APC: A kò ní takò ìdájọ ilé ẹjọ lórí àṣẹ lọ rọọ́kún nílé Oshiomole

Aworan Adams Oshiomole

Oríṣun àwòrán, Google

Ọrọ aṣẹ lọrọọkun nile ti ile ẹjọ pa fun alaga ẹgbẹ oṣelu APC ma tun ti gba ọna mi yọ pẹlu bi Adams Oshiomole ti ṣe sọ pe ohun ṣi ni alaga ẹgbẹ naa.

Ninu ọrọ atẹjiṣẹ ti agbẹnusọ Oshiomole Simon Egbegbulem fi ranṣẹ si akọroyin wa, o ni awọn ti kọwe kotẹmilọrun lati tako idajọ naa.

O ni toun ti bi gbogbo igbeṣẹ ti ṣe n lọ ni iwaju ile ẹjọ kotẹmilọrun, Adams Oshiomole ṣi ni alaga ẹgbẹ naa.

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress APC ti fesi si aṣẹ ile ẹjọ giga Abuja to ni ki alaga ẹgbẹ naa Adams Oshiomole lọ rọọkun nile.

Adele akọwe ẹgbẹ naa Victor Giadom lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC.

Giadom ni ẹgbẹ awọn yoo bọwọ fun aṣẹ ti ile ẹjọ pa pe ki Oshiomole yẹba ṣẹgbẹ kan titi ti wọn yoo fi gbẹjọ lori yiyọ nipo.

Adams Oshiomole

Oríṣun àwòrán, Jubril A. Gawat

Àkọlé àwòrán, Ọpọ onwoye gbagbọ pe omi n bẹ lamu fun Oshiomole lori iṣọkan ẹgbẹ oṣelu naa

Nigba ti akọroyin wa beere lọwọ Giadom nipa iroyin to n ja rain pe awọn agbofinro ti wa ọkọ gunlẹ niwaju oluileeṣẹ ẹgbẹ naa ni Abuja, o ni ko si ohun to jọ bẹ.

''Ko si iyatọ ninu nkan to n ṣẹlẹ niwaju ile ẹgbẹ.Bi ibẹ ti ṣe ma n ri ni gbogbo igba ni yẹn''

Igbimọ Amuṣẹya fi ontẹ lu Ajimobi ati awọn oloye ẹgbẹ tuntun mi

Ni ọjọru kannna ti awuyewuye lori aṣẹ lọ rọọkun nile Oshiomole n waye, akọwe ipolongo ẹgbẹ Lanre Issa Onilu ti fi atẹjade sita pe ẹgbẹ ti fontẹ lu awọn oloye apapọ ẹgbẹ mẹta tuntun.

Ninu wọn la ti ri Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri Senatọ Abiola Ajimobi ti wọn yan si ipo igbakeji alaga ẹgbẹ fun Iwọ oorun Guusu.

Sẹnẹtọ Ajimobi

Oríṣun àwòrán, @AAAjimobi

Àkọlé àwòrán, Abiola Ajimobi

Bẹẹ naa ni wọn ni Arch Waziri Bulama ni yoo jẹ akọwe ẹgbẹ ti Paul Chukwuma yoo si jẹ oluyẹweowowo ẹgbẹ.

Bi ọrọ naa ti ṣe ṣẹlẹ lọjọru re e

Ile ẹjọ giga kan to fi ilu Abuja ṣe ibujoko ti paṣẹ pe ki alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC,Adams Oshiomole lọ rọọkun nile.

Adajọ Danalami Senchi to fi idajọ yii mulẹ ni ki Oshiomole fi ipo alaga silẹ fun igba diẹ, titi ti awọn yoo fi yanju ẹjọ tawọn kan pe lati yọ ni ipo alaga ẹgbẹ naa.

Adajọ niigbẹjọ ọrọ yi yoo waye lọjọ keje ati ikẹjọ oṣu Kẹrin ọdun 2020.

Lẹnu ọjọ mẹta yii, awuyewuye ti n waye lori iṣakoso Oshiomole gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ naa ni Naijiria.

Bi a ko ba gbagbe awọn alaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Edo, ti o jẹ ipinlẹ Oshiomole ti sọ pe, awọn ko ni igbagbọ ninu iṣakoso Oshiomole gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ.

Yatọ si aawọ pẹlu awọn alaga wọn yii, awọn Gomina kan ninu ẹgbẹ APC naa ko yọnu si Oshiomole gẹgẹ bi alaga.

Àkọlé fídíò, #Oshimole: Àwọn aṣáájú APC kò mọ ohun ti wọ́n n ṣe lásìkò yí

Titi di bi a ti ṣe n ṣe akojọ iroyin yi, ẹgbẹ APC ko ti fesi si idajọ ti ile ẹjọ yi gbe kalẹ.