Àwọn agbébọn ṣekúpa fijilanté mẹ́ta ní Kwara, ìjọba gbé ọjà tìpa

Aworan ọja ti awọn agbebọn ti ṣọṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Idoju ibọn kọra ẹni laarin awọn agbebọn atawọn eleto abo ti yọri si iku fijilante mẹta nipinlẹ Kwara.

Iṣẹlẹ naa lo waye ni ilu Gada Woro, ni opopona Patigi to wa ni ijọba ibilẹ Edu.

Gẹgẹ bi ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ se sọ, awọn agbebọn naa duro si ilu Gada to wa lẹba Gbugbu, tawọn fijilante si lọ koju wọn pẹlu awọn ọmọ ogun ati awọn agbofinro, ṣugbọn ohun ija awọn agbebọn naa lagbara.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe jẹ

Lasiko to n ba BBC sọrọ lori iṣẹlẹ naa, o ni ọpọ awọn eleto abo lo farapa.

O tẹsiwaju pe wọn ti ti ọja nla to wa lagbegbe naa pa bayii latari iṣẹlẹ ọrọ eto abo.

Oṣojumi koro naa fikun ọrọ rẹ pe inu ibẹru bojo lawọn eeyan agbegbe ọhun wa bayii.

Awọn fijilante mẹta ti wọn padanu ẹmi wọn ni, Mohammed Nma to wa lati abule Kokodo, Ndagi Saraka lati abule Edogi, ati Yanda lati abule Lafiagi.

Bakan naa ni wọn fidiẹ mulẹ pe fijiilante kan ti dawati lẹyin ikọlu naa.

Ẹwẹ, wọn ti ti ọja agbegbe naa ni Gbugbu pa latari ibẹru bojo akọlu awọn agbebọn ti wọn tun le pada wa.

Ẹlomiran ti ọrọ naa ṣoju rẹ, Ọgbẹni Ganna sọ pe nigba mii ọjọ ọja ni wọn ma n wa lati ji awọn eeyan gbe.

Ṣugbọn lọjọ Aje ọsẹ yii, awọn fijiilante ati awọn eleto abo parapọ lati lọ koju wọn.

O tẹsiwaju pe lasiko ti awọn fijilante atawọn eleto aabo lọ koju wọn lawọn fijiilante mẹta to di oloogbe padanu ẹmi wọn.

O tun fi kun pe, awọn eleto aabo naa tun farapa lasiko ikọlu naa.

Gẹgẹ bo sẹ ṣalaye, agbegbe naa o fararọ lọwọ yii nitori awọn agbebọn ọhun ko jẹ ki wọn ri imu mi pẹlu bi wọn se n ji awọn eeyan gbe.

Awọn ara ilu naa ti wa ke si ijọba ko pese abo to peye fun wọn.

Ijọba ti ọja pa

Ẹwẹ alaga ijọba ibilẹ Edu, Abdullahi Bello ti gbe ọja Gbugbu ti pa.

Ninu atẹjade kan ti alaga ijọba ibilẹ naa fi sita, o ṣalaye pe ọja naa yoo wa ni titi pa titi ti ọrọ eto abo agbegbe ọhun yoo fi duro.

Lẹyin naa lo rọ araalu lati farada igbesẹ naa, o tun kan sara si awọn eleto aabo fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe.

Ọja Gbugbu lo jẹ ọja nla to tobi julọ lagbegbe naa.