Ọkọ̀ òfúrufú iléeṣẹ́ ọmọ ogun já lulẹ̀ láàárín àdúgbò, èèyàn 46 jáde láyé

Sudan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ko din ni eeyan mẹrindinlaadọta to ti jade laye lẹyin ti baalu ileeṣẹ ọmọ ogun orilẹede Sudan ja lulẹ laarin adugbo kan ni Omdurman.

Eeyan mẹwaa mii lo tun farapa yanyana lẹyin iṣẹlẹ naa.

Ko pẹ si asiko ti baalu ọhun gbera ni ibudo awọn ologun Seidna ko to ja lulẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun.

Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹni to tii le sọ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa amọ awọn kan nileeṣẹ ologun orilẹede ọhun sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ṣe ni lara awọn irinṣẹ ọkọ naa kọṣẹ.

Baalu yii lo ja lẹyin ọjọ kan ṣoṣo ti ẹgbẹgun Rapid Support Forces (RSF) to n kọju ija si ileeṣẹ ọmọ ogun ilẹ naa sọ pe oun ja baalu kan bọ ni South Sudan.

Ija to n waye laarin ileeṣẹ ọmọ ogun Sudan ati RSF ti ṣe akoba nla fun ọpọ eeyan lorilẹede naa.

Lara awọn agbegbe ti ija naa ti milẹ titi julọ ni Khartoum ati Omdurman.

Ẹgbẹgbẹrun eeyan lo ti padanu ẹmi wọn nibẹ, ti miliọnu mejila eeyan si di alainilelori.

Ileeṣẹ eto ilera sọ pe awọn ti ko awọn eeyan, ti ọmọde wa ninu wọn lọ sile iwosan lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

Iṣẹlẹ naa tun mu ki ina mọnamọna kọṣẹ lawọn agbegbe to sunmọ ibi to ti ṣẹlẹ.

Ogun abẹle n lọ lọwọ ni Sudan lati inu oṣu Kẹrin ọdun 2023 lẹyin ti ẹgbẹgun RSF ati awọn ọmọ ogun bẹrẹ si n dun agbara mọ ara wọn lọwọ.

Lọwọ yii, orilẹede naa ti pin si meji; ileeṣe ọmọ ogun lo n ṣakoso iha ariwa nigba ti ẹgbẹgun RSF n ṣakoso agbegbe to pọ ju ni Darfur.