Wo ohun tó n ṣẹlẹ̀ sí ọkàn rẹ bí o bá sá eré ìje olóbìírípo láì sinmi

Hugo Farias lo wọ aṣọ alawọ aro, ti awọn oniukẹkẹ mẹta wa lẹyin rẹ.

Oríṣun àwòrán, Dókimos Produções

Àkọlé àwòrán, Hugo Farias loun fẹẹ mọ bo ṣe n ri lara bi eeyan ba n ṣere idaraya to le ju.
    • Author, Giulia Granchi
    • Role, BBC News Brasil
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Ni 2023, ọkunrin elere ije kan, Hugo Farias, gba ami ẹyẹ agbaye fun bo ṣe pari ere olopoo to din diẹ ni irinwo, 366 marathons ,leralera.

Ere sisa yii ju ki eeyan sare onikilomita mejilelogoji (42km)lọ, iyẹn maili mẹrindinlọgbọn (26miles) bi a ba ṣi i ni ti maili lojumọ kan .

Bẹẹ lo ṣe sare naa fun ohun to le lọdun kan, ko si pa ọjọ kan jẹ laaarin rẹ ri tojo-tẹẹrun.

Laarin asiko to n ṣe nnkan agbara yii, Hugo, ẹni ọdun marundinlaadọta (45) to si tun jẹ oniṣowo ọmọ ilẹ Brazil, kopa ninu iṣẹ iwadii iṣegun kan lati mọ ipo ti ọkan rẹ wa pẹlu iṣẹ agbara to ṣe.

O fẹ lati mọ bi nnkan ṣe n lọ lara rẹ nigba to n sa kilomita mẹẹẹdogun (15,000km) (9,321 miles) laaarin ọdun kan.

"Ki i ṣe pe mo jẹ elere idaraya to gbayi to bẹẹ yẹn naa tẹlẹ. Ẹẹkan pere ni mo sare lai sinmi ri laye mi.

"Ṣugbọn o wu mi lati yi itan mi pada, mo fẹ fi itan balẹ lati ara ere idaraya, bo ṣe n jawọ-jasẹ ninu mi niyẹn."

Hugo Farias lo ṣalaye bẹẹ.

Hugo Farias.

Oríṣun àwòrán, Clayton Damasceno

Àkọlé àwòrán, Farias ree, o ni oun lero pe irinajo oun yii yoo jẹ iwuri fun awọn eeyan mi-in.

''Ohun tí mo ti ń bá bọ̀ tẹ́lẹ̀ sú mi, mo pinnu láti yí ayé mí padà''

Gegẹ bi Farias ṣe ṣalaye fun BBC Brasil, o ni oun pinnu lati yi boun ṣe n ba aye oun bọ pada, nitori igbesi aye ojukan toun n gbe nigba naa su oun.

"Igba kan wa ti mo jokoo ti mo ro o, mo ni ṣe ohun ti wọn bi mi fun ni mo n ṣe yii? Ki ni ka maa ṣe nnkan kan naa fun ọdun marundinlogoji abi ogoji ọdun?

"Lati kekere ni eeyan ti n kọ ẹkọ, lati maa n wa ọna ti a maa fi yan iṣẹ kan laayo lati ṣe ka too pe ẹni ọdun mejidinlogun (18).

Eeyan ti gbọdọ maa ro o bi yoo ṣe rẹsẹ tilẹ, bi yoo ṣe le da duro ti yoo si ni ẹbi tirẹ, bẹẹ ni eeyan yoo ti maa gbaradi fun ifẹyinti ko too de .

"Mo bẹrẹ si i ronu pe mo le ṣe ju bẹẹ lọ, ti yoo si jẹ nnkan iwuri fun awọn eeyan mi-in lọna ọtọ."

Hugo Farias ree ni yara ayẹwo pẹlu awon dokita to n wo iṣẹ ọkan rẹ.

Oríṣun àwòrán, Handout

Àkọlé àwòrán, Awọn dokita to n ri si ọkan eeyan ree ti wọn n yẹ ọkan Farias wo ni ileewosan São Paulo Heart Institute InCor..

Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsí náà ṣe níbẹ̀

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lara ohun to wu Farias lori bo ṣe wi ni itan ọkunrin ọlọkọ oju omi ọmọ Brazil kan ti orukọ ẹ n jẹ Amyr Klink, ọkunrin naa wa ọkọ oju omi lori alagbalugbu omi okun South Atlantic ni 1984.

''Ṣugbọn emi o ni ni i wa ọkọ oju omi, ere ni mo maa sa ni temi." Hugo lo ronu bẹẹ to si pada mu ero ọkan rẹ ṣẹ.

O wa ọna lati pade elere ije ọmọ Belgium, Stefaan Engels, ẹni to ti sare olopo 365 ti fun ọdun kan. Farias naa si pinnu lati sa tiẹ ju bẹẹ lọ.

O ju oṣu mẹjọ lọ to fi to gbogbo ero ọkan rẹ to fẹẹ muṣẹ yii. Bo ṣe n lọ fun idaraya lo n gba itọni lati ọdọ awọn ogbontarigi elere ijẹ.

"Mo mọ pe mi o le da a se, awọn ikọ gbogbo ti mo nilo ni mo ṣeto.

Awọn dokita, awọn elere idaraya , awọn to n to egungun ati dokita to n ri si irori eeyan ni mo ko jọ. "

" Iṣẹ ti mo n ṣe to ti fẹsẹ mulẹ daadaa ni mo fi silẹ ti mo si kọ oju mọ ohun ti mi o mọ boya yoo tiẹ mu èrè wa fun mi rara.

Ẹru maa n ba mi nigba mi-in lori ohun ti mo gunle yii, nitori ẹ lo fi ṣe pataki pe ki n ko awọn ti mo sọ yẹn mọra lati yẹ mi wo."

Ọkan lara awọn akọṣẹmọṣẹ ti Hugo gbe iṣẹ naa fun ni ile iwosan itọju ọkan São Paulo Heart Institute InCor.

"Mo beere pe ṣe wọn le darapọ mọ mi, ki wọn fi han mi bi ọkan mi ṣe gba iṣẹ ti mo n fun un ṣe.

Boya yoo jẹ ki ọkan mi tobi si i ni tabi yoo jẹ ko kere si i, boya mo maa ni aisan ti a mọ si arrhythmias [ti ọkan ko ni i ṣiṣẹ daadaa) tabi mo maa koju awọn wahala mi-in.

"Mo si tun fẹẹ da si imọ ijinlẹ sayẹnsi pẹlu."

Bẹẹ ni Hugo Farias wi.

Aworan to ṣafihan aṣeyọri Hugo Farias.

Dokita onimọ nipa ọkan, Maria Janieire Alves, kopa ninu ayẹwo ọkan Farias.

"Ẹnikẹni ko ti i ṣe ohun to ṣe yii ri, o si ni ipa to ṣe e tọka si lori ọkan."

Dokita Maria ṣalaye lori ọna ti Hugo ko fi ni i lugbadi aisan ọkan.

Oṣooṣu lo n lọ fun ayẹwo kan ti wọn pe ni 'ergospirometry (wọn fi n mọ bi ọkan ṣe n ṣiṣẹ si lasiko ere idaraya.

Oṣu mẹta-mẹta naa lo si fi n ya aworan ọkan rẹ.

"A ṣe eyi lati mọ bi ọkan rẹ ṣe n ṣiṣẹ si, nigba to ba n ṣere lile ati ere ti ko nira . A si n yẹ ẹ wo boya awon nnkan kan ti n yingin."

Dokita Maria Alves lo ṣalaye bẹẹ.

Hugo Farias naa ree to ṣi ara rẹ silẹ, to si n rẹrin-in musẹ.

Oríṣun àwòrán, Dókimos Produções

Àkọlé àwòrán, Hugo Farias

'Hugo pari idije naa '

Hugo pari ere ije naa lọjọ kejidinlọgbon, oṣù Kẹjọ odun 2023.

Díẹ̀ ló ku ko gba a to ẹgbẹta wakati (1,590 hours) lati pari ere ije 15,569km (9,674 miles).

Idije naa ni oruko re si fi wọ iwe àkọsílẹ̀ agbaye (Guinness World Record.)

Hugo to bímọ meji maa n sare laraarọ ko le baa ni asiko fún áwọn ẹbí rẹ, ko si le fi asiko to ku sinmi.

Bakan naa lo fẹrẹ jẹ́ pe ọ̀nà kan naa lo maa n sare gba nigboro Americana, ilu São Paulo.

Àbọ̀ iwadii ti wọn fi lede ninu iwe scientific journal Arquivos Brasileiros de Cardiologia, gba pe pẹlu bi Hugo ṣe kopa ninu ere ṣíṣá leralera, ko si apeere akoba tabi ailera kankan ni ọkàn rẹ.

Ju gbogbo ẹ lọ, àbọ̀ iwadii naa fi han pe eeyan le kọ ọkàn rẹ lẹkọọ lati gbacere ìdárayá to le, to ba ti jẹ pe ko le ju.

Dokita Alves lo sọ eyi.

"Eyi fi han wa pe okan elere idaraya le gba ohun to ba le gan-an, niwon igba ti ko ba ti kọjá gbedeke alaafia, to si n sinmi láàárín ẹ kọ̀ọ̀kan."

Dokita to n tọju arun ọkàn lẹka eré idaraya, Filippo Savioli, ti ko ba wọn ṣe ninu ìṣe ìwádìí náà ló ṣalaye bẹẹ fun BBC.

Awon akọṣẹmọṣẹ ṣalaye pe Farias pari idije naa lai jẹ pe ohunkóhun ṣe ọkàn rẹ

Oríṣun àwòrán, Dókimos Produções

Àkọlé àwòrán, Awon akọṣẹmọṣẹ ṣalaye pe Farias pari idije naa lai jẹ pe ohunkóhun ṣe ọkàn rẹ

O ni Hugo sare naa lọ́nà tí kò nira.

Dokita Filippo Savioli sọ pe onka ọkàn re wa ni 140bpm niṣẹju kan.

Onka 70-80% ni ifunpa rẹ si wa, eyi to ni o daa fun ọjọ ori rẹ.

"Eyi je ko wa ni alaafia ara, ara rẹ ṣi le pese eemi to nílò."

O ni bi eeyan ba n sare nilana ti Hugo tọ yii, o maa n din ewu aisan okan ku.

Dokita naa sọ pe to ba jẹ pe ilana to le ju ni Farias fi sa ere rẹ ni , ipa to buru ni ko ba ni lara rẹ.

O kilọ pe o lewu lati bẹ̀rẹ̀ iru ere yii lai si ẹ̀kọ́ fun un ati lai si abojuto awon dokita.

"Bi èèyàn ko ba gbaradi to si bẹ̀rẹ̀ ere bi eyi, o han kedere pé yoo ṣe ara rẹ lèṣe, o si le ja siku pẹlu."

'Gbàgbọ́ nínú ara à rẹ '

Fun Hugo, o ni abajade iwadii awon dókítà ya oun lenu.

"Ara mi da ṣakaṣaka leyin ère naa. Bi wọn si se ni ko si laburu kan to ṣe mi lati ara ere náà ṣe pataki gan-an.."

Ṣùgbọ́n ki i ṣe pe ere sisa naa fi gbogbo ẹ rọrùn, Hugo ṣalaye pe:

"Gbogbo ẹ ni mo koju: otutu, ooru, ojo, sunkẹẹrẹ-fakẹẹrẹ, mo ṣeṣe pelu. "

Ẹẹmeta lo koju igbọnsẹ gbuuru, o fi ọjọ márùn-ún ṣègbọ̀nsẹ̀ lasiko kan.

"Mo padanu ara sisan pelu ìwọ̀n mẹrin, 4kg. Nisẹ ni mo ṣe àtúnṣe si oúnjẹ mi ati bi mo ṣe n mumi. Ṣùgbọ́n mi o tori ẹ jáwọ́"

Farias ree pelu awon ẹbi rẹ nigba to parí ere olopa 366 naa.

Oríṣun àwòrán, Dókimos Produções

Àkọlé àwòrán, Farias ree pelu awon ẹbi rẹ nigba to parí ere olopa 366 naa.

'Ìdíje tó kú fún mi báyìí ni ti kí ń jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó sáré yipo po gbogbo America '

Hugo Farias ti kọ̀wé nipa iriri rẹ yii, ko si fi ere sisa sílẹ, o ṣi n sare.

Gege bo ṣe wi, idije to ku fun un bayii ni ti bo ṣe fẹẹ jẹ ẹni àkọ́kọ́ ti yoo sare yipo gbogbo America, bẹ̀rẹ̀ lati Prudhoe Bay, ní Alaska, de Ushuaia, ní Argentina.

"Afojusun mi ni lati kede anfaani to wa ninu ere idaraya fun gbogbo aye, káwọn èèyàn si le mọ pe wọn le ṣe àwọn nǹkan agbayanu."

"Ko seni to gbọ́dọ̀ sare ije aisinmi lojoojumọ, ṣùgbọ́n gbogbo eeyan lo yẹ ko gbagbọ ninu ẹbun ara rẹ."

Hugo Farias lo pari ọrọ rẹ bẹẹ.