Immigration officer kills man in Ogun: Ṣé lóòótọ́ ni ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè yínbọn lu olùfẹ̀hónúhàn nítorí #200 ní ìpínlẹ̀ Ogun?

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ́ ṣé lóòtọ́ ní ẹ̀sọ́ aṣọ́bòdé yínbọn lù olufẹhonuhan nítorí #200 ní Ìpínlẹ̀ Ogun?

Awọn olugbe ati ọmọ ilu Idigbo ni ijọba ibilẹ Yewa nipinlẹ Ogun ti kegbare sita lẹyin ti osisẹ ẹsọ aṣọbode kan yinbọn pa ọkan lara ọdọ ilu naa, Jacob Bamgbola lasiko ifẹhinuhan to waye niluu.

Araalu to ba Ileeṣẹ BBC News Yoruba sọrọ, Egunjobi Josiah ni awọn aṣọbode to wa ni ilu Igbokofin ti gbegi de ọna kan lati maa da awọn eeyan duro nibẹ.

"Nigba to di aarọ kutu, ọmọ kan ti wọn pe ni Gbenga, ọmọ yẹn n gbe awọn ọmọbinrin meji kan lọ lori ọkada."

Agbegbe kan ninu ilu

"Nigba ti Gbenga fẹ kọja, awọn ẹsọ aṣọbode ni o gbọdọ fun awọn ni igba naira.

"Ọmọ ọhun ni oun ko ni owo lọwọ, o ba lọ, igba to n pada bọ ni ṣe ni awọn aṣọbode naa ṣina ibọn bolẹ".

Egunjobi ni eyi lo bi awọn ọdọ ninu ti wọn si mori le ọdọ awọn aṣọbode naa lati ṣe ifẹhonuhan ṣugbọn nnkan to ṣẹlẹ ju agbara wọn lọ.

"Ilu pinnu pe ki a ransẹ pe awọn ẹṣọ aṣọbode lori ọrọ naa ṣugbọn nigba ti wọn de, niṣe ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn, awọn ọmọ yẹn wọn ko ba wọn ja.

"Aburo mi yẹn to d'oloogbe yẹn ni wọn kọkọ yinbọn lu u si ẹṣe osi, ọmọ yẹn ba wa ka ẹsẹ naa soke, ṣugbọn nigba to ṣe diẹ ni wọn ba tun gbe ibọn lu u ni ẹsẹ keji, lọmọ yẹn ba wo lulẹ.

"A de ile wosan kini, wọn ko gba, ikeji naa kọ silẹ, ko to gbe de ikẹta ni ọmọ naa jade laye,"

Pẹlu omije loju, Iyawo ati ọmọ oloogbe fi ba BBC News Yoruba sórọ

A kan si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun sugbọn alukoro ọlọpaa ni awọn ko gbọ nkankan nipa isẹlẹ naa

E wo fọnran yii