Ohun tí òbí tó bá ń dá ọmọ tọ́ nílò rèé láti gba ìwé ìrìnà fún ọmọ wọn

Ileesẹ to n risi ijade-iwọle lorilẹede Naijiria, NIS ti ni ko si otitọ ninu iroyin pe awọn kii fun awọn obinrin nikan ni iranwọ ti wọn nilo lai gba asẹ baba ki wọn to fun wọn ni iwe irinna.
Eleyii n waye lẹyin ti awọn obinrin kan ke gbajare lori ẹrọ ayelujara pe NIS ko gba iwe aṣẹ ‘’consent lẹta ti o ba jẹ iya nikan lo buwọlu u lai si ibuwọlu baba nibẹ pẹlu.
Wọn ni: "Ajọ naa ko ni fun iru ọmọ bẹẹ ni iwe irinna."
Eyi lo mu ki ajọ ajafẹtọ omọniyan paapaa ẹtọ awọn obinrin gbe ọga agba ajọ NIS lọ si ileẹjọ lori ẹsun idẹyẹsi.
Ohun ti wọn n beere fun ni ki awọn eniyan buwọlu ki o le da ofin mu ajọ NIS lati gba laaye ki obi ẹyọkan ninu meji buwọlu iwe aṣẹ ki wọn to le fun ọmọ ni iwe irinna.
Amọ ajọ NIS ni ko si ohun to jọ idẹyẹsi ninu igbesẹ wọn, nitori asẹ ni pe ki awọn obi mejeeji buwọlu lẹta kan naa lati le gba ki wọn fun wọn ni iwe irinna.
Ohun tí òbí tó bá ń dá tọ́ ọmọ nílò rèé láti gba ìwé ìrìnà fún ọmọ wọn

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọmọ mi padanu lati lọ kawe ni ilẹ okeere nitori Naijiria kọ lati fun ni iwe irina’’
Arabinrin kan to sọ iriri rẹ ni ọmọ oun padanu lilọ ka iwe loke okun nitori iwe aṣẹ naa.
Iya awọn ọmọ mẹta naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Carolyn tik ii se orukọ abisọ rẹ , lo gbiyanju lati gba iwe irinna fun ọmọ rẹ ti ko I tii pe ọmọ ọdun mejidinlogun.
O ni awọn ajọ NIS kọ lati fun ọmọ naa ni iwe irinna nitor ibuwọlu oun nikan lo wa lori lẹta aṣẹ, iyen ‘’consent letter’’.
Arabinrin naa ni o le to bẹẹ titi ọmọ naa padanu ati wọle, ti ohun si gbiyanju lati lọ si ilu miran ki oun le gba iwe irinna naa.
O ni gbogbo ilakaka oun, ti oun tun san 90,000 ki o le jade bọọrọ, o ni ibi ti wọn ti fẹ ya aworan ni wọn ti fa idaduro nitori obi ẹyọkan lo buwọlu.
Bakan naa lo ni wọn fi ẹsun kan oun wi pe kilo de ti oun ko jẹ orukọ awọn baba awọn ọmọ naa to ba jẹ lootọ ni oun jẹ iya wọn.
Wọn tilẹ ni iru iwa bẹẹ lo ma n safihan awọn to ba ji ọmọ gbe, tabi ti wọn fẹ lọ fi wọn se owo ẹru ni ilẹ okeere.
Arabinrin naa ni ọpẹlọpẹ ibatan oun to kesi ọkọ oun tẹlẹri to buwọlu iwe aṣẹ naa ni wọn to fun ọmọ naa ni iwe irinna.
Amọ iwadii fihan pe ohun to w ani oju opo ayelujara Nigerian Immigration Service ni pe ọkan lara awọn pobi mejeeji lo gbọdọ fi lẹta silẹ pe awọn ọmọ awọn ni.
Ohun ti obi to n danikan tọ ọmọ nilo ree

Ajọ NIS ni documenti ti awọn ba beere lọwọ awọn araalu to fẹ gba iwe irinna se pataki nitori ohun ti wọn nilo ni.
O ni idi ni pe awọn ko fẹ ki obi keji wag be awọn lọ si ileẹjọ lẹyin ti wọn ba ti fun ọmọ ni iwe irinna lai gba aṣẹ lọwọ awọn obi mejeeji.
Ajọ naa ni awọn ko tako obi ẹyọkan amọ o se pataki ki awọn mejeeji fi ọwọ sowopọ ti wọn ba fẹ ran ọmọ lọ si ilẹ okeere.
Ajọ NIS war ọ awọn ọmọ Naijiria ki wọn gbaruku ti wọn nitori aṣẹ naa wa fun gbogbo eniyan ni.
Gẹgẹ bi ọrọ wọn awọn ohun ti wọn nilo ni;
Fọọnu ti wọn buwọlu lori ẹrọ ayarabiasa pẹlu aworan wọn nibẹ, ti awọn obi buwọlu
Evidence of Nigerian citizenship of parent(s).Arodaju pe ọmọ Naijiria ni awọn obi mejeeji tabi ọkan ninu awọn obi naa
Sabuke igba ti wọn bi ọmọ naa gba ọwọ ajọ National Population Commission fun awọn ọmọ ti wọn bi ni Naijiria.
Lẹta mo buwọlu, ọmọ mi ni lati ọwọ awọn obi ọmọ naa
Iwe ofin ‘’court affidavit’’ lati sọ pe obi ẹyọkan ni ọmọ naa w ani ikawọ rẹ gẹgẹ bi ohun ti agbẹnusọ NIS sọ fun BBC Pidgin.
Iwe pelebe to safihan oye ti ẹni naa san fun iwe irinna naa.
Iwe lati ileẹjọ ati iwe ti ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ ọmọde ati obinrin buwọlu to ba jẹ pe kii se awọn lo bi ọmọ naa, amọ ti wọn jẹ alagbatọ.















