Oxford AstraZeneca - Ìjọba àpapọ̀ ní kò séwu nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára

Ọjọgbọn Akin Abayomi

Oríṣun àwòrán, Prof Akin Abayomi

Yoruba ni eeyan kii daradara ko ma ku sibi kan, bẹẹ si ni a kii waye, ka ma ni arun kan lara.

Bẹẹ lọrọ fẹ ẹ ri pẹlu abẹrẹ ajẹsara Oxford AstraZeneca to wa lati dena arun Coronavirus, eyi ti wọn ti ko wọ orilẹede Naijiria bayii.

Lọwọ lọwọ bayii, ko din ni eeyan ẹgbẹrun mẹjọ to ti gba abẹrẹ ajẹsara naa nilẹ wa, gẹgẹ bi igbimọ amusẹya lori arun Coronavirus se wi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ sa, ajọ naa ni ipinlẹ Kogi nikan ni ẹnikẹni ko ti gba abẹrẹ naa nitori bi isẹ atunse se n lọ lọwọ lori ẹrọ amunkan tutu rẹ, ti wsn yoo ko abẹrẹ naa pamọ si.

Abẹrẹ ajẹsara

Oríṣun àwòrán, EPA

Amọ nibayii, Kọmisana feto ilera nipinlẹ Eko, Akin Abayomi ti sisọ loju rẹ pe awọn ewu kan wa to rọ mọ gbigba abẹrẹ ajẹsara AstraZeneca naa.

Dokita Abayomi ni lootọ ko si ohunkohun to se oun ni ọjọ akọkọ ti oun gba abẹrẹ ajẹsara naa amọ lọjọ keji ni ori n fọ oun, ti ara si tun n ro oun pẹlu.

"Lọjọ keji ni otutu n mu mi, ara n ro mi, ti oju ibi ti mo ti gba abẹrẹ naa si n dun mi amọ mo lo oogun ara riro, mo sere idaraya, ti mo si lọ sun.

Nigba ti mo taji, se ni ara mi le koko, ti mo si wa daada."

Kaakiri agbaye, awọn orilẹede kan ti n fofin de gbigba abẹrẹ ajẹsara naa nitori abajade rẹ lara awọn eeyan kan ti wọn lo n mu ki ẹjẹ wọn di.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Mọ̀ si nípa àṣà ìsọmọlórúkọ́ nílẹ̀ Yorùbá àti ìtumọ̀ orúkọ̀ fún ìkókó

Lọwọ lọwọ, orilẹede Spain, Germany, France, Italy ati Holland naa ti darapọ mọ awọn orilẹede to ti dawọ duro lori fifun awọn eeyan wọn ni abẹrẹ naa.

Ohun ti wọn lo sokunfa igbesẹ wọn ọhun ni bi ẹjẹ awọn eeyan kan se n di.

Amọ ajọ eleto ilera lagbaye WHO ti kede pe kawọn eeyan mase dẹkun gbigba abẹrẹ ajẹsara naa nitori ko si ewu ninu rẹ.

WHO ni ko si ẹri kankan to daju nipa aleebu ti wọn ni abẹrẹ ajẹsara naa ni, eyi to ni se pẹlu ewu ẹjẹ didi.

Àkọlé fídíò, Adebunmi Adeyeye: Mo jẹ gbèsè gbọ́múléláńtà, ìdí iṣẹ́ kabúkabú ni mo ti ri san

Nibayii, ijọba apapọ ti fọwọ gbaya fawọn araalu pe ko si ewu kankan nidi gbigba abẹrẹ naa.

Dokita Shuaib Faisal, tii se akọwe apapọ fun ajọ eleto ilera alabọde ni Naijiria lo fọwọ gbaya bẹẹ pẹlu afikun pe, tori abẹrẹ ajẹsara Oxford AstraZeneca jẹ olowo pọọku, ko tumọ si pe ko pegede to.