Àjọ FCCPC pàṣẹ fún Multichoice láti dáwọ́ àfikún owó DSTV àti GoTV dúró

Multichoice

Oríṣun àwòrán, Multichoice

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n daabo bo ẹtọ awọn onibaara ni Naijiria, Federal Competition and Consumer Protection Commission, FCCPC, ti paṣẹ fun ileeṣẹ Multichoice pe ko ma tii ṣafikun iye owo ọja rẹ ni Naijiria lọwọ yii.

FCCPC lo fi ikede naa sita loju opo ayelujara rẹ.

Ileeṣẹ Multichoice lo n pese DSTV ati GoTV ti awọn eeyan n wo lori ẹrọ amohunmaworan ni Naijriia.

Ṣaaju ni Multichoice ti kokọ kede afikun iye owo ti awọn eeyan yoo maa san lori DSTV ati GoTV, eyii ti ọpọ araalu koro oju si.

Lẹyin ikede naa ni FCCPC ke si awọn aṣoju ileeṣẹ naa pe, ki wọn farahan niwaju oun fun awọn iwadii kan.

Amọ Multichoice sọ fun FCCPC pe oun yoo yọju ṣugbọn ki wọn fun oun ni akoko diẹ si.

DSTV

Oríṣun àwòrán, @fccpcnigeria

Atẹjade FCCPC sọ pe "aṣẹ tuntun yii lo n waye lẹyin ti Multichoice Nigeria ni ki a fun oun ni asiko diẹ si ki oun to yọju niwaju ajọ yii.

"Lootọ ni FCCPC ti fun wọn ni akoko diẹ si, ileeṣẹ naa gbọdọ yọju si wa ni akoko tuntun ti a mu fun iwadii lọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun 2025 pẹlu idahun rẹ.

"Nitori naa, a ti paṣẹ fun Multichoice ko ṣi maa gba owo to n gba tẹlẹ lori awọn ọja rẹ boṣe wa lonii ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2025, titi di igba ti a o gbe ọrọ naa yẹwo ti a o si fi esi iwadii wa sita."

Ajọ ọhun sọ pe o ṣe pataki ki afikun owo naa ma tii waye lasiko yii ko ma ba a ṣe ipalara fun awọn onibaara Multichoice ni Naijiria.