Peju Ogunmola kéde pé òun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà padà lẹ́yìn oṣù méjì tí ọmọ rẹ̀ kú

Oríṣun àwòrán, Peju Ogunmola /Instagram
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà Péjú Ogunmola Omobolanle tí yọjú síta lẹ́yìn oṣù méjì tó pàdánù ọmọ kansoso tí bí.
Ní ọjọ kẹfà oṣù kẹsàn-án ọdún 2025 ni Ayomikun, tíí ṣe ọmọ kansoso tí Péjú Ogunmola bí jáde láyé.
Ọpọ eeyan lo n bá kẹ́dùn nígbà náà, tí a kò sì gbọ́ ọrọ kankan láti ọ̀dọ̀ rẹ.
Àmọ́ leyin oṣù méjì tí Ayomikun salaisi, Peju Ogunmola tí jáde síta láti fi ẹ̀mí imoore rẹ hàn sí gbogbo àwọn èèyàn tó dúró tíì, bá kẹ́dùn, gbàdúrà fún.

Oríṣun àwòrán, Peju Ogunmola /Instagram
Ninu fidio kan tó gbé síta ni òwúrọ̀ ọjọ́ Abameta ni Peju Ogunmola tí kéde pé òun ti padà sidi ère tíátà báyìí.
"Gbogbo ẹyin olólùfẹ́ mi, alabasisepo àti ẹbí mi, Láti bíi oṣù méjì sẹ́yìn tí mo ti pàdánù ọmọ mi, ní mo ti wá nínú iporuru ọkan àti Ìbànújẹ́ ńlá.
Àmọ́ bí mo ṣe wa ninu Ìbànújẹ́ yìí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo agbaye jẹ ki n mọ pe awọn wá lẹ́yìn mi.
Mo ri ìfẹ́ tí ẹ fi hàn mí, mo sì ń mọ imọlara àdúrà yín àti itọju yín. Gbogbo rẹ̀ náà ni mo ń rí."
Peju Ogunmola ni lati ìsàlẹ̀ ọkàn òun, ní òun ti ń sọ fún gbogbo àwọn èèyàn jákèjádò agbaye pé wọn seun, òun dúpẹ́ pupọ, òun sì mọ ìfẹ́ tí wọn ní si òun loore ó.
"Orin onigbagbọ kan sọ pé nígbà tó bá tẹ wá lọrun, ìwọ ni Oluwa to ga julọ, bí kò sì tẹ wá lọrun, ìwọ ni Ọlọ́run tó ga julọ.
Mo ti gba fún Ọlọ́run, ẹ seun, mo dúpẹ́."
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà náà wà kéde pé òun ti dé padà sidi isẹ tíátà lẹ́yìn tí òun ti kẹ́dùn ikú ọmọ òun fún oṣù méjì.
"Lónìí, mo dìde padà. Kii se pe ìrora yẹn tí lọ àmọ́ torí mo mọ pe ọmọ mi Ayomikun kò ní fẹ́ kí n máa joko sílè.
Mo padà sidi isẹ ère tíátà tí mo fẹ́ràn. Gbogbo eyin olootu ère, òṣèré tíátà, olùdarí àti onigbọwọ ere, mo ti dé padà. Isẹ ti ya."

Oríṣun àwòrán, Peju Ogunmola /Instagram
Ta ni Peju Ogunmola?
Yatọ si pe o jẹ agba oṣere, Peju Ogunmola jẹ agba onkọtan, oludari ere ati olugbe sinima sita gẹgẹ bii ti baba rẹ, Kola Ogunmola.
Ní ọdun 1989, Peju Ogunmola ṣe igbeyawo pẹlu Sunday Omobolanle, ẹni ti ọpọ mọ si Papiluwe, to si jẹ iyawo keji fun agba oṣere alawada naa.
Ninu ọrọ ti Ọkọ rẹ, Sunday Omobolanle ba ileeṣẹ iroyin City People sọ lọdun 2017, o ni oun pade iyawo oun ni ile baba rẹ, Kola Ogunmola lasiko ti o n tẹlẹ baba naa kaakiri fun ere itage lasiko náà.
Peju bí ọmọkùnrin kan ṣoṣo, Ayomikun fún Sunday Omobolanle Aluwe, ẹni tíì ṣe ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún kò to jáde láyé.
Lara awọn ère tíátà tí Peju Ogunmola tí ṣe ni wọn yìí:
Apaadi (2009), Omo Ghetto: The Saga (2010) gẹgẹ bii iya Ayomide
King of Thieves (2022) gẹgẹ bii Lalopne
Beast of Two Worlds (2024) gẹgẹ bii Iyalode
House of Ga'a (2024) gẹgẹ bii Iyaloja
Maradona (2003), Mafi wonmi (2008), Toromade (2009), ati Apaadi (2009).














