Bí ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbẹ̀mí ènìyàn 15 ṣe wáyé ní òpópónà Badagry, Eko rèé…

Oríṣun àwòrán, Others
Ọjọ buruku eṣu gbomi mu ni ọjọ ti iṣẹlẹ ijamba ọkọ waye ni agbegbe Badagry ni ipinlẹ Eko ni Ọjọ Aiku.
Eniyan marundinlogun lo padanu ẹmi wọn ninu ọkọ naa,ti gbogbo wọn si n lọ si ibi ayẹyẹ.
Bakan naa ni awakọ ati ẹni to n pero si ọkọ naa ku ninu iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade ti Ajọ FRSC fi lede ni awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ọkọ naa wọ ọkọ lati Yaba, ki wọn si jijọ lọ fun ayẹyẹ ni ilu Benin Republic.
Aago mẹsan an aarọ ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Ade-Mowo to sunmọ Mowo ni opopona ilu Eko si Badagry.
Ajọ to n risi irinna ọkọ nipinlẹ Eko, LASTMA ni ọkọ Mazda to kun fun ero naa ni o fori sọ ọkọ tirela to ko yanrin.
Awakọ naa ni ko mọ ibi ti yoo koju ọkọ si lẹyin to ri tirela niwaju rẹ lasiko to fẹ sare kọja ọkọ to gbe yanrin.
"Eniyan mẹrinla ni wọn ko wa sinu ileewosan ti wọn ti ku lẹsẹkẹsẹ to fi mọ awọn arinrinajo to wa ninu ọkọ naa ati dirẹba pẹlu ọmọ ẹkọsẹ rẹ".
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ to n risi irinna naa ni wọn ti ko oku awọn eniyan to ku naa lọ si ile igbokusi to wa ni ileewosan gbogboniṣe ni Badagry General Hospital.
Ajọ FRSC fikun un pe awọn mẹsan-an lo farapa ninu iṣẹlẹ naa amọ ti eniyan kan ninu wọn tun pada ku ni ileewosan.
FRSC ni awọn ti wọn farapa naa n gba iwosan to peye lọwọ, ti wọn ni ireti pe wọn yoo ye ninu iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni ijọba ba awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn kẹdun, pẹlu adura pe Edua yoo fun wọn ni ẹmi lati la iṣẹlẹ naa kọja.
E ye sare asapajude loju popo – FRSC
Ajọ FRSC ninu atẹjade ti wọn fi lede naa kesi awọn araalu lati maa se jẹjẹ loju popo.
O rọ awọn awakọ igboro ati awakọ ara wọn lati maa se jẹjẹ, ki iru isẹlẹ yii mase maa waye ni igba de igba.
Ajọ naa ni iru ijamba yii ko ni waye kani awakọ naam ọ lati duro ni aye rẹ.
O ni isẹlẹ naa waye nitori bi awọn awakọ naa se n gbiyanju lati kọja ara wọn lasiko ti ojo arọrọda n waye.
O ni eyi jasi bi awọn ọkọ naa se fi ori sọ ara wọn, ti wọn si ọpọlọpọ si padanu ẹmi wọn.
Ajọ naa ni awọn ko ni dẹkun lati maa fi iya jẹ awọn to n sa ere asapajude loju popo, ti wọn yoo si maa fi oju wina ofin.














