USSD: Wo nǹkan tó yẹ kí o mọ nípa owó USSD tí CBN wọ́gilé ní Báǹkì àti àǹfààní rẹ̀

USSD

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló ti n bèèrè pé kí ní ìtumọ̀ owó tí àwọn bánkì máa ń yọ ti ènìyàn bá fi owó ránṣẹ́ sí ẹlomiran láti orí ẹ̀rọ iléwọ́?

Owó yìí ni wọ́n ń pè ni Unstructured Supplimentry Data Service (USSD), tí aráàlú sì fẹ́ mọ ohun tó ni ṣe pẹ̀lú àwọn.

Ní báyìí, CBN tí ni Nàírà mẹ́fà àti kọ́bọ̀ mẹ́jìdílọ́gọ́rún (N6.98) ni ki wọ́n má yọ lórí gbogbo ènìyàn to ba lo ami asiri Code fi fowo ransẹ lori ẹrọ alagbeka.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bánkì àpapọ̀ Nàìjíríà (CBN) àti àjọ tó n sàkóso àwọn ilé iṣẹ́ ìbáraénisọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà (NCC) si ti gbé òfin tuntun jáde láti le mú èdèàiyedè tó máa n wáyé láàrin àwọn bánkì àti àwọn ilé iṣẹ́ ibáraẹnisọ̀rọ̀ kúrò.

Ofin tuntun naa lo ti gbérasọ láti ọjọ́ Iṣẹ́gun, ọjọ́ kẹrìndílógun oṣù kẹta ọdún 2021.

USSD

Gbèdéke owó tuntun yìí ni ibi ti wọ́n fẹnukò sí nígbà ti báǹkì àti àwọn ilé iṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ se ìpàdé ni ọjọ́ ajé

CBN àti NCC ní àwọn yóò ma bá àwọn ilé iṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ náà gba owó wọ́n láti inu àpà ìkówópamọ́ àwọn alábàrá wọn.

"Bánkì ni máa yọ owó ti kò tọ́ mírà lọ́wọ́ àwọn oníbàra wọ́n nítorí pe wọ́n lo USSD," èyí jẹyọ nínú àtẹjáde ti CBN àti NCC fọwọ́sí.

Kíni ìtumọ̀ USSD àti pé kíní UUSD ni Bánkì

Ǹkan ti USSD túms sí ni pe àwọn ìrànwọ́ míràn ti bánkì máa se fáwọn oníbarà wọ́n (Unstructured Supplementary Service Data), ẹ̀yí ló máa n ran àwọn alábàrà tí ko bá ni fóònù ìgbàlódé lọ́wọ́ tàbí tó n lo pálasà láti fówó ránsẹ lórí ẹrọ ìbánisọ̀rọ̀ wọ́n pẹ̀lú kóòdù.

USSD yìí náà sì fẹ́ fara pé ǹkan ti a mọ̀ sí ìfọ̀rọ̀ránṣẹ́ kéékèké (SMS) sùgbọ́n ìyàtọ̀ díẹ̀ wà lára wọn.

Ní ti USSD àwọn oníbàrá le yan abala tọ bá wù wọ́n nínu láti orí ẹ̀rọ ìléwọ́ wọn.

Yàtọ sí bi SMS ṣe n ṣiṣẹ́, USSD máa n síṣẹ́ ni wàrà ǹ ṣesa pẹ̀lú bánkì. Ìtumọ̀ èyí ni pé, abala mẹ́jì ni ìfọ̀rọ̀ ránṣẹ́ tirẹ̀ pín si níwọ̀n ìgbà tí ààyè bá ti wà, ìbéèrè àti ìdáhùn náà yóò ma wá ni ṣíṣẹ̀ ń tẹ̀lé.

Àkọlé fídíò, Farmers Herders Crisis: Rẹ́rẹ́ rún, ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò lágbègbè Ariwa Yewa

Onírúrurú ǹkan ni àwọn ènìyàn máa lò USSD fún.

  • Fífi ẹ̀rọ iléwọ́ ṣètò o'wó ní Bánkì: Lilo USSD fún sísàn tàbí gba owó ni Bánkì kò dàbí lílo áàpù tí ènìyàn yóò nílo láti wọ orí ayélujara, bákan náà ni ènìyàn nílò ẹ̀rọ ìléwọ́ ìgbàlódé. kí ó tó ṣiṣẹ́.
  • Wọ́n má nlo USSD láti ṣe àtúntò ojú òpó ìbáraẹnisọ̀rọ̀; USSD jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tí wọ́n fí n tún ẹ̀rọ iléwọ́ sẹ yálà láti ṣe àtúntọ tàbi àtúnṣe ojú òpó ibáraẹnisọ̀rọ̀ tí àwọn alábàrárà le ló fún oníruurú ǹka bí kátàkárà.
  • Lílò fún ṣíṣe afíkun nípa alábàrá: Wọ́n máa n lo USSD láti ṣe àsopọ̀ láàrín àwọn elétò nípa àwọn alábàrá, láti pè fún ẹ̀kúrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwọn alábàrá àti gbígba dátà wọ́n.
  • Lilo fun ìwádìí ìmọ̀lára àwọn alábara: Wọ́n máa n fi USSD se ìpólówó ọjà, bí àpẹrẹ àwọn ilé iṣẹ́ a maa lo láti fi se ìwádìí lọ́wọ́ àwọn alábàrà láti mọ ǹkan ti wọ́n nífẹ́ẹ̀ sí, èyí máa n ra àwọn ilé iṣk lọ́wọ́ láti mọ́ ǹkan ti àwọn alábàrá wọ́n fẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
  • Wọ́n máá n lò fún ètò pípeni padà: Àwọn ilé iṣẹ́ adójútòfò, àti ilé ìfọ́wọ́pamọ́ máa n lo USSD láti mọ́ nípa ǹkan ti alábàrá wọ́n n fẹ́, wọ́n a fún wọ́n ni ànfàni láti pe ilé iṣẹ́ wọ́n padà lẹ́yìn ti wọ́n bá ti fi ǹkan ti wọ́n ní hàn wọ́n.
  • Lati fidi rẹ múlẹ̀ pé àwọn ti rí ọjà tí ènìyàn fẹ́ rà: Ọ̀pọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ló máa n lò láti ṣe ìsopọ̀ láàrín ilé iṣk àti onibara tí ènìyàn bá pè fúnrira oja lori ayelujara, èyí si ni yóò sọ fún oníbara nígbà ti ọjọ́ rl bá tí n bọ̀ lọ́nà.
  • Kupọn àti ìwé ẹ̀bùn: Àwọn ilé ìtajà máa n lò USSD láti ta àwọn oníbàrá wọn lólobó nípa àwọn ǹkan tuntun ti wọ́n ni, bákan n'[a ni wọ́n yóò fi Kupọ́n àti ìwé ẹ̀bùn ṣọwọ́ sí wọn.