Níbo ní ọ̀rọ̀ dé ní Labour Party lórí bí wọ́n se fí ọwọ́ òsì júwe ilé fún Doyin Okupe?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ oṣelu Labour party nipinlẹ Ogun lo kede pe awọn ti le adari ikọ ipolongo fun aarẹ, Doyin Okupe kuro ni ẹgbẹ wọn pẹlu awọn mẹwaa miran.

Awọn adari ẹgbẹ oṣelu Labour Party nipinlẹ Ogun ni wọn kede.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni wi pe ko ṣe ẹtọ rẹ lori ọrọ owo gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ oṣelu lati bii oṣu mẹfa ṣẹyin.

‘’Doyin Okupe ko lee sọ ibi ti N20m naira wọ ilẹ si’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Okupe ati awọn miran ti wọn fi ọwọ osi juwe ile fun ni Abayomi Collins, Abel Olaleye, Jagun Lookman, Olori Oluwabukola Soyoye, Gbadebo Fesomade, ati Abdulmalik Olaleye.

Awọn miran ti wọn tun fi ọwọ osi juwe ile fun ni Jide Amusan,Adeshina Wasiu Shojobi, Deborah Adewale, Olatunde Abolade.

Amọ adari ẹgbẹ oṣelu Labour Nipinlẹ Ogun, Michael Ashade ni awọn ti awọn yọ naa tapa si ofin ẹgbẹ oṣelu naa.

Ashade ni Doyin Okupe ko lee sọ ibi ti ogun miliọnu naira wọle si labẹ iṣakoso rẹ.

Awuyewuye tẹle bi wọn ṣe yọ Doyin Okupe...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti tẹle bi wọn ṣe yọ Doyin Okupe kuro ni ipo adari ikọ ipolongo fun Peter Obi gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ ni ọdun 2023.

Ko i tii pe wakati kan ti wọn yọ kuro ni ipo ni alaga ẹgbẹ, Julius Abure ni ki awọn oniroyin ri ikede naa gẹgẹ bi iroyin ofege, ti wọn si ni ki wọn maṣe kọbi ara sii.

Abure ni ko si ninu adehun ẹgbẹ lati yọ Okupe kuro ni ipo.

O ni Okupe ko ni ẹsun magomago kankan ti oun koju ninu ẹgbẹ nitori naa wọn ko ni aṣẹ lati yọ kuro ni ipo.

A ko ni wo ariwo ọja, a o tẹsiwaju iṣẹ wa – Doyin Okupe

Lasiko ti awuyewuye pe wọn yọ ni ipo nlọ lọwọ ni Doyin Okupe fi ero rẹ han loju opo ikansiraẹni Twitter.

Ikọ Peter Obi think tank lo fi kọ sita pe awọn ko ni wo ariwo ọja lasiko ti wọn wa lọwọ yii.

Atipe ohun ti awọn n ta ni ọja ni awọn yoo koju si, to fi mọ ti gbogbo awọn ọmọ Naijiria.

Doyin Okupe buwọlu akọsilẹ yii lori Twitter to si tun ṣe apinka rẹ si oju opo ara rẹ pe "a o ni wo ariwo ọja, awọn ti a n ba naja iyẹn awọn ọmọ Naijiria ni a o gbajumọ."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post