Mr Eazi àti Temi Otedola mú ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu bàbá olówó Femi Otedola lórí ìfẹ́ wọn

Temi Ọtẹdọla ati Mr. Eazi.

Oríṣun àwòrán, Instagram/temiotedola

Baba olowo Fẹmi Ọtẹdọla ti da ibeere bo ọmọ rẹ Temi Ọtẹdọla ati afẹsọna rẹ, gbajugbaja akọrin takasufe, Mr. Eazi pe nigba wo gan ni wọn yoo gbe ere ifẹ wọn de ibi ere igbeyawo.

Temi ọmọ Ọtẹdọla lo fi fọto kan soju opo Instagram rẹ pe oun ati ololufẹ oun Mr. Eazi yoo bẹrẹ eto igbohunsafẹfẹ ori ayelujara kan laipẹ, ki awọn eeyan o maa fojusọna.

Baba rẹ, eekan olowo ni Naijiria ati lagbaye, Fẹmi Ọtẹdọla lo ba na ibeere nla sii loju opo naa pe "Moremiii, nigba wo lẹ fẹ ṣegbeyawo?".

Awọn ọmọ Naijiria ko si tiI jami lori esi ti wọn n fun ọrọ baba Temi. Bi ọpọlọpọ wọn ṣe n yin in lawọn mii n pe o gbe igbesẹ baba rere ti awọn miran si n ke sawọn ẹyẹle ifẹ mejeeji, iyẹn Temi Ọtẹdọla ati Mr. Eazi pe ki awọn naa ṣe kiakia.

Gẹgẹ bi awọn iroyin abẹle ṣe sọ, o ti le ni ọdun mẹta bayii ti awọn mejeeji yii ti n ṣe ajọṣepọ ifẹ, o si da bii ẹni pe eyi ti n pẹ ju loju baba wọn to si n fẹ ki wọn sọ kini ọhun dohun ni kiakia.

Aworan atẹjade naa

Oríṣun àwòrán, Instagram/temiotedola

Aworan atẹjade naa

Oríṣun àwòrán, Instagram/temiotedola

Aworan atẹjade naa

Oríṣun àwòrán, Instagram/temiotedola

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?