Anike Agbaje-Williams, ẹni àkọ́kọ́ tó farahàn lórí tẹlifísan l'Afrika, jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Others
Oloye Anike Agbaje –Williams, ẹni akọkọ to farahan lori ẹrọ amohunmaworan ni gbogbo ilẹ Afrika, jade laye.
Agbaje-Williams, ẹni ọdun mejidinlaadọrun, re bi agba n re ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2025.
Gẹgẹ bii iroyin to tẹ wa lọwọ, oloogbe naa jade laye pẹlu alaafia ni ile rẹ to wa Idi-Ishin niluu Ibadan nibi to ti lọ ọpọ igbesi aye rẹ.
Arabinrin Banji Sokoya, akọbi oloogbe, lo kede iku oloogbe, to si jẹ ko di mimọ pe iku rẹ jẹ ohun to dun mọlẹbi pupọ, to si jẹ pe gbogbo wọn ati awọn to mọ iya Williams ni yoo mọ lara.

Oríṣun àwòrán, Others
Ta a ni Anike Agbaje Williams?

Oríṣun àwòrán, Others
Oloye Anike Agbaje Williams, jẹ ọmọ Baba Kuforiji.
Wọn bi i ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 1936. Ilumọka ni oloogbe yii ni agbo igbohunsafẹfẹ
O fi itan balẹ nigba to di ẹni akọkọ to farahan lori ẹrọ amohunmaworan ni gbogbo ilẹ Afrika lori ileeṣẹ tẹlifisan Western Nigerian Television(WNTV) to wa ni Agodi niluu Ibadan.
Nigba naa ni ileeṣẹ naa n kọkọ n dan awọn irinṣẹ wo gẹgẹ bi tẹlifisan akọkọ ni Afrika, lori eto Test Transmissions Night ati lori eto Official Opening Night ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 1951.
Bakan naa, oun ni ẹni akọkọ ti ohun rẹ dun lori redio akọkọ WNBS.
O fẹyinti ni ọdun 1986 lẹyin to ti kopa ninu igbohunṣafẹfẹ.















