Olóṣó gún oníbàárà rẹ̀ pa l’Eko, ọ̀rọ̀ di ti ọlọ́pàá

Awọn obinrin oloṣo to duro n wa onibaara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Igba akọkọ kọ niyi ti oloṣo pa onibaara ni ipinlẹ Eko
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Obinrin aṣẹwo kan, Joy Kelvin, ni a gbọ pe o ti ṣeku pa onibaara rẹ ti wọn pe orukọ rẹ ni Okafor, nitori owo to yẹ ki ọkunrin naa sọ fun un lẹyin ibalopọ.

Iṣẹlẹ yii waye lọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024, ni Jakande Housing Estate, Lekki nipinle Eko.

Ohun ti a gbọ ni pe Okafor, ẹni ọdun mejidinlaadọta,(48), gbe Joy wale lati ba a ṣere ifẹ, ki o si fun un lowo ti wọn jọ duna-dura laaarọ ọjọ keji.

Ṣugbọn nigba tilẹ mọ, ti oloṣo beere owo rẹ, Okafor ko mu adehun naa ṣẹ.

Eyi fa ariyanjiyan laaarin awọn mejeeji, eyi to mu ki Arabinrin Joy fi ibinu mu nnkan oloro, to si fi gun Okafor.

Lẹyin to gun ọkunrin naa ni ko mọ nnkan kan mọ, eyi to pada ja si iku rẹ.

Àlàyé ọlọ́pàá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Joy Kelvin,oloṣo ti wọn lo gun Okafor pa.

Oríṣun àwòrán, Lagos State Police Force

Àkọlé àwòrán, Joy Kelvin, oloṣo ti wọn lo gun Okafor pa.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin to fi iṣẹlẹ naa lede ninu atẹjade kan, ṣalaye pe olufisun kan fi to wọn leti ni agọ ọlọpaa Ilasan, pe ni nnkan bii aago mẹfa ku iṣẹju mejidinlọgbọn, ni aṣẹwo kan, Joy Kelvin, gun ọrẹ oun Okafor, ẹni ọdun mejidinlaaadọta, nile rẹ to wa ni Jakande Estate, Lekki, Eko.

O ni agbesunmọju ni Okafor fi oloṣo naa ṣe.

‘Wọn sare gbe Okafor lọ sileewosan ijọba to wa ni Marina, l’Ekoo, lẹyin iṣẹlẹ naa, nibi ti dokita ti fidi ẹ mulẹ pe o ti ku.'

Lẹyin eyi ni awọn ọlọpaa lọ si ibudo iṣẹlẹ yii ti wọn si ya fọto, wọn gbe oku Okafor lọ si mọṣuari ijọba to wa ni Yaba, fun itọju ati ayẹwo.

Nipa aṣẹwo to gun onibaara rẹ pa naa, Hundeyin sọ pe ọwọ ofin ti ba a, o si ti wa lahamọ.

Bakan naa lo ni iṣẹ n lọ lati kan si awọn mọlẹbi Okafor, bẹẹ ni iwadii pẹlu ṣi n lọ lọwọ bo ṣe sọ.

Irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wáyé, ó ti ṣẹlẹ̀ rí.

Chidinma Ojukwu ati Oloogbe Usifo Ataga

Oríṣun àwòrán, Usifo Ataga

Àkọlé àwòrán, Chidinma Ojukwu ati Oloogbe Usifo Ataga

Tẹ o ba gbagbe, iru rẹ ni ti akẹkọọ ileewe Yunifasiti Eko, Chidinma Ojukwu, ti wọn ni o gun Micheal Usifo Ataga, ọkunrin to ni ileeṣẹ tẹlifiṣan Super TV pa ni 2021.

Lekki Phase 1, niluu Eko ni iṣẹlẹ yii naa ti waye, lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021.

Chidinma ni a gbọ pe o fi ọbẹ gun Usifo yanna-yanna ni igba aya ati ọrun, lẹyin ibalopọ ti wọn ti jọ ni.

Bi ọmọbinrin to wa ni ipele kẹta ẹkọ ninu iṣẹ iroyin nigba naa ṣe gun Usifo pọ to bẹẹ gẹẹ to jẹ iku lo yọri si fun ọkunrin olowo nla naa.

Ẹjo naa ṣi wa ni kootu titi di asiko yii, yoo si tẹsiwaju lọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹwaa ọdun 2024 yii.