Bí o ṣe le fi orúkọ sílẹ̀ láti di ìràwọ̀ akọ̀ròyìn Africa tí BBC n wá

Oríṣun àwòrán, Komla Dumor
Ileeṣẹ iroyin BBC n wa akọroyin ti irawọ rẹ n tan lasiko yii, lati jẹ anfaani ami ẹyẹ BBC News Komla Dumor, to pe ọdun mẹwaa bayii.
Awọn akọroyin jakejado ilẹ Afrika ni anfaani wa fun lati fi orukọ silẹ fun ami ẹyẹ naa, ti afojusun rẹ jẹ ipolongo awn ẹbun tuntun.
Ẹni to ba jawe olubori yoo lo oṣu mẹta ni olu-ileeṣẹ BBC to wa niluu London, lati kọṣẹ, ko si gba imọ kun imọ.
Ogunjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2025 ni iforukọ silẹ yoo pari ni deedee agogo mejila ku iṣẹju kan l'oru.
Wọn ṣe idasilẹ ami ẹyẹ yi ni irnati Komla Dumor akikanju akọroyin ọmọ orileede Ghana to jẹ atọkun lori eto BBC World News to dagbere faye lẹni ọdun mọkanlelogoji ni nkan bi ọdun mọkanla sẹyin.
Opo Dumor,Kwansema Dumor sọ pe ''inu oun dun si aṣeyọri ati ipa ọkọ rẹ ni BBC''
O ni idile awọn ''dupẹ lọwọ BBC fun iranti ti wọn ṣe fun ọkọ rẹ'' nipasẹ ami ẹyẹ yii.
Yatọ si ẹkọ ti akọroyin yoo kọ kun ẹkọ, ẹni ito ba jaweolubori yoo lanfaani lati rinrinajo jakejado Africa lati ṣisẹ lori iroyin ti wọn ṣe iwadii rẹ ti wọn yoo si gbe safẹfẹ fawọn eeyan Africa.
Lasiko to wa laye, ilumọọka ni Komla Dumor jẹ nipa gbigbe iroyin nipa ilẹ Africa jade nigbe ododo.
Awọn to ti gba ami ẹyẹ naa ri
2024: Rukia Bulle from Kenya
2023: Paa Kwesi Asare from Ghana
2022: Dingindaba Jonah Buyoya from Zambia
2020: Victoria Rubadiri from Kenya
2019: Solomon Serwanjja from Uganda
2018: Waihiga Mwaura from Kenya
2017: Amina Yuguda from Nigeria
2016: Didi Akinyelure from Nigeria
2015: Nancy Kacungira from Uganda












