Yoruba Artists: Chatta bímọ tuntun, Toyin ati Davido lẹ̀pọ̀, Sanwo-Olu fún Sola Sobowale lámì ẹ̀yẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ẹbun pataki lọmọ bibi, iya aburo ku ewu. Eleduwa ti fi ọmọ tuntun jojolo da idile ọkan lara awọn oṣere tiata kan lọla laarin ọsẹ yii.
Eyi ni akojọpọ awọn ohun to ṣẹlẹ lagbo awọn oṣere tiata Yoruba lọsẹ yii.
Ibrahim Chatta
Eleduwa ti fi ọmọbinrin lantilanti jinki gbajugbaja oṣere tiata, Ibrahim Chatta.
- Ọ̀pọ̀ nǹkan tí kò yé èmi àti Bàbá Wande, ló fa ìjà lórí sinimá Tolúwa Nilẹ̀ - Tunde Kelani
- Yorùbá rẹwà, kọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí ìró ẹnu wọn jọra àmọ́ tí ìtumọ̀ wọn yàtọ̀
- Bojú bojú o... Ta ló rántí?
- Músò! Músò! Afurasí Alárun Coronavirus kejì ní Nàíjíríà tún rí ìwòsàn
- Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá, DSS, ẹ fún Sanusi lómìnira àti rìn fanda padà - Iléẹjọ́ pàṣẹ
- Ọkùnrin tó bẹ́ sì òdò ọ̀sà pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, lòun náà fi fẹ́ kú - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Chatta fi aworan ọmọ naa nibi to ti gbe e dani sori oju opo Instagram rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Chatta dupẹ lọwọ Ọlọrun bi o ti kede pe ọmọbinrin ni ọmọ naa ti Eleduwa fi ta idile rẹ lọrẹ
Ẹwẹ, kete ti iyawo Chatta bimọ naa tan lawọn akẹgbẹ rẹ bẹrẹ si ni fi ikinni ranṣẹ sii.

Oríṣun àwòrán, Instagram
Wunmi Toriola wa lara awọn oṣere to kọkọ kii ku oriire ọmọ tuntun ti Ọlọrun fi jinki idile Chatta.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
O gbadura pe ki Ọlọrun wo ọmọ naa ati awọn ẹgbọn rẹ, koda aworan Chatta ati iyawo rẹ pẹlu ọmọ tuntun naa ni Wunmi fi si oju opo Instagram rẹ lati ki wọn.
Toyin Abraham
Aworan bi Toyin Abraham ti fẹnu ko olorin takasufe, Davido lẹrẹkẹ ni o fi si oju opo Instagram rẹ.
O lo anfaani naa lati polowo fiimu rẹ. ''Fate of Alakada'' ti yoo jade ni sinima lọjọ jẹta oṣu kẹrin ọdun yii.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Adura lo gba pe ki Eleduwa tubọ maa bukun fun olorin Davido.
Mide Martins
Fiimu ''AJULO'' to n bọ lọna ni Mide Martins sọ nipa rẹ lori ẹrọ ayelujara Instagram.
Fọtọ oun ati ilumọọka olorin Fuji, Saheed Osupa lo fi sori ojo opo Instagram rẹ nibi tawọn mejeeji ti jọ joko.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 4
Mide ki awọn ololufẹ rẹ ku oju lọna fiimu ọhun ninu eyi ti Saheed Osupa ko pa ninu rẹ.
Sola Sobowale
Ami ẹyẹ imọriri ẹni ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu fi da oṣere, Sola Sobowale lọla.
Sola Sobowale fi idunnu rẹ han nibi to ti ki Gomina Sanwo-Olu fun imọriri oun.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 5
O ni oun ko niran pe Gomina ipinlẹ Eko ni iru nnkan bayii lọkan lati fun oun ni ami ẹyẹ.
Foluke Daramola
Orin igbe ni Foluke Daramola fi bọnu ninu fidio to fi lede loju opo Instagram rẹ.
Foluke sọ ninu fidio naa pe kawọn eeyan kan to n gbe iroyin ofege kiri pe oun ku ye parọ kiri.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 6
O ni oun ko ni ku iku kiku kan bi ko ṣe yiye, o ni ẹni to ba n ro iku ro oun yoo lọ jẹ Ọlọrun nipe.