Face Transplant: DiMeo ṣùn lásìkò tó n wa ọkọ̀ lálẹ́, ló bá jóná nígbà tí ọkọ̀ gbiná

Àkọlé fídíò, Face Transplant: DiMeo ṣùn lásìkò tó n wa ọkọ̀ lálẹ́, ló bá jóná nígbà tí ọkọ̀ gbiná

Awọn agba bọ, wọn ni ireti si n bẹ fun igi ta bẹ lori, nitori bo pẹ, bo ya, igi yoo pada ruwe.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ọmọ orilẹede Amẹrika kan, Joseph DiMeo to jona nigba ti ọkọ rẹ sadede gbina lasiko to sun lọ nigba to n wa ọkọ naa lalẹ.

Ete, ọwọ ati Oju Joseph lo jona, to si nira fun lati maa wo digi lati mọ bi aworan rẹ se ri.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ awọn ẹbi rẹ seto fun lati sisẹ abẹ lẹyin osu mẹjọ ti isẹlẹ naa waye, tawsn dokita ogoje si se isẹ abẹ naa fun wakatai mẹtalelogun ni igba mẹta ọtọọtọ.

Igba kẹta ni aseyọri to wa lati paarọ ọwọ, oju ati ete Joseph to jona, to si pada di eeyan to see wo.

Nigba to n ba BBC sọrọ, Joseph DiMeo ni ohun to wu ohun bayii ni lati wa ni ominira toun naa, ki oun si le da duro bii awọn eeyan yoku lati gbara le ẹnikẹni.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O si fi ẹmi imoore rẹ han si awọn ẹbi rẹ naa ti wọn duro tii nigba isoro.