Iba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé Yorùbá síbẹ́, ó lè burú ju àwọn míì lọ

Àkọlé fídíò, Iba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé màláíkà kan lọ sí Aso Rock, kò lè ṣàṣeyọrí

Aarẹ Ọna Kakanfo ti ilẹ Yoruba, Ọtunba Gani Adams ti ni ọrọ ijinigbe ko ṣe ajoji si ijọba kankan ni Naijiria.

O ni daju daju, ijọba mọ si ohun gbogbo to n ṣẹlẹ nipa ijinigbe lorilẹ-ede yii.

Iba Gani Adams jẹ ko di mimọ pe Kò sí ìdàmú ìlú tó kọjá ọjọ́ mẹ́ta láì lọ́wọ́ ìjọba nínú.

Ọ ni ni ti ẹgbẹ OPC atawọn agbaagba Yoruba, wọn n gbiyanju ninu riran awọn eniyan lọwọ ṣugbọn sibẹ, iwọnba ni ohun ti wọn lee ṣe lai si aṣẹ ijọba ko ma lọ di pe wọn n fi ọwọ ofin mu awọn eeyan awọn.

Ẹwẹ, Aarẹ Ọna Kakanfo ni koda bi ipo ààrẹ ba bọ si ọwọ̀ iran Yoruba, o ṣee ṣe ki o buru ju ti ẹlomii gan lọ.