Air polution: WHO ní mílíọ́nù méje èèyàn ni ìdọ̀tì inú afẹ́fẹ́ ń pa lọ́dọodún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ri si eto ilera lagbaye, WHO ti kede pe idoti inu afẹfẹ jẹ ọkan gboogi lara awọn iṣoro to n dojukọ agbaye lasiko yii.
WHO ni ko din ni miliọnu meje eeyan ti ẹmi wọn sọnu lọdọọdun nitori oniruru awọn arun ti idọti inu afẹfẹ n fa.

Oríṣun àwòrán, facebook: U.S. Mission Nigeria
O ni awọn orilẹ-ede ti ko rọwọ họri ni iṣoro naa dojukọ julọ niroti igbẹkẹle wọn ninu epo rọbi gẹgẹ bii ohun amuṣagbara.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ ló fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ mí, àyàfi Dudu Heritage nìkan
- Sunday Igboho kò tíì bọ́ lọ́wọ́ wa, á fi ẹ̀sùn míì kàn-án - Malami
- "Màálù tó ya sójú pópó kọlu ọ̀kadà ọmọ mí, tó sì kú ní ìkómọ ọmọ rẹ ku ọ̀la"
- El-Rufai fẹ́ kó jàndùkú wọ apá Gúúsù ló jẹ́ kó tako òfin ìdaranjẹ̀ nígboro - Akeredolu
- Ọwọ́ Biola Fowosere tẹ afurasí olè tó kó fóònù àti owó rẹ̀
O ni lara awọn idọti inu afẹfẹ ni siga mimu ati jijẹ awọn ounjẹ ti ko tọna.
Ṣaaju ni WHO ti kọkọ sọ fun awọn orilẹ-ede mẹ́rìnléláàdọ́wàá (194) lagbaye lati mu adinku ba bi efin ṣe tu jade lawujọ, ki wọn si ṣe awọn ohun to yẹ lati fopin si awọn iṣoro ti ayipada oju ọjọ n mu lọwọ.
Adari agba ajọ ọhun, Tedros Adhanom Ghebreyesus sọ pe "Ipenija nla ni idọti inu afẹfẹ n mu ba gbogbo orilẹ-ede lagbaye, ṣugbọn awọn orilẹ-ede ti ko ri jajẹ ni iṣoro naa n koju julọ."
"Nnkan bii miliọnu meje eeyan lo n ku lọdọdọdun nitori awọn arun ti idọti inu afẹfẹ n fa."
WHO sọ siwaju si pe awọn arun na le dí idagbasoke ẹdọforo awọn ọmọde lọwọ.
Lara awọn agbalagba ẹwẹ, idọti inu afẹfẹ le fa aisan ọkan, to fi mọ arun rọpa-rọsẹ.
- Ìjọba ẹ má wòran, àjà ilé Aṣòfin tó ń jò le wó lé wa lórí - Aṣòfin sọ̀rọ̀ ṣókè!
- Ọ̀run yóò ya bọ́ tí ààrẹ kò bá wá láti ẹ̀kùn gúúsù Nàíjíríà - Joe Igbokwe
- Wo èèwọ̀ mẹ́wàá to fi lè bọ́ lọ́wọ́ ewu iná gáàsì
- A pàdánù Ìyá Nkechi Blessing láìpẹ yìí- Toyin Abraham
- Sunday Igboho kò tíì bọ́ lọ́wọ́ wa, á fi ẹ̀sùn míì kàn-án - Malami














