‘Àwọn oúnjẹ mẹ́fà tóo lè jẹ rèé tí ọpọlọ rẹ yóò máa jí pépé’

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn ounjẹ wa lorisirisi to lee mu anfaani ba agọ ara rẹ ati ihuwasi awọn ọmọ eniyan.
Awọn ounjẹ yii tun ma n se anfaani fun ọpọlọ eniyan ti yoo si jẹ ko jaa geere, ko si ṣisẹ bi o se yẹ.
Awọn ọrọ igbani niyanju ti onimọ nipa ihuwasi eniyan ati ọpọlọ, Uma Naidoo sọ niyii ni ileẹkọ imọ nipa eto ilera ni fasiti Harvard, lorilẹede Amerika.
Ninu ọrọ rẹ lo ti fidi rẹ mulẹ pe, ihuwasi eniyan niiṣe pẹlu iru ounjẹ ti wọn n jẹ, eleyii ti yoo mu ibasisẹpọ to dan mọran wa laarin awọn mejeeji.
Onimọ naa ni ohun to mu ki wọn jọ maa ṣisẹ pọ nipe inu embryo kan ni wọn ti wa, ti okun kan naa si so wọn pọ.
Onimọ naa ni ti eniyan ba jẹun ti ko to, ọna ọfun naa le wu, ti ko ni ni ni ilera to peye, eleyii le fa aisan ọpọlọ, bii irẹwẹsi ọkan.
Onimọ naa ni lilo vitamin bii Vitamin B, b-12,B-9 ati B-1, to si salaye awọn anfaani to n se fun ara.
Ẹroja ounjẹ bii Ginger, turmeric, saffron, ti wọn n pe ni ‘’Spices’’

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn eroja ounjẹ bii Tumeric ma n se ara loore, to si ma n mu ki ọpọlọ ji pepe nitori awọn eroja anti-oxidant to wa ninu rẹ.
Omiran bii re ni wọn pe ni Curcumin to wa ninu Tumeric to si le mu ki ara eniyan balẹ ti ọkan rẹ bag be soke.
Ominran ni eroja Saffon ti wọn ni o m n mu ki ara eniyan to ba ni irẹwẹsi ọkan balẹ, ti yoo si fi ni ọkan balẹ.
Iwadii fihan an pe ẹnito ba jẹ yoo ri pe ilera ara rẹ yoo ji pepe.
Awọn ounjẹ ti wọn n pe ni ‘’fermented foods'' bii ''Yoghurt''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orisirisi ni awọn ounjẹ to wa ni ipele yii to si le se ara loore.
Awọn ounjẹ yii ma n ni adapọ miliki, ẹfọ ati awọn ohun miran bii microorganism bii yeast ati bacteria.
Eyi to wọpọ ni wọn n pe ni ohun ẹlẹrindodo bii yoghurt ati awon miran bii sauerkraut, kimchi ati Kombucha.
Awọn ounjẹ bii iru eleyii ma n da abo bo ọpọlọ eniyan, ti kii si jẹ ki iṣẹ ọpọlọ eniyan dinku lai pe ọjọ.
Naidoo ni o dara lati maa fi Probiotic-Yoghurt ku ounjẹ ti eniyn ba fẹ jẹ, amọ ki wọn fi ina kankan se e.
Ẹpa dara fun ọpọlọ

Oríṣun àwòrán, Others
Jijẹ ẹpa dara lara nitori o ni awọn eroja asaraloore bii omega -3 fatty acids to wa ninu rẹ, eleyii to ma n se anfaani fun ọpọlọ ati ero ẹda.
O pọn dandan ki wọn jẹ ẹpa to ni ohun meremere bii ọra to dara lati mu ki ara ji pepe.
‘’Chocolate’’ dudu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Jijẹ sokoleeti dudu dara fun ipese ohun amara ji pepe bii iron, eleyii to ma n da abo bo awọn eroja asaraloore to sun mọ ibi ti ọpọlọ wa.
Iwadii fihan pe awọn to n jẹ sokoleeti dudu yii kii sab ani irẹsi ọkan bii awọn ti kii jẹ.
Iwadii fihan bẹẹ ni ọdun 2019 nigba ti awọn ọdọ to le ni ẹgberun lọna mẹtala jẹ sokoleeti dudu, ti iwadii si fihan pe awọn to jẹ ni ilera ọkan pipe.
Avocado

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Avocado ni eroja amarajipepe bii magnesium to se koko fun ki ọpọlọ w ani alaafia.
Ọpọ iwadii fihan pe aisan irẹwẹsi ọkan niisepẹlu aisi eroja asaraloore magnesium nibẹ.
Ẹfọ jijẹ

Oríṣun àwòrán, Others
Onimọ nipa eto ilera ọpọlọ ni jijẹ alawọ ewe se pataki to si lee mu ki ara ji pepe.
Bio tilẹ jẹpe ọpọ awọn miran to kọ, ẹfọ ni eroja ara Vitamin E, carotenoids ati flavonoids to ma n sise karakara fun ara ti kii si jẹ ki o jo ajorẹyin.
Bakan naa ni ẹfọ dara ni ara fun ipese ẹjẹ ati awọn ohun to n mu ki awọ eniyan dan, ki ara naa si ji pepe.

Oríṣun àwòrán, Others












