Ìjọba Naijiria fẹ́ já iléèṣẹ́ amúnáwá mẹ́tàlá kúrò ní orísun iná ẹ̀lẹ́tírìkì

Òṣìṣẹ́ Iléèṣẹ́ amúnáwá

Oríṣun àwòrán, Others

O ṣeéṣe ki ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ orílè-èdè Naijiria, wa ninu okunkun birimu láìpẹ́, nitori bi ìjọba apapọ ṣe n já awọn Iléèṣẹ́ amunawa kuro ni orísun ina ẹ̀lẹ́tírìkì gbogbogboo.

Iroyin sọ pe ijọba apapọ n gbe ìgbésẹ̀ yii, lẹyin to ti kọ́kọ́ kọ iwe ìkìlọ̀ si awọn Iléèṣẹ́ amunawa.

Ìjọba àpapọ̀, nipasẹ ileeṣẹ to n pese ina, fi ẹ̀sùn kàn pe awọn ileeṣẹ amunawa naa jẹ ìjọba ni obitibi gbese owo.

Àwọn owo naa lo yẹ ki ileeṣẹ amunawa kọọkan ma a san si apo ìjọba, fun amojuto ati awọn nnkan míì to fi n ṣe àtìlẹ́yìn fun wọn.

Iléèṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé, Punch, jábọ̀ pe awọn Iléèṣẹ́ amunawa (Discos) ati awọn ileeṣẹ to n pese ina yàtọ̀ sí ìjọba (Gencos) ti ijọba yoo já kuro ni orísun ina ẹ̀lẹ́tírìkì ni:

  • Abuja Electricity Distribution Company
  • Benin Electricity Distribution Company
  • Enugu Electricity Distribution Company
  • Ibadan Electricity Distribution Company
  • Ikeja Electric
  • Jos Electricity Distribution Company Kaduna Electric
  • Kano Electricity Distribution Company Port Harcourt Electricity Distribution Company
  • APL Electric Company Aba
  • Ajaokuta Steel Company

Gencos

Niger Delta Power Holding Company Paras Energy

Gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ ati ìlú to wa lábẹ́ ileeṣẹ amunawa kọọkan ni ko ni ri ina lo nigba ti igbesẹ ijọba ba bẹ̀rẹ̀.

Ọkàn lara awọn ileeṣẹ amunawa ti ọrọ kan, IBEDC, sọ fun àwọn akọ̀ròyìn pe, obitibiti gbese ti awọn onibaara jẹ, lo ṣe okunfa owo ti ileeṣẹ naa jẹ ìjọba.

Eyi si lo mu ki oludari ileeṣẹ naa, Kingsley Achife, bẹ àwọn araalu lati san owo ina wọn ni kiakia.

Ìjọba sọ pe awọn ilana ati ofin wa fun ẹka ina ẹ̀lẹ́tírìkì, eyi to ṣe pataki fun gbogbo Iléèṣẹ́ amunawa lati tẹle.