Agbébọn jí obìnrin tó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó láàárọ̀ òní, ọ̀rẹ́ rẹ̀, àtàwọn mẹ́jọ míì gbé lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbebọn ti ji obinrin to n mura igbeyawo ati ọrẹ rẹ timọtimọ gbe labule Chacho, ni ijọba ibilẹ Wurno, ni ipinlẹ Sokoto.
Ileeṣẹ iroyin Channels jabọ pe nnkan bii aago kan abọ oru ni awọn agbesunmọmi naa yabo abule ọhun ti wọn si gbe iyawo, ọrẹ iyawo atawọn mẹjọ mii gbe lọ nibẹ.
Awọn eeyan to n gbe lagbegbe naa sọ pe ọjọ keji ọjọ Aiku naa gan ti iṣẹlẹ ọhun waye ni wọn ji obinrin naa gbe.
Gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lo jẹ obinrin, ayafi ọkunrin kan to farapa lasiko ikọlu naa to si ti n gba itọju lọwọ bayii.
Ọkan lara olugbe ilu naa ti ko fẹ ki awọn akọroyin darukọ oun sọ pe iṣẹlẹ ọhun jẹ eyii to buru jai to si da omi tutu si ọkan awọn.
O ni aarọ oni ọjọ Aje lo yẹ ki obinrin naa ṣe igbeyawo ki wọn to gbe oun ati ọrẹ rẹ lọ.
Ẹni naa fi kun pe awọn ke si awọn agbofinro lasiko ti ikọlu naa n lọ lọwọ amọ wakati kan lẹyin ti awọn agbesunmọmi naa na papa bora ni ọlọpaa to de.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, bi wọn ṣe pẹ de naa jẹ ki ikọlu ọhun tubọ dun awọn eeyan naa.
O ni " A n ke si ijọba ki wọn ji giri si ojuṣe wọn lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu."
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpee ipinlẹ naa, DSP Ahmad Rufa'i, to fidi iroyin naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin Channels ni awọn ti gbe igbesẹ lọri ikọlu ọhun.
Iṣẹlẹ yii tun ti kun oniruru iṣẹlẹ ijinigbe ati iṣẹrubalu to n waye lemọlemọ ni Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii.
Ṣaaju lọjọ Aiku ni awọn agbebọn kọlu ile ijọsin alaṣọ funfun kan nipinlẹ Kogi, nibi ti wọn ti gbe pasitọ atawọn ọmọ ijọ kan lọ nibẹ.
Asiko ti isin n lọ lọwọ ni awọn agbesunmọmi naa kọlu ile ijọsin Cherubim and Seraphim Church to wa ni Ejiba, ni ijọba ibilẹ Yabgba, nipinlẹ ọhun.















