Agbébọn ṣekúpa èèyàn mọ́kànlá níbi ibùdó ìgbafẹ́ ní South Africa

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
- Author, Jaroslav Lukiv
- Author, Mayeni Jones
- Reporting from, Johannesburg
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá orílẹ̀ èdè South Africa ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti ṣàwárí àwọn agbébọn kan tó yìnbọn pa èèyàn mẹ́sàn-án, tí ọ̀pọ̀ míì sì tún farapa.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pé ọkùnrin méje àti obìnrin méjì ni wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn ní Bekkersdal lẹ́bàá Johannesburg lẹ́yìn tí àwọn agbébọn kan tí iye wọn tó méjìlá yawọ ibùdó ìgbafẹ́ kan nínú ọkọ̀ méjì tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀.
Nǹkan bíi aago kan òru ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kejìlá ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe sọ.
Àwọn agbébọn náà ṣíná ìbọn bolẹ̀ báwọn èèyàn ṣe ń sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn.
South Africa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn ti wọ́pọ̀ jùlọ ní àgbáyé. Èèyàn mẹ́tàlélọ́gọ́ta ni wọ́n ń pa ní ojúmọ́ láàárín oṣù Kẹrin sí oṣù Kẹsàn-án ọdún 2025.
Ohun tó sábà máa ń fa ìpànìyàn gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe sọ ni àríyànjiyàn, ìdigunjalè àti ìjà ìgboro láàárín àwọn géńdé.
Ìdí tí wọ́n fi ṣe ìkọlù ọ̀hún kò ì tíì yé ẹnikẹ́ni.
Níbi ìkọlù yìí, igbákejì Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ẹkùn Fred Kekana sọ fún akọ̀ròyìn Newzroom Afrika pé àwọn tó ṣé ìkọlù náà ní ìbọn AK-47 lọ́wọ́, wọ́n sì ní àwọn ìbọn kékeré mìíràn.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Ó sọ pé àwọn tó ṣe ìkọlù náà ṣíná ìbọn bolẹ̀ lásìkò táwọn èèyàn ń ṣe fàájì.
Kekana fi kun pé ìta ibi ìgbafẹ́ náà ni wọ́n ti yìbọn pa àwọn méjì lásìkò tí wọ́n ń gbìyànjú láti sálọ tí ẹnìkẹta sì jẹ́ awakọ̀ èrò kan tó wá já èèyàn kan sílẹ̀.
Nígbà tó ń bá Newzroom Afrika sọ̀rọ̀, olùgbé agbègbè náà júwe bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbọn yínyín ṣe di ohun tó wọ́pọ̀ ní alaalẹ́ ní Bekkersdal.
"Àwọn ọ̀daràn máa ń ṣe bó ṣe wù wọ́n níbi ni," ẹni náà sọ.
"Àwọn ìbọn yìí, alaalẹ́ ni wọ́n máa ń dún… tí ilẹ̀ bá ti ń ṣú lọ ni a ti mọ̀ pé ìro ìbọn máa bẹ̀rẹ̀, wọ́n sì máa ń lágbára.
"Wọ́n máa ń dà wá láàmú gidi ní àdúgbò wa."
Àwọn ìbọn mílíọ̀nù mẹ́ta tí wọ́n ní ìwé àṣẹ ló wà ní South Africa ṣùgbọ́n iye èyí tí kò sí ìwé àṣẹ fún bẹ́ẹ̀ náà ló tún wà gẹ́gẹ́ bí àjọ Gideon Joubery láti ẹgbẹ́ àwọn tó ní ìbọn ní South Africa ṣe sọ.
Àpapọ̀ iye èèyàn tó wà ní South Africa jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́tàlélọ́gọ́ta.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, kò dín ní èèyàn mọ́kànlá, tó fi mọ́ ọmọdé kan, ni wọ́n yìnbọn pa ní ilé kan ní Pretoria.












