Ilé ẹjọ́ wọ́gilé ìyọnípò alága àjọ elétò ìdìbò INEC

aworan alaga INEC

Oríṣun àwòrán, @INEC

Adajọ Maryam Hassan ti ile-ẹjọ giga ilu Abuja ti fagile awọn ẹsun to jọ maa ikede dukia eke ti won fikan Alaga ajọ fun eto idibo ti Orilẹ-ede yii (INEC), Ọjọgbọn Yakubu Mahmood.

Ninu igbejo naa, Ile-ẹjọ tun fi ofin de ajọ otelemuye (DSS) ), ọlọpaa, ati Code of Conduct Bureau (CCB) lati ṣewadii Yakubu lori ikede awọn ohun-ini rẹ.

Ninu Iwe ipejọ ti Somadina Uzoamaka kan fi pe e lejọ ẹda eyi ti Adajọ agba fun orilẹede yii naa wa ninu ipejọ naa, Uzoamaka ro ile ẹjọ lati fipa mu Alaga ajọ INEC ko we fipo re silẹ titi iwadii yoo fi waye.

Olufisun naa tun tọrọ aṣẹ lati da Yakubu duro lati di eyikeyi ọfiisi ijọba mu fun ọdun mẹwaa.

Ninu idahun rẹ si ẹsun naa, Ọjọgbọn Yakubu fun ile-ẹjọ ni ọpọlọpọ awọn ẹri lati ṣe afihan awọn orisun owo ti o fi ra awọn dukia naa, bẹẹ gẹgẹ ni Mahmood Yakubu tẹnumọ pe ikede awọn dukia oun ni o ṣẹlẹ lọna tootọ ti o si tẹle ofin.

Ile-ẹjọ naa wọgile awọn ẹsun mẹrinla ti olufisun naa mu wa sile ẹjọ, to si kede pe alaga ajọ INEC ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan.