Mr Macaroni: Mo rọ àwọn ọ̀dọ́ láti múra síṣẹ́, kí wọn má sì tẹ́ńbẹ́lú ẹnikẹ́ni

Oríṣun àwòrán, Instagram
Gbajugbaja oṣere ati apanilẹrin ti gbogbo eniyan mọ si Mr Macaroni, amọ ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Debo Adebayo ti ni, igbe aye oun ti yatọ si ti tẹlẹ lati igba ti oun ti bẹrẹ si ni pa awọn eniyan lẹrin.
Mr Macaroni sọ eyi lasiko ti BBC se akanṣe ifọrọwerọ pẹlu rẹ lori bi o se bẹrẹ si ni sere ati bi o ṣe jẹ gbajugbaja loni lori oju opo ibanidọrẹ, Social Media.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Láì lo Kakulétọ̀, mo ní ọpọlọ ìṣirò, tábìlì ìṣirò wà lórí mi - Human Calculator
- Chatta bímọ tuntun, Mide àti Osupa lẹ̀pọ̀, Sanwo-Olu fún Sola Sobowale lámì ẹ̀yẹ
- Osinbajo wọ́gilé ìrìn-àjò rẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀kan lára ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ kú nínú ìjàmbá ọkọ̀
- Sanusi tí kúrò ní ìlú Awe lọ sí Abuja- Gomina El-Rufai
- Músò! Músò! Afurasí Alárun Coronavirus kejì ní Nàíjíríà tún rí ìwòsàn
- Ọkùnrin tó bẹ́ sì òdò ọ̀sà pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, lòun náà fi fẹ́ kú - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Ifọrọwerọ BBC Yoruba ree pẹlu Mr Macaroni:
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Apanilẹrin naa jẹ ẹni to ti n se ere tiata ni ẹka sinima Naijiria taa mọ si Nollywood, lati ọdun diẹ sẹyin.
Mr Macaroni ni ayé oun ti dára si láti ìgbà tí oun ti bẹ̀rẹ̀ si ni ṣe awọn ere apanilẹrin kekeke yii, ti o si ti ṣi ọpọlọpọ ilẹkun fun oun.

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ninu ọrọ rẹ, o ni awọn ibi nlanla ti oun ko le e wọ tẹlẹ, oun ti bẹrẹ si ni ni anfaani lati wọ ibẹ ti awọn eniyan si n mori oun wu ni gbogbo igba.
Bakan naa lo fikun pe, itara lati ka iwe lo mu oun lọ si ile iwe giga fasiti mẹrin ọtọọtọ lati ọdun 2009 si isinyii, ki oun sẹ̀sẹ to lọ fun agunbanirọ oun.

Oríṣun àwòrán, Instagram
Mr Macaroni wa gba awọn ọdọ ni iyanju lati mura si iṣẹ ti wọn ba n se, ki wọn si mase tẹnbẹlu ẹnikẹni nitori ko si ẹni to mọ bi ọjọ ọla yoo ṣe ri.
Bakan naa ni o sọ fun awọn eniyan to ba nilo iranwọ le kan si wọn, amọ ki awọn naa mura si iṣẹ ki gbogbo wọn lapapọ le ṣe oriire papọ.
- Yorùbá rẹwà, kọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí ìró ẹnu wọn jọra àmọ́ tí ìtumọ̀ wọn yàtọ̀
- Kò sẹ́ni tó fẹ́ pa Buhari o, ọkùnrin tó pakuru mọ́ ààrẹ kàn fẹ́ bọ̀ọ́ lọ́wọ́ ni - Femi Adesina
- Àríwá Nàíjíríà, ẹ sọ ẹran jọ̀bọ̀-jọbọ nù pẹ̀lú Sanusi tẹ yọ lóyè - Soyinka gbarata
- A kò mọ ẹni tó pa ọlọ́pàá Ondo àti ìyàwó rẹ̀, òun kọ́ ló pa ara rẹ̀- ọlọ́pàá
- Nàìjíríà bèèrè ìrànwó lọ́wọ́ àjọ àgbáyé láti kápá Coronavirus
- "Owó oṣù òṣìṣẹ́ yóò di gbèsè, oúnjẹ yóò wọ́n, ìlú yóò le, bí ọrọ̀ ajé Náíjíríà bá dagun"
Lara awọn ere ti Mr Macaroni ti kopa ni ere apanilẹrin Jenifa's Diary, House 31, Royal Outlaw, SuperStory ati bẹẹ bẹẹ lọ.












