̀̀́Wo ǹkan mẹfà tí o kò mọ nípa ẹyà Coronavirus tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹya arun coronavirus tuntun tun ti gbode ti o si ń tete tankalẹ ni ilu Amẹrika, ilu Ọba naa ti kẹfin ẹya coronavirus tuntun naa.
Awọn ohun ti o yẹ ki o mọ nipa coronavirus XBB.1.5 tuntun ree...
Ẹya coronavirus yii jẹ ọkan lara ẹya arun coro miran ti o gbode lẹyin igba akọkọ ti arun coronavirus gbode ni ọdun 2021.
Eyi ti o ti bii ẹya arun miran bi omicron eyiti o yara tan kalẹ ju eeya coronavirus akọkọ.
Ẹya corona XBB.1.5 lọ jade latara ẹya XBB.
Ti wọn kọkọ ri ni ilu Ọba UK ninu oṣu kẹsan-an, ọdun 2021 ṣugbọn ti wọn ka si aarun ti ko lagbara ju gẹgẹ bi iwadii awọn oniṣegun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arun coronavirus eya XXB ni awọn eroja ti o ma n jẹ ki o soro fun awọn kokoro digboluja inu ara rii wọn.
Ọjọgbọn Wendy Barclay lati ile iwosan ijọba ni ilu Ọba Imperial College ni XBB.1.5 ni aisan korona titun miran ti wọn pe ni F486p ni ọna lati lugọ lai farahan. Awọn onisegun lati ajọ to gbogunti arun lagbaye WHO ni iyatọ wa laarin ẹya arun korona XBB.1.5
Ati ti Omicron to ti ṣaaju tan kalẹ, wọn ni ẹya tuntun yii XBB.1.5 kò lagbara to eya omicron ti awọn si gbiyanju lati ṣe iwaadi to peye lori rẹ.
Lorilẹede Amẹrika ida ogoji awọn ti o ni arun korona ni o je ti ẹya titun ti XBB.1.5 lati inu oṣu kejila ọdun to kọja ida mẹrin awọn to ni aarun corona lọ jẹ ti ẹda titun XBB.1.5 eyiti o ti yato si ẹda Omicron.
Awọn to ko aarun corona ni orilẹede Amẹrika ti Pọsi pẹlu akọsilẹ awọn ilẹ iwosan lorilẹede naa.
Ọjọgbọn Barclay ni ẹru aarun corona titun yii nba oun nitori abeere ajesara ti awọn eniyan gba ṣẹṣẹ ko maa ni agbara too lati bori aarun korona XBB.1.5 titun .

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọgbọn Hunter ni ko ti si ẹri to daju pe aarun korona XBB.1.5 lagbara lati ran eniyan lọ si ile iwosan tabi paayan bii ẹya omicron to wa ṣaaju. O ni iyalẹnu Lọ jẹ pe awọn eniyan bẹru aarun korona ti o ja ni orilẹede China lai naani ẹya titun ti o ṣẹṣẹ beere ni ilu Amẹrika. Ọjọgbọn David Heymann ni orilẹede China ko lati fi akọsilẹ iye awọn to lugbadi aarun naa sita eyi ti yoo ran awọn oniṣegun lọwọ lati mo n bi aisan XBB.1.5 ṣe n tan laarin awọn ti ko gba abẹrẹ ajesara COVID-19.














