Coronavirus: Akọ̀ròyìn ni ẹni àkọ́kọ́ tí àrùn Coronavirus pa ni Zimbabwe

Oríṣun àwòrán, @matigary
Gbajugbaja akọrọyin ati sọrọsọrọ ori afẹfẹ nilẹ Zimbabwe, Zororo Makamba ti di ẹni akọkọ ti yoo gbẹmi mi nitori arun Coronavirus nilẹ naa.
Ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ ilẹ naa, ZBC lo fi ọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ.
Ọjọ Abamẹta ni ayẹwo fi han pe ọkunrin ọhun ti fara kaasa arun Coronavirus.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Wọn ni ẹni ọgbọn ọdun naa ṣabẹwo si ilẹ Amẹrika loṣu to kọja to si pada si Zimbabwe lati South Africa ki ọlọjọ to de.
Coronavirus: Ọmọ Ọlọrun kò leè lùgbadì àrùn Coronavirus- Ààrẹ Tanzania

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹ-ede Tanzania, John Magufuli ti sọ pe idi ti ijọba rẹ ko ṣe tii wọgile isin lawọn ṣọọṣi ati mọṣalaṣi lorilẹ-ede naa ni pe ibẹ ni ojulowo iwosan wa.
Aarẹ naa lo ṣo ọrọ yi nibi isin kan to waye lọjọ Isinmi ni Dodoma, to jẹ olu ilu orilẹ-ede ọhun.
Magufuli ni ẹmi eṣu ni arun Coronavirus, ko si le gbe ninu agọ ara awọn ọmọlẹyin Kristi.
Aarẹ ọhun to kẹkọọ gboye ọmọwe ninu imọ ijinlẹ kẹmistri, to tun jẹ ọmọ ijọ Katoliiki sọ pe akoko yii lo yẹ ki igbagbọ awọn eeyan tubọ gberu si ninu Oluwa.
O ni "Eṣu ni Coronavirus, ko le gbe ninu agọ ara Kristi nitori lẹsẹkẹṣẹ lo maa gbina sọnu."
Ṣaaju ni orilẹ-ede naa, to wa ni Ila-oorun Afirika ti gbe agadagodo sẹnu ọna gbogbo ileewe, to si ti wọgile gbogbo ere idaraya lati igba ti arun Coronavirus ọhun ti rapala wọ ilẹ naa.
Nigba to n gba awọn eeyan niyanju, o ni "Arun yii yoo dohun igbagbe gẹgẹ bi awọn arun mii to wa ṣaaju rẹ, ṣugbọn a ni lati maa tẹle imọran awọn eleto ilera."
Magufuli ṣe ikilọ funn awọn eeyan lati dẹkun ati maa pin iroyin ofege nipa arun naa ati pe ẹni ti ọrọ naa ba ṣi mọ lori yoo jẹyan rẹ niṣu.
Ni bayii, eeyan mejila lo ti fara kaasa arun Coronavirus lorilẹ-ede naa, ti mẹjọ ninu wọn si jẹ ọmọ ilẹ ọhun.
Corona virus in Nigeria: NCDC kéde pé èèyàn márùn ún míì tún ti lùgbàdì àrùn coronavirus

Oríṣun àwòrán, Twitter/Federal Ministry of Health
Ajọ to gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC tun ti kede pe eeyan marun un mi tun ti ni arun coronavirus.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ninu atẹjade to fi sita lori oju opo Twitter rẹ, NCDC ṣalaye pe eeyan meji ninu awọn marun un naa wa lati Abuja, meji lati ilu Eko nigba ti ẹyọkan to ku wa lati ipinlẹ Edo.
Igba akọkọ ree ti ipinlẹ Edo yoo ni ẹni to lugbadi arun COVID-19.
Meji ninu awọn eeyan marun un naa lo ṣẹṣẹ rinrin ajo de lati orilẹede UK.
Ni bayii, o ti di eeyan marun un le lọgbọn bayii to ti lugbadi arun coronavirus ni Naijiria, eeyan meji ti gbadun ninu wọn.
Ìjọba ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn elétò ìlera láti gbógun ti Coronavirus - Buhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ fun awọn ọmọ Naijiria pe awọn n ṣiṣẹ karakara lati ri wi pe orilẹ-ede Naijiria bori arun Corona virus.
Buhari sọ eyi lasiko to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ loju ọpọ ikansiraẹni Twitter.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Aarẹ Buhari ni awọn n ṣiṣẹ pẹlu ẹka to n ri si eto ilẹra lorilẹ-ede Naijiria lati ri wi pe eto ilera to peye wa fun awọn ọmọ Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Amọ, ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu bi aarẹ Buhari ṣẹ darukọ covid 19.
Igba akọkọ ni yii ti aarẹ Buhari yoo ma a ba awọn Naijiria sọrọ lati igba ti arun Coronavirus ti bẹ silẹ ni agbaye loṣu kejila, ọdun 2019.
O ti le ni ọgbọn eniyan to ti ni arun Coronavirus ni Naijiria.
Bakan naa ni ọpọlọpọ gomina ni orilẹ-ede Naijiria ti kede ki onile o gbele fun awọn eniyan lọna ati dena itankalẹ arun naa.
Ninu ọrọ tirẹ, Gómínà ìpínlẹ̀ Eko Babajide Sanwo-Olu ti kede pé pé kí gbogbo òṣìṣẹ́ ìjọba láti ipile kejila si isàlẹ̀ jòkó silé wọn fún ọsẹ̀ méji.
Sugbọ́n ó ni ikéde yìí yọ àwọn to ṣe àwọn osiṣẹ́ eleto ààbò, awọn panapana àti àwọn onimọ iṣegun.
Bakan náà ni Gomina ni ìjọba ti ṣe àfikún àwọn ilé iwosan ti wọ́n le ko àwọn ènìyàn si.
















