A ò lè sùn pẹ̀lú àlááfíà mọ́ nítorí àwọn ọmọ onílẹ̀ ní – Àwọn onílé ní Alagbaka, Akure pariwo síta

Àkọlé fídíò, A ò lè sùn pẹ̀lú àlááfíà mọ́ nítorí àwọn ọmọ onílẹ̀ ní – Àwọn onílé ní Alagbaka, Akure pariwo síta
A ò lè sùn pẹ̀lú àlááfíà mọ́ nítorí àwọn ọmọ onílẹ̀ ní – Àwọn onílé ní Alagbaka, Akure pariwo síta

O seese ki ọpọlọpọ awọn onile ni agbegbe Alagbaka extention n'ilu Akure, ti n se olu-ilu Ipinlẹ Ondo, di alainile lori laipẹ.

Eyi waye bi ẹbi Olokunjuwon ati Umelu ṣe kede lọjọ Aiku to kọja pe, awọn ni wọn ni awọn ilẹ agbegbe naa ni ibamu pẹlu idajọ Ileẹjọ to ga julọ lorileede yi.

Nigba ti BBC Yoruba ṣe abẹwo si agbegbe naa safihan, wọn ti lẹ iwe kaakiri awọn ile to wa lagbegbe naa, pe ki wọn kuro lori ilẹ ti wọn kọle si tabi ki wọn ṣe idunadura pẹlu ẹbi mejeeji.

Awọn onile lagbegbe ọhun n sọ pe awọn ko loju orun mọ bayi ati pe idumọhuru awọn ọmọ onilẹ naa ti n ko ẹmi awọn soke.