Kí ni Andrew ṣe, tí wọn ṣe yọ òyè Ọmọọba Gẹ̀ẹ́sì kúrò lára orúkọ rẹ̀, gba ipò Duke lọ́wọ́ rẹ̀, tí wọn tún le kúrò láàfin?

Yoruba ni ọmọ ọba le di ẹru, iwẹfa naa si le di ọlọrọ.
Nibayii, Ọmọọba ilẹ Gẹẹsi, Andrew ni yoo padanu oye ati ipo rẹ gẹgẹ bii Ọmọọba ilẹ Gẹẹsi.
Bakan naa, Andrew ni ireti wa pe yoo kuro ni aafin Windsor ati Royal lodge, to jẹ ara awọn aafin ti idile ọba nilẹ Gẹẹsi maa n lo si.

Ninu osu yii ni Andrew fi ipo ati oye Ọmọba silẹ to fi mọ oye Duke ti York, lẹyin ti ẹnu n kun lori iwa to n hu nipa igbe aye rẹ
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin awọn iwadiii ati ayẹwo alagbara lori ajọsepọ ti Andrew ni pẹlu Jefferey Epstein, tii se ẹni to lọ sẹ́wọn tori ẹsun ibalopọ.
Atẹjade kan ti wọn fisita ni alẹ Ọjọbọ lati aafin Buckingham salaye pe aburo Ọba ilẹ Gẹẹsi naa ni yoo pa orukọ da, ti wọn yoo si maa pe ni Andrew Mountbatten Windsor lasan.
Ninu osu yii ni Andrew fi ipo ati oye Ọmọba silẹ to fi mọ oye Duke ti York, lẹyin ti ẹnu n kun lori iwa to n hu nipa igbe aye rẹ.
Ninu iwe iranti ti wọn tẹ sita nibẹrẹ osu yii, Virginia Giuffre tẹnumọ awọn ẹsun to n fi kan Andrew pe nigba ti oun wa ni kekere, oun ni ibalopọ pẹlu Andrew nigba mẹta ọtọọtọ.
Amọ Andrew maa n sẹ lori awọn ẹsun naa.
Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ ọtun yii, idile omidan Giuffre salaye pe "ọmọ awọn mu odidi ọmọọba ilẹ Gẹẹsi walẹ pẹ́lu otitọ ati igboya alailẹgbẹ to ni"
Ibẹrẹ ọdun yii ni omidan Giuffre ti pa ara rẹ.
Ninu atẹjade kan to fi sita, aafin salaye pe Ọba "ti bẹrẹ igbesẹ lati gba oye ọmọọba kuro lọwọ Andrew."
Bakan naa, Andrew yoo padanu ipo rẹ, Aafin lo sọ bẹẹ,
A si ti kọwe si pe ko ko awọn dukia naa to wa nikawọni rẹ silẹ lori aafin Royal Lodge.
Andrew ni wọn maa mu lọ si ile ti ara rẹ to wa ni Sandringham Estate lati maa gbe, eyi ti a mọ pe Ọ́ba Charles ni yoo sanwo rẹ nidakọnkọ.
" Awọn idena yoo lo pọn dandan, lai naani pe Andrew n tẹsiwaju lati maa sẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan naa"
Atẹjade lati aafin salaye.
Aafin wa fi atilẹyin rẹ han fun awọn eeyan to faragba ninu "asemase yowu"
Sarah Ferguson, tii se iyawo Andrew tẹlẹ, yoo ko kuro ni aafin Royal Lodge, ti yoo si seto ibi ti yoo maa gbe funra rẹ
Ọmọbinrin meji ti Andrew bi, ti wọn jẹ agbalagba, Eugenie and Beatrice, yoo si maa lo oye ati ipo ọmọọba lọ tori Andrew ni o wa nipo kẹjọ si ori itẹ ọba ilẹ Gẹẹsi.
Bakan naa, Sarah Ferguson, tii se iyawo Andrew tẹlẹ, naa yoo ko kuro ni aafin Royal Lodge ti yoo si seto ibi ti yoo maa gbe funra rẹ.
Titi di osu yii, Sarah si n lo orukọ oye rẹ, tii se Sarah, Duchess of York - amọ o ti pada maa jẹ orukọ baba rẹ tii se Ferguson lẹyin ti Andrew finu findọ fi oye rẹ, Duke ti York silẹ.
Aafin ti jiroro pẹlu ijọba lori igbesẹ naa atawọn ipinnu ti wọn se lati gba oye ati ipo Andrew, ti wọn si ri atilẹyin ijọba gba.
Nigba to n dahun ibeere lori eto BBC, Akọwe fun ọrọ asa nilẹ Gẹẹsi, Lisa Nandy ni "Awọn igbesẹ yii lo n fi isẹ nla ransẹ si awọn eeyan to fara gba ninu iwa ibalopọ lọna aitọ."
"Isẹlẹ nla ni eyi jẹ, o si jẹ igbesẹ nla fun Ọba ilẹ Gẹẹsi lati gbe, mo si fẹ sọ pe lati ibẹrẹ ni mo ti fara mọ igbesẹ ti Ọba gbe."
Ẹsun ibanilorukọjẹ to nii se pẹlu nini ibalopọ lọna aitọ pẹ́lu Jeffrey Epstein lo yọju sita nigba ti wọn ka iwe akọsilẹ ti omidan Giuffre kọ nipa awọn ẹsun ifipabanilopọ
Bi wọn gba oye ati ipo Andrew yii lo waye tori bi wọn se n ke si idile ọba lati se bẹẹ.
Ẹsun ibanilorukọjẹ to nii se pẹlu nini ibalopọ lọna aitọ pẹ́lu Jeffrey Epstein lo yọju sita nigba ti wọn ka iwe akọsilẹ ti omidan Giuffre kọ nipa awọn ẹsun ifipabanilopọ.
Bi o tilẹ jẹ pe Andrew n sẹ lemọlemọ pe oun ko fipa ba omidan Giuffre lopọ, amọ ni ibere osu yii, awọn iwe lati ori email n yọju sita, eyi to n fidi rẹ mulẹ pe Andrew ni ibasepọ pẹlu Epstein lẹyin ọpọlọpọ osu to ni ko si ajọsepọ laarin awọn mejeeji.
Ẹunrẹrẹ iroyin nipa bi Andrew se n gbe naa ti lu sita, pẹlu akọtun ibeere pe lẹnu lọọlọọ yii, nibo ni Andrew ti n ri owo to fi n gbe igbe aye rẹ niwọn igba to jẹ pe kii se ọmọọba to n sisẹ.
Andrew ti n gbe ni aafin Royal Lodge lati ọdun2004, lẹyin to tọwọbọ iwe adehun lati haya ile fun ọdun marundinlọgọrin pẹlu onile kan to ni Crown Estate, tii se ileesẹ aladani.















