Coronavirus: Gbogbo ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama yóò wá ní titipá ní Italy

Oríṣun àwòrán, Reuters
Orileede Italy lawọn n gbero lati ti gbogbo ile ẹkọ ati fasiti lorileede naa pa nitori ajakalẹ aisan Coronavirus.
Erongba lati gbe igbesẹ yi waye nibi ipade kan tawọn alaṣẹ ijọba ṣe eleyi to n gbero pe ki wọn ti awọn ile ẹkọ pa titi di aarin oṣu Kẹta.
Wọn ni eleyi jẹ ọna pajawiri lati koju aisan Coronavirus to n ja kaakiri ilẹ naa.
Minisita feto ẹkọ nilẹ naa Lucia Azzolina nigba to n fesi si iroyin yi ti ọpọ ileeṣẹ iroyin ti gbe sọ pe awọn ko ti fẹnuko lori igbesẹ yi ṣugbọn awọn yoo bun wọn gbọ laipẹ.
Ẹwẹ, orileede Faranse ti ti awọn ileẹkọ to wa ni agbegbe Paris pa.
Ọgọfa ileewe ni yoo wa ni titi pa lawọn agbegbe ti ajakalẹ aisan yi ti peleke.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ileewe alakọbẹrẹ ati awn ileewe girama lọrọ yi kan ni ariwa Paris nibi ti eeyan meji to padanu mi wọn lọwọ aisan yi n gbe.
Yatọ si Paris, orileede Saudi naa ti kede pe awọn ko ni gba nikẹni laye yala ọmọ ilu tabi alejo lati kopa ninu Umrah gẹgẹ bi ọna lati koju itankalẹ Coronavirus.
Lọsẹ to kọja ni wọn wọgile Umrah fawọn ara ita.
Lọjọ Aje ni Saudi kede pe eeyan kan to jẹ ọmọ Saudi ni ẹni akọkọ ti yoo ko aisan naa.Arakunrin naa ririn ajo lọ si Iran nibiti ajakalẹ naa peleke julọ nilẹ larubawa.












