Mudashiru Obasa: Mo ti padà ṣẹ́nu iṣẹ́, kò sí ẹni tó yọ mí nípò olórí ilé aṣòfin Eko

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic
Aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Agege nipinlẹ Eko, Mudashiru Obasa, ti sọ pe oun ti bẹrẹ iṣẹ pada gẹgẹ bii olori ile aṣofi ipinlẹ naa.
Asiko to lọ si ile aṣofin naa lọsan an Ọjọbọ lo sọ bẹe fun awọn akọroyin.
Ọrọ yii lo n jade lẹyin ọsẹ melokan ti awọn akẹgbẹ rẹ ninu ile naa ti kọkọ yẹ aga nidi rẹ gẹgẹ olori wọn.
Nigba ti awọn akọroyin bere lọwọ rẹ boya awọn aṣofin ile naa ti da a pada sipo to wa tẹlẹ o fesi pe ko si ẹni to yọ oun nipo.
Obasa sọ pe "wọn ko yọ mi nipo tẹlẹ, ọrọ ofin ni iyọnipo jẹ, nitori naa, ti ẹ ba fẹ yọ eeyan nipo, ẹ gbọdọ tẹle ilana to yẹ. Mi o lodi si ki wọn yọ eeyan nipo ni ọna to ba ofin mu."
Amọ ṣa, awọn aṣofin kan to wa lẹyin olori ile ti wọn ṣẹṣẹ yan sipo, Mojisola Meranda, ti sọ pe awọn ko fẹ Obasa, ati pe Meranda gan ni ojulowo olori ile naa lọwọ yii.
Lojiji ni Obasa ṣadede ya bo ile aṣofin naa lọsan Ọjọbọ toun ti awọn ẹṣọ alaabo atawọn alatilẹyin rẹ.
Igbesẹ naa ni igba akọkọ rẹ ninu ọgba ile naa lati igba ti wọn ti yọ ọ bii jiga lọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2025.
Ẹwẹ, ogunlọgọ awọn alatilẹyin rẹ lo korajọ siwaju ile aṣofin ọhun, ti wọn si n kan sara si i.
Oṣu Kinni ọdun yii ni ida meji ninu mẹta ninu ile naa yọ Obasa nipo lori ẹsun aṣilo ipo atawọn ẹsun mii.
Ilẹ okeere lo wa lasiko ti wọn yọọ nipo, o si ti sọ pe iyọnipo oun ko ba ofin mu nitori oun gbọdọ wa ninu ile naa lasiko ti wọn ba n dibo lati yọ oun nipo.
Aṣofin naa tun sọ pe irọ pọnbele ni gbogbo awọn ẹsun ti ile naa ka si oun lẹsẹ ṣaaju.
Awọn iroyin kan sọ pe rogbodiyan to n waye nile aṣofin Eko ko ṣẹyin pe Onasa n lepa lati di gomina ipinlẹ Eko lẹyin saa Babajide Sanwo-Olu.
Ọdun 2007 ni wọn kọkọ yan Obasa sipo aṣofin nipinlẹ Eko, lati ọdun naa wa lo si ti wa nibẹ gẹgẹ bii aṣofin.
Inu oṣu Kẹfa ọdun 2015 lo gori aga olori ile ki wọn to fi ibo yẹ aga nidi rẹ lọdun 2025 yii lori ẹsun aṣilo ipo.















