Èèyàn mẹ́tàdínlógún farapa lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì ní Croatia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iṣẹlẹ ilẹ riri to waye ni Zagreb, tii ṣe olu ilu Croatia ti ba ọpọlọpọ ile, ọkọ ati dukia jẹ nilẹ naa.
Awọn adoola ẹmi sọ pe ọmọ kekere kan ti wa lẹsẹ kann aye, ẹsẹ kan ọrun lẹyin ti orule kan wo lu ọmọ ọhun lori.
Gomina olu ilu naa ti rọ awọn ara ilu lati lọ fara pamọ sile wọn nitori ibẹru Coronavirus to wa nigboro.
Wọn ni iṣelẹ ilẹ riri ọhun ni iru rẹ to buru ju ti yoo ṣelẹ si ilu naa lati nnkan bi ọgọrun un ọdun o le diẹ sẹyin.
Yatọ si ọmọ kekere ọhun, awọn eeyan mẹrindinlogun mii tun farapa.
EFCC: Ilé ẹjọ́ gba onídùró Oyo-Ita pẹ̀lu ₦100 mílíọ́nù

Oríṣun àwòrán, @usmanlawal
Ile ẹjọ giga ilu Abuja ti faye gba beeli adari awọn oṣiṣẹ Naijiria tẹlẹ, Winifred Oyo-Ita lẹyin to foju bale ẹjọ lori ẹsun ikowojẹ.
Wọn fi ẹsun mejidinlogun kan Ita-Oyo niwaju adajọ Taiwo Taiwo pẹlu awọn alabaṣiṣẹ rẹ tẹlẹ, Barba Umar ati Ubong Okon Effiok, ti awọn mẹtẹta si sọ pe wọn kojẹbi ẹsun ti wọn kan wọn.
Ninu idajọ rẹ to ṣe, adajọ Tawio gba oniduro Oyo-Ita faye gba beeli pẹlu Oyo-Ita ọgọrun un miliọnu naira, bẹẹ lo si gba oniduro Effiok ati Umar pẹlu aadọta miliọnu naira fun ẹnikankan wọn.
Adajọ ọhun wa ni ki awọn memeji pese eeyan to dantọ lati jẹ oniduro fun wọn, bẹẹ lo tuin sọ awọn ohunn miran to yẹ ki wọn ṣe.
Lẹyin eyii lo fa awọn mẹta naa le agbẹjọro wọn lọwọ, to si kan nipa fun wọn lati maa farahan nileeṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC titi wọn yoo fi san owo beeli naa atawọn nnkan mii to yẹ ki wọn ṣe.
Adajọ naa wa kilọ fun wọn pe oun yoo dawọn pada sinu ahamọ ti wọn ba kọ lati ṣe awọn ohun to rọ mọ beeli naa.
EFCC: Òní ni ìgbẹ́jọ́ Oyo-Ita àti EFCC nílé ẹjọ́ gíga Abuja

Oríṣun àwòrán, @EFCC
Loni ni igbẹjọ Olórí òṣìṣẹ́ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Arabinrin Winnifred Oyo-Ita lati fojú ba ilé ẹjọ́ gíga ní Abuja lónìí lórí ẹ̀sùn ìkówójẹ́.
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC lo pee lẹjọ lori pe o lu owo ilu ni ponpo lasiko to jẹ adari fun gbogbo oṣiṣẹ Naijiria.
O le ni biliọnu mẹta naira ti wọn fẹsun kan Oyo-Ita pe o ṣe kumọkumọ ki wọn to rọọ loye.
Ṣaaju ni Arabinrin Winnifred Oyo Ita ti kọkọ gba ile iwosan lọ lẹyin ti wọn gba oniduro nigba igbẹjọ akọkọ lọdun 2019.
Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ ọdun 2019 ni EFCC kọkọ bẹrẹ si ni fọrọ waa lẹnuwo.
Oṣu kẹsan an ọdun 2019 ni Aarẹ Buhari kede pe ki Arabinrin Folasade - Esan gba iṣẹ lọwọ Oyo-Ita













