James Ibori: Ìjọba UK yóò dá bílíọ̀nù méjì(N2b) owó tí Ibori kó pamọ́ padà sí Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Metropolitan Police
Ijọba orilẹede UK ti ṣeleri lati da owo to le ni biliọnu meji naira(2,206,888,400) lara owo ti gomina ipinlẹ Delta tẹlẹ ri, James Ibori ji ko pamọ si orilẹede naa pada si Naijiria.
Gomina ipinlẹ Delta tẹlẹ ri jẹbi ẹsun ikowo pamọ silẹ okeere lọna aitọ ti wọn fi kan an lọdun 2012.
Owo to le ni biliọnu mejidinlọgbọn ni wọn fẹsun kan Ibori pe o ji ko lọ silẹ okeere lati Delta.
- Wakili tẹẹ rí yẹn kìí ṣe ẹran rírọ̀, ó ń díbọ́n ní o - Iba Gani Adams
- Wakili jiyàn ọ̀rọ̀, ó ní òun kò mọ ohunkohun nípa ìṣekúpani tó ń wáyé n'Ibarapa méjèèje
- Nkán ìbànújẹ ni bí ọlọ́pàá ṣé ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC mọ́lé nítorí Wakili- Adari OPC
- Áwa Hausa tá a wà l'Ogbomoṣọ ti di Yorùbá- Oba Haruna Sabo Ogbomoso
- Ọ̀rọ̀ aàbò ní Nàìjíríà ti di kí olórí dorí ẹ mú- Femi Falana
- Wòlíì Kasali gba Bunmi ìyàwó rẹ̀ àkọ́fẹ́ padà, ìjà parí!
Awọn alaṣẹ orilẹede Uk ṣalaye pe igba akọkọ ree ti ti orilẹede Gẹeṣi yoo da owo ti wọn ri gba lati ọwọ ọdaran pada si Naijiria.
Ọdun 2016 ni Naijiria ati ijọba ilẹ Gẹẹsi kọwọ bọ iwe adehun ninu eyi ti ijọba UK ti ṣeleri lati maa da owo tawọn ọmọ Naijiria ba ji ko wa si orilẹede naa pada si Naijiria.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan an oṣu kẹta ọdun 2021 ni aṣoju ijọba orilẹede UK ati Naijiria tu buwọlu iwe adehun mii pe Naijiria gbọdọ lo owo naa fun ipese ohun amayedẹrun.
Bakan naa ni wọn tun jọ ṣe adehun pe ijọba yoo lo lara owo lati pari ọna ilu Eko si Ibadan ati Abuja si ilu Kano to fi mọ afara Niger keji ti iṣẹ n lọ lori rẹ lọwọ.
Ta ni James Ibori?
James Ibori ni gomina ipinlẹ Delta nigba kan ri.
Ṣaaju ni Ibori gbe ni orilẹede UK ni bii ogoji ọdun sẹyin nibi to ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi akọwe owo nile itaja ti wọn n pe ni DIY store niluu London.
Ibori jẹbi ẹsun ole jija nibi to ti n ṣiṣẹ ni London lọdun 1991.
Lẹyin naa lo pada si Naijiria ti o si bẹrẹ si ni ṣe oṣelu.
Ibori di gomina ipinlẹ Delta lọdun 1999, nibẹ lo ti bẹrẹ si ni ko owo ipinlẹ naa lọ si ilẹ okeere.
Ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ si ni ṣe iwadii Ibori lọdun 2005 nigba ti o fẹ ra baalu agberapa ti tara rẹ.
Ọdun 2012 ni wọn fi ẹsun jibiti onikoko mẹwaa kan an to le ni biliọnu mejidinlọgbọn ṣugbọn wọn fi silẹ lọdun 2016.












