Akẹ́kọ̀ọ́ eni ọdún mẹ́fà yìnbọn lu Olùkọ́, ile ẹ̀kọ́ di títì pa!

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Akẹkọọ ọmọ ọdun mẹfa kan lo ti dero atimọle lẹyin to yin lu olukọ rẹ, Abby Zwerner, ẹni ọdun mẹdọgbọn.

Isẹlẹ naa waye ni dede ago meji ọsan ni ile ẹkọ Richneck Elementary School ti wa niluu Newport nipinlẹ Virginia lorilẹede Amẹrika.

Steve Drew to jẹ oloye niluu naa ni awọn ko le sọ ibi ti ọmọ ọhun ti ri ibọn sugbọn ọmọ naa mọmọ yinbọn olukọ rẹ ni.

“A ko ki n ṣe ijamba rara, o mọmọ yin olukọ rẹ nibọn ni. A ko le sọ ibi ọmọ ọdun mẹfa naa ti ri ibọn.”

Olukọ ọhun, Abby Zwerner, ni wọn digba digba lọ si ile wosan lẹyin isẹlẹ, to si farapa gan sugbọn o ti n gba itọju

Awọn agbofinro ti balẹ si ile ẹkọ naa, to ni akẹkọ toto ẹẹdẹgbẹta, lati bẹrẹ iwadii ati lati ṣe ayewo fun awọn akẹkọọ.

Awọn ọlọpaa kọ lati kede iru ibọn ti akẹkọọ fi ṣe olukọ rẹ lese sugbọn wọn ni ibọn kekere ọwọ ni.

Adari ile ẹkọ naa, George Parker ni awọn naa ti bẹrẹ iwadii lati mọ ohun to isẹlẹ ti ọmọ naa fi yinbọn lu olukọ rẹ.

“Ohun iyalẹnu to buru ni. Nnkan bayi ko sẹlẹ ri , ti a si fẹ ri pe ko sẹlẹ mọ.”

Ile ẹkọ ti di titi pa bayi

Ninu atẹjade kan, ile ẹkọ ti ni awọn yoo gbe kọkọrọ si ilẹkun ile ẹkọ naa fun igba diẹ lati fun awọn akẹkọọ ni anfani lati gba gbe isẹlẹ buruku naa.

Ọkan lara awọn Ọbi ti ọmọ rẹ wa nibi isẹlẹ naa,Steve Gonzalez, ni ọmọ sọ fun oun pe olukọ Ms Zwerner ni ki awọn yooku maa salọ lẹyin akẹkọọ naa yinbọn lu.

“O ni o pariwo mọ awọn pe ki awọn maa salọ kete ọmọ naa yinbọn lu.”