Ooni Ife wọ ìpèbí ọlọ́jọ́ méje nítorí ọdún Ọlọ́jọ́, Ó ní àwọn alálẹ̀ gbọ́dọ̀ dá sí ìnira mẹ̀kúnnù

Aworan Ooni ile ife

Oríṣun àwòrán, Ile Oodua

Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji ti wọ isera ni igbaradi fun ọdun Ọlọjọ to n bọ lọna nilu Ile Ifẹ.

Ọjọ meje ni Ọọni Ogunwusi yoo fi wa ni isera naa lasiko ti yoo fi maa ba awọn alalẹ ilẹ Yoruba gbogbo sọrọ ṣaaju ajọdun naa.

Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ nilu Ile Ifẹ ki wọn to sin in wọ inu ile Imọlẹ lọ, Ọọni Ogunwusi ṣalaye pe adura fun idagbasoke ati igbayegadun gbogbo ọmọ Oodua, orilẹede Naijiria ati gbogbo agbaye loun yoo mu lọkunkundun lasiko isera pẹlu Eledumare at’awọn irunmọlẹ naa.

Aworan Ooni ile ife

Oríṣun àwòrán, ile oodua

Ile Imọlẹ ni gbagede iṣẹmbaye awọn irumọlẹ lati igba iwasẹ nilu Ile Ifẹ lagbegbe Irẹmọ.

Bakan naa lo ke si gbogbo awọn orilẹede adulawọ kaakiri agbaye lati fi imọ ṣọkan pẹlu alaafia fun igbega eto ọrọ aje rẹ.

Bakan naa lo rọ awọn olori gbogbo nilẹ Afirika lati dide giri fun igbeleke Afirika ṣaaju ohunkohun.

“Mo fẹ ki gbogbo afbaye ba Afirika ṣe pọ gẹgẹ bi ọrẹ ati alajumọṣiṣẹ pọ. Afirika kii ṣe iṣoro ti aa yẹra fun tabi maa kaanu fun. Afirika ni kọkọrọ si ọjọ ọla gbogbo agbaye “

Aworan Ooni ile ife

Oríṣun àwòrán, ile oodua

Ọọni Ifẹ ṣalaye pe ko si ohun kan ti oun beere lọwọ Eleduwa at’awọn alalẹ ni gbogbo igba ti oun ba wọ isera fun ọdun Ọlọjọ lati odun mẹjọ ti oun ti gori oye ti ko wa si imusẹ.

O ni pẹlu laalaa ati ipenija t’awon ọmọ Naijiria n dojukọ lọwọ bayi, o pọn dandan fun awọn alalẹ lari da si ọrọ iṣejọba Aarẹ Tinubu ki o le jẹ eyi ti yoo mu ireti ọtun waye fun awọn ọmọ Naijiria.

Bakan naa lo rọ gbogbo awọn olori ijọba lẹkajẹka pe ki wọn tubọ tẹnpẹlẹ mọ titan wahala araalu, ki wọn si ti aarẹ lẹyin fun itẹsiwaju Naijiria.