naa.

Awọn ipinlẹ naa ree:

  • Eko

Ilu Eko lagba ninu awọn ipinlẹ to n pawo nla wọle, gẹgẹ bi BudgIT ṣe la a kalẹ.

Ipinlẹ Eko ti gbiyanju pupọ nipa pipa owo wọle funra rẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni 2024, Eko pa N1.26 trillion, to le di ida aadọta si iye ti wọn pa ni 2023 bi BudgIT ṣe wi.

Onka si fi han pe ida 73 ninu owo yii ni wọn pa lati ara owo ori sisan.

Eko ni ọpọ ileeṣẹ nla wa, ileetura, ibudo ọkọ oju omi, ibẹ ni wọn n gba ko ọja wọle ati jade ju, ileeṣẹ ifọpo Dangote to tobi ju l'Afica, ilu Eko lo fikalẹ si.

  • Enugu

Ipinlẹ Enugu naa wa lori atẹ awọn to lowo julọ ni Naijiria, bi BudgIT ṣe pin in.

Igbagbọ wa pe bi Enugu ko gba owo lọwọ ijọba apapọ, ipinlẹ naa le da ẹru ara rẹ gbe pẹlu owo to n pa wọle.

Owo to wọle fun wọn ni 2024 bi wọn ṣe gbe e kalẹ to N180.50 billion, pẹlu N26.68 to wọle lati owo ori tawọn eeyan san.

  • Kano

Gẹgẹ bi ẹka Nigerian Bureau of Statistics, NBS, ṣe wi, Kano le pa to N74.77 labẹnu. Wọn pa N37.38 billion ni 2023.

Ẹka to n pawo wọle labẹnu ni Kano (KIRS), ti ni oun yoo gba to N180 billion owo ori ni 2026.

  • Kaduna

Ipinlẹ Kaduna lo pawọ le Kano ninu owo nini, wọn pa N71 billion wọle labẹnu ni 2024. Gẹgẹ bi awọn Kaduna State Revenue Service, KADIRS, ṣe sọ.

  • Kwara

Ipinlẹ Kwara to wa ni Aarin -Gbungbun Ariwa Naijiria naa wa lara awọn ipinlẹ to n pawo wọle labẹnu daadaa.

BudgIT ṣalaye pe owo to n wọle labẹnu ni Kwara ti wọ N65.16 billion ni 2024.

Bẹẹ naa ni wọn ni ipinlẹ yii ti n pawo daadaa naa, o ti ju ọdun mẹrin lọ.

  • Anambra

Ipinlẹ Anambra wa to wa ni Guusu-Ila-Oorun Naijiria ni a gbọ pe o pa N42.97 billion ni 2024, eyi to le si N36.20 billion to pa ni 2023, bi BudgIT ṣe wi.

Awọn ọja nla to gbajumọ to wa nipinlẹ Anambra wa lara ọna to n gba pawo rẹ, awọn bii ọja Onitsha to gbajumọ kaakiri Iwọ-Oorun Africa.

  • Abia

Ipinlẹ Abia toun naa w ani Guusu-Iwọ -Oorun Naijiria naa n rọwọ họri nipa owo ti wọn n pa wọle.

BudgIT ṣalaye pe owo to n wọle fun wọn ti gberasọ lati N17.99 billion ti wọn pa ni 2023, si N41 billion ni 2024.