Aráàlú fọnmú bí Sanwo-Olu ṣe fẹ́ fi N3bn ra fáànù, N7.5m ra lọ́fíńdà, ìjọba ṣàlàyé

Aworan Gomina Sanwoolu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gomina Babajide Sanwoolu ni awọn araalu ti bẹrẹ si nii tabuku rẹ latari bi wọn ṣe gbọ pe o buwọlu biliọnu mẹta naira lati ra faanu si ọfiisi igbakeji rẹ, Obafemi Hamzat.

Bakan naa ni wọn tun gbọ pe o tun fẹ fi miliọnu meje abọ naira ra turari oloorun didun si ọfiisi tirẹ.

Bakan naa lawọn eeyan bẹrẹ si nii sọrọ lori ẹrọ ayelujara lori awọn iṣẹ akanṣe ti ileeṣẹ to n ba ijọba ra ọja gbe sita ni saa keji ati ikẹta ọdun 2023.

Ojilenirinwo miliọnu naira si ni wọn fẹ fi ra ọkọ afaragbọta fun lilo ni ọfiisi olori awọn oṣiṣẹ gomina.

Ọfiisi olori awọn oṣiṣẹ gomina yii tun gba miliọnu mejidinlogun-abọ naira lati fi pin ẹgbẹwa adiyẹ kaakiri awọn ijọba ibilẹ ati wọọdu idibo to wa nipinlẹ naa.

"Miliọnu mejilelaadọjọ naira wa fun ipese omi ni aafin Idunganran to jẹ ibugbe ọba ilu Eko"

Gẹgẹ bii akọọlẹ ti awọn eniyan fi si ori ikanni X, ijọba Eko tun fọwọ si miliọnu mejilelaadọjọ naira fun ipese omi ni aafin Idunganran to jẹ ibugbe ọba ilu Eko.

Ninu iwe ọhun, ile ijọsin Anderu mimọ to wa ni Oke-Popo ni yoo gba atunṣe oni miliọnu to fẹẹ to ẹgbẹta naira.

Iwe isuna ọhun ni wọn lo tun fi han pe ipese ọgbọn miliọnu naira wa fun ọfiisi igbakeji gomina lati fi kan si awọn to ku diẹ kaa to fun lawujọ.

Abẹ idari iyawo igbakeji gomina si ni ọọfisi naa wa, ti ọgbọn miliọnu miran si wa fun ironilagbara awọn taa wi yii.

Oludije ninu ẹgbẹ ADC l‘Eko lo tu asiri ọrọ naa, ti araalu fi fọnmu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ‘Action Democratic Congress (ADC) nipinlẹ Eko lọdun 2023, Funsho Doherty, wi pe oun ti kọwe si Gomina Sanwo-Olu lati boju awọn mkan to wa ninu eto iṣuna naa.

Doherty kọ soju opo X rẹ pe “lilo owo ilu lọna to tọ ṣe pataki, paapaa julọ lakoko yii”.

Ọpọ awọn to n lo ikanni X lo koro oju si iwe ọhun, ti wọn si ni ko yẹ ki ijọba maa na owo ilu ni ina apa lai ro ti iya to n jẹ awọn araalu.

Lara ohun ti wọn sọ ni yii:

@SavvyRinu wi pe “idi ti awọn kan ko fi fẹẹ pa ara wọn dipo ki idibo ti ko ni magomago ninu o waye ree”.

@Kelvin18123 wi pe “ko si ẹni to lee ṣe iṣẹ ara rẹ bayii. Idi ti iru nkna bayii fi n tẹsiwaju ni pe wọn kii ran awọn eeyan lẹwọn fun nina owo ijọba ni ina apa”.

Ni ti @biodun_alao, “eleyii ṣini loju. Mi o mọ idi ti olori oṣiṣẹ lọfiisi gomina yoo fi maa pin adiyẹ. A n reti esi ti ijọba yoo fun wa”.

@DJDaley wi pe “kẹẹ si waa maa wo, ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira pere ni owo oṣiṣẹ to kere jul;ọ nipinlẹ Eko o”.

Ni iwoye @iam_wilsons, “eyi jẹ ohun ẹlẹya. Awọn oloṣelu Naijiria buru jayi”.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Awa ko ni nkankan fi pamọ - Ileeṣẹ to n ba ijọba Eko ra ọja salaye

Ileeṣẹ to n ba ijọba ra’ja nipinlẹ Eko lo ti fesi si ọrọ to n tan kalẹ naa lori ẹrọ ayelujara lori iye owo ti ileeṣẹ naa fẹẹ fi ra awọn ohun elo kan lọfiisi gomina ati igbakeji rẹ.

Ọga agba ileeṣẹ ọhun, Fatai Onafowote, ninu atẹjade to fi fesi sọrọ naa wi pe funfun nẹnẹ ni ọwọ awọn mọ pẹlu gbogbo ohun ti ileeṣẹ oun ba n ṣe.

Onafowote wi pe alaye ti ko kun lo faa ti awọn eeyan fi gba ọrọ naa sodi.

O fi kun pe ofin iduna-dura ipinlẹ Eko lo de gbogbo ohun ti ileeṣẹ naa ba n ṣe.

Atẹjade naa ka pe: “A kabamọ pe alaye ni kikun, papa julọ to nii ṣe pẹlu awọn ohun ti ijọba fẹẹ ṣe ti fa ariyanjiyan, to si lee tabuku ijọba ati awọ ileeṣẹ to n ba ijọba dowo pọ.

“Eyi lo waye latara bi ko ṣe si alaye kikun lori awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba fẹẹ gbe sita, to si mu ki awọn eeyan gbaa sodi.

“A faramọ bi awọn eeyan ṣe fi ẹdun ọkan wọn han, a si tọrọ aforiji fun ohun ti eyi le fa fun wọn. A ko nii lọkan lati ṣe ohun ti yoo fa aigbọra-ẹni ye tabi tabuku awọn eeyan atawọn ileeṣẹ to nii ṣe pẹlu ọrọ yii."

“Ki awọn olugbe ipinlẹ Eko o lee gbe aye irọrun ni o jẹ wa logun"

Fatai Onafowote tẹsiwaju pe “Lati le jẹ ki ọrọ yii ni ojuutu, ileeṣẹ yii ti gbe igbesẹ lati ṣe alaye ni kunkun, lẹsẹẹsẹ, lori gbogbo iṣẹ akanṣe yii lati le jẹ ki o han gbangba si awọn araalu ko ma baa si awuyewuye mọ.

“Ileeṣẹ yii yoo tẹsiwaju lati mu agbega ba bi o ṣe n fi ọrọ lede fawọn araalu nitori pe o yẹ ki ọrọ ijọba o ye awọn eeyan ni ketekete.

“Mo si fẹẹ ran awọn araalu leti pe ki ileeṣẹ yii o lee ṣe ojuṣe rẹ lai ni magomago tabi itọwọbọ latọdọ ẹnikẹni, la ṣe da duro gedengbe.

A fi da awọn eeya loju pe ileeṣẹ wa yoo tẹsiwaju lati maa ṣe ohun to tọ lai figba kan bọ ọkan ninu, a o si tun rii daju pe awọn afilede wa ko nii ruju mọ.

“Ki awọn olugbe ipinlẹ Eko o lee gbe aye irọrun ni o jẹ wa logun, a si n fi daa yin loju pe a ko ni jakan ninu ipinnu yii.”